Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ẹ̀ka ìpínlẹ̀ èkó gbé òṣùbà ràbàǹdẹ̀ fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lórí ipa májẹ́óbàjẹ́ tó kó nínú ìdìbò gọ́mìnà ìpínlẹ̀ Anambra. Wọ́n ní bí ó ti yẹ kí àgbà ó ṣe gan-an ni ààrẹ ṣe láìgbè sí ọ̀dọ ẹnìkan nínú ètò ìdìbò náà, àpẹẹrẹ rere nịnú ìṣèjọba àwarawa lèyí jẹ́.
Agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Èkó; Ọ̀gbẹ́ni Seye Oladejo ló sọ èyí fún àwọn akọ̀ròyìn.
Ó wí pé ààrẹ dúró fún ètò ìdìbò tí kò ní mọ̀dàrú nínú ní èyí tó ń fi ẹsẹ̀ ìṣèjọba alágbádá múlẹ̀.
Èyí hànde nígbà tí ààrẹ kọ dá sí ọ̀rọ̀ ìdìbò náà, ó kọ̀ láti gbè sí ẹ̀yìn Kankan nínú àwọn olùdúje, ó fi àjọ INEC sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ wọn bíi iṣẹ́, èyí fi hàn pé adarí tó ṣe é wòkọ́ṣe ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Bákan náà ló gbé oríyìn fún àjọ INEC fún ṣíṣe ètò ìdìbo náà pẹ̀lú òtítọ́ láì fi igbá kan bọ̀kan nínú.
Èyí jẹyọ lẹ́yìn tí Gómìnà Soludo jáwé olúborí nínú ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra.
Àjọ ètò ìdìbò ilẹ̀ wa; INEC ti kéde èsì ìdìbò Gómìnà tó wáyé lọ́jọ́ kẹ́jọ, oṣù Belu, ẹni tó jáwé olúborí náà ni gómìnà tó wà nípò lọ́wọ́lọ́wọ́; Chukwuma Soludo, èyí ni yóò jẹ́ sáà kejì rẹ̀ báyìí.
Gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ni Soludo fi la àwọn olùdíje yòókù, ẹni tí ibò tirẹ̀ náà ta bíọ́bíọ́ díẹ̀ náà ni olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC; Nicholas Ukachukwu.
Gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rọ̀ INEC; mẹ́rìndínlógún ni àwọn olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kànlélógún tó wà ní ìpínlẹ̀ náà ni Soludo ti jáwé olúborí, dájúdájú, kékeré kọ́ ni bàbá fi ju ọmọ lọ.
Omoregie; ẹni tó kéde èsì ìdìbò náà wí pé lẹ́yìn gbogbo àkójọ àti kíkà; Soludo ni ó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà. Ó wí pé àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan kojú ìdààmú àti rògbòdìyàn ní èyí tó mú kí wọn ó fagi lé ibò wọn níbẹ̀ àmọ́ èyí kò dí èsì àpapọ̀ lọ́wọ́.
Omoregie wí pé lákòótán, òun fi ọwọ́ sọ̀yà pé ìdìbò náà lọ nírọwọ́ rọsẹ̀ tí Chukwuma Soludo; ẹni tó jẹ́ olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APGA jáwé olúborí.
Bí Soludo ṣe ń yọ̀ ni olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti ní kó má tíì dunnú jù. Ẹ ka ohun tó wí:
Nicholas Ukachukwu; ẹni tó jẹ́ olùdíje dupò gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti sọ ìhà tó kọ sí èsì ìdìbò náà, ó wí pé òun kò tíì gbà pé Chukwuma Soludo; ẹni tó wà nípò náà báyìí tó sì tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APGA ló jáwé olúborí, ó wí pé àwọn yóò ṣe àtúnyẹ̀wò èsì ìdìbò náà pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tí àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ bá mú wá.
Ó wí pé àwọn èèyàn tí iye wọn dín díẹ̀ ní mílíọ́nù kan ló dìbò fún òun, èyí túmọ̀ sí pé àwọn aráàlú ń fẹ́ òun nípò náà fún ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbàsókè, láìpẹ́ láìjìnnà, ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni yóò máa darí ìpínlẹ̀ Anambra.
Ọ̀rọ̀ Nicholas tẹ̀síwájú pé láti ibi ìdìbò abẹ́lé ni àwwọn ti ń ṣe akitiyan, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òun gbìyànjú wọ́n sì ṣe bẹbẹ kí gbogbo rẹ̀ ó le já sí rere àmọ́ lásìkò ìdìbò náà, àwọn jàǹdùkú ṣe ìkọlù fún àwọn olólùfẹ́ mi àti àwọn aṣojú mi, wọ́n tilẹ̀ gbé ọ̀kan nínú wọn pamọ́ di ẹ̀yìn ìbò.
