Èèyàn márùn-ún kú nínú ìkọlù tó wáyé ní Ikire – Kò dín ní àwọn èèyàn márùn-ún tó rọ̀run àṣàǹte nínú ìkọlù tó wáyé ní ibùdókọ̀ Naira and Kobo ní Ìkirè. Awakọ̀ méjì àti àwọn èrò mẹ́ta ló ṣe àlábàápàdé ikú òjijì náà.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ibùdókọ̀ náà ti wà ní abẹ́ ìṣàkóso àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣaajú àsìkò yìí, aago mẹ́wàá ààbọ̀ àárọ̀ òní ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Accord yá dé tí wọ́n sì fẹ́ gba ìṣàkóso ibùdókò náà padà.
Nínú àwòrán tí a rí ni ọkùnrin kan ti jókòó síwájú ọkọ̀ kan pẹ̀lú àpá ní orí rẹ̀, a rí òmíràn náà nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ nílẹ̀. Bákan náà ni wọ́n ba ọkọ̀ tí Hilux ti àgọ́ ọlọ́pàá Ikire jẹ́ yányán. – Èèyàn márùn-ún kú nínú ìkọlù tó wáyé ní Ikire
Nínú àlàyé náà ni a ti gbọ́ pé wọ́n yìnbọn pa ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Accord kan. Lẹ́yìn náà ni wọ́n lọ sí ààfin Akire lọ fi ẹjọ́ sùn pé DPO àgọ́ ọlọ́pàá Ikire lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà. Wọ́n tún gbé akọ̀wé ẹgbẹ́ elépo Ikire lọ pẹ̀lú.
Lẹ́yìn tí gbogbo èyí rọlẹ̀ ni àwọn ará ìlú tú síta ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn, ariwo DPO Ikire ni wọ́n mú bọ ẹnu tantan.
A kò ní jẹ́ kí etí yín di sí bí ó bá ṣe jẹ́, a kò ríi jù báyìí lọ lásìkò yìí ná.- Èèyàn márùn-ún kú nínú ìkọlù tó wáyé ní Ikire
Láti ìgbà tí wọ́n ti di ìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni nǹkan kò ti fara rọ ní ìpínlẹ̀ náà. Láàrin àsìkò náà ni wọ́n yìnbọn mọ́ ọkọ̀ Gómìnà Adeleke tó jáwé olúborí ní Òṣogbo:
Àwọn jàǹdùkú kan yin ìbọn mọ́ ọkọ̀ akọ́wọ̀ọ́rìn Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun; Ademola Nurudeen Jackson Adeleke nígbà tí ó ń darí bọ̀ láti ààfin Ata ọjá ti Òṣogbo.
A gbọ́ pé Gómìnà ṣe àbẹ̀wò sí ààfin Ata ọjá lẹ́yìn tí ó gba ìwé ìyànpadà sípò nílé iṣẹ́ INEC, Òṣogbo. Ní kété tí ìpàdé náà parí tí Ata ọjá sì ṣe àdúrà ìparí ni ìró ìbọn bẹ̀rẹ̀ sí ní ró lákọlákọ nínú gbọ̀ngán ìpàdé náà.
Lásìkò yìí, Gómìnà Adeleke àti àwọn ẹmẹ̀wàá rẹ̀ ti gba ẹnu ọ̀nà mìíràn jáde, ó tilẹ̀ ti dénú ọkọ̀ rẹ̀ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ní yìnbọn náà.
Ẹnìkan tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé àwọn jàǹdùkú náà ti gbọ́ pé Gómìnà yóò ṣe àbẹ̀wò sí Ata ọjá wọ́n sì wá dúró dè é. Ọkọ̀ Sienna kan tí kò ní ìwé ìforúkọsílẹ̀ ni wọ́n gbé wá láti Ita olokan wá sí Òṣogbo.
Ó tó bíi ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n kí ìró ìbọn náà tó rọlẹ̀, àwọn ẹ̀ṣọ́ Gómìnà kojú wọn, wọ́n sì padà sá lọ. Bákan náà la gbọ́ pé wọ́n fi ìbọn já ilẹ̀kùn ààfin wọlé ni.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n tún lọ dá ọkọ̀ Gómìnà lọ́nà ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ àmọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ Gómínà ṣọkọ fún wọn wọ́n sì sá gba ọ̀nà Iléṣà sá lọ.
Àwọn ọlọ́jà ti ìsọ̀ wọn pẹ̀lú ìbẹ̀rùbojo, oníkálukú sá lọ sí ilé rẹ̀ nínú ìbẹ̀rù kí ọta má bà wọ́n.
Kọmíṣọ́nà fún ìfitónilétí; Kolapo Alimi fìdìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé kò sí ẹni tó farapa nínