Gẹ́gẹ́ bí Ìròyìn lórí èsì ètò ìdìbò tí alága ètò ìdìbò ipinlẹ̀ Ọ̀ṣun fi léde lórí ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó wáyé ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló jáwé olúborí sí gbogbo ipò alága ìjọba ìbílẹ̀ náà pẹ̀lú ìjókòó àwọn Káńsẹ́lọ̀ ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ ọgbọ̀n tó wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀șun.
Ó ṣàlàyé pé ètò ìdìbò náà lọ láìsí gbọ́nmi-sí-i-omi-ò-tó-o kankan rárá, tó sì ní àṣeyọrí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àríyànjiyàn ráńpẹ́ fẹ́ẹ́ wà níbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Gómìnà Adélékè ti fìgbà kan pàrọwà fún àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun pé wọ́n kópa tó yẹ nínú ètò ìdìbò ìjọba tiwa-ñ-tiwa náà.
Alága ètò ìdìbò sọ ọ́ di mímọ̀ pé ẹgbẹ́ méjìdínlógún ló kópa nínú ètò ìdìbò náà. Tí a ò bá gbàgbé, ilé-ẹjọ́ gíga tó fìkàlẹ̀ sí ìlú Iléṣà ti kàn án nípá fún àjọ elétò ìdìbò nínú ìdájọ́ rẹ̀ lórí ẹjọ́ tí ẹgbẹ́ PDP pè pé kí wọ́n tẹ̀síwájú nínú ètò ìdìbò tí wọ́n ti là kalẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Ṣáájú àkókò yìí ni Amòfin Àgbà tó tún jẹ́ mínísítà fún ètò ìdájọ́ nílẹ̀ Naijiria, Lateef Fagbemi ti rọ ìjọba ìpínlè Ọ̀ṣun láti kára ró lórí ètò ìdìbò náà,nítorí ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ kan ti dá alága tó wà níbẹ̀ padà sórí àlééfà. Nítorí náà kò sí àlàfo kankan ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ ọgbọ̀n tí wọ́n fẹ́ẹ́ yan ènìyàn sí mọ́.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe pa á láṣẹ pé ìdìbò náà kò gbọdọ̀ wáyé nítorí pé àwọn gbọ́ pé rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀, Gómìnà Adeleke fakọyọ nípa títẹ̀síwájú nínú ètò ìdìbò náà, ní báyìí, èsì ti jáde, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tíí ṣe ẹgbẹ́ òṣèlú Gómìnà Adeleke ni ó jáwé olúborí ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ àti ipò kánsílọ̀.
A kò gbọ́ nǹkankan lẹ́nu ẹgbẹ́ òṣèlú APC látàná, kẹ́kẹ́ pa mọ́ àtíòro wọn lẹ́nu.