Ẹ̀yìn náà ríi pé ejò lọ́wọ́ nínú èsì ìdìbò náà. Mo ń dúró de ìjábọ̀ àwọn aṣojú mi àti ohun tí ẹgbẹ́ APC yóò sọ kí n tó mọ ohun tí màá ṣe.
Wọ́n tún fi ẹ̀sùn ìbò rírà kàn mí, ǹjẹ́ ó ṣe é ṣe fún ẹni tí kò sí nípò láti ra ìbò?
Bí mob á ra ìbò lóòótọ́, èsì ìdìbò ni yóò fi hàn kìí ṣe àwọn ni yóò ṣe máa sọ. Gbogbo àwọn tí wọ́n ṣe ìkọlù sí ló jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, wọ́n tún dáná sun ilé obìnrin kan tí òun náà jẹ́ olólùfẹ́ APC, ṣé ẹ̀yin náà rí i pé àparútu ni ẹgbẹ́ òṣèlú APGA ṣe? Nicholas ló bèèrè bẹ́ẹ̀.
Mìmì kan ò ní mi ẹgbẹ́ òṣèlú APC, digbí ni ó wà tí yóò sì borí – Nicholas Ukachukwu.
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti kí gómìnà àtúnyàn ti ìpínlẹ̀ Anambra; Chukwuma Soludo kú oríire àtúnyànsípò rẹ̀ fún sáà kejì ó sì tún ṣe ìlérí pé ìjọba àpapọ̀ yóò fún un ni gbogbo àtìlẹ́yìn pátápátá porogodo.
Ààrẹ ṣe àpèjúwe ìṣèjọba Soludo gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà àbáyọ fún àwọn aráàlú, dájúdájú, ìwé kíkà ní ipa rere nínú ìṣèjọba tó yaranti.
Bákan náà ni ààrẹ ṣe ìrántí àbẹ̀wò tó ṣe sí ipínlẹ̀ Anmabra lóṣù Èbìbí ńgbà tó lọ ṣí àwọn àkànṣe iṣẹ́ tí Soludo ṣe sí ìpínlẹ̀ náà, mi ò le gbàgbe àwọn iṣẹ́ bàǹtàbanta tó o gbéṣe ní Anambra.
Ààrẹ kí Gómìnà Soludo káre fún ṣíṣe àmúlò ọgbọ́n, òye, oore-ọ̀fẹ́, làákàyè àti ìbáwí nínú ìṣèjọba rẹ̀ ní èyí tó jẹ́ kí oríkì ó ro ìpínlẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi ìmọ̀lẹ̀ orílẹ̀-èdè.
Mo ṣe ìlérí fún ọ Soludo pé ìjọba àpapọ̀ yóò tì ọ́ lẹ́yìn gbọ̀ngbọ̀n láti ṣe àṣeyọrí – ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Ní báyìí, ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti gbé oríyìn fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu pé ó hu ìwà àgbà rere nínú ètò ìdìbò náà.
Bákan náà ni ààrẹ tún fi ìwà òtítọ́ yìí hàn nínú ìyànsípò ọ̀gá àgbà ilé ìwé UNIZIK:
Ilé ìwé gíga Nnamdi Azikiwe tó wà ní Awka tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Anambra ti yan ọ̀gá àgbà titun báyìí. Ọ̀gá àgbà titun náà ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Bond Anyaechie.
Ìyànsípò yìí wáyé lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n yọ ẹni tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yàn sípò náà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Bernard Odoh ni ààrẹ yàn lọ́gàá UNIZIK àmọ́ kò bá àwọn adarí ilé ìwé náà lára mu.
Àjọ àwọn olùkọ́ yarí kanlẹ̀, wọ́n ní Ọ̀jọ̀gbọ́ Bernard Odoh kò ní ìwé ẹ̀rí tó kúnjú fún ipò náà àti wí pé ìyànsípò rẹ̀ ní ọwọ́ kan ejò nínú nítorí kò ṣe àwọn ìdánwò àti àwọn ohun mìíràn tó yẹ kó ṣe.
Lẹ́yìn gbogbo fàǹfà, wọ́n yọ Ọ̀jọ̀gbọ́n Bernerd nípò náà wọ́n sì ti yan Ọ̀jọ̀gbọ́n Bond báyìí.
Alága àwọn adarí ilé ìwé náà; Olugbenga Kukoyi sọ nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ pé àwọn tọ gbogbo ọ̀nà tó yẹ kí àwọn tó yan Ọ̀jọ̀gbọ́n Bond ni, ó ní ìyànsípò rẹ̀ kò ní kọ́lọ́fín nínú.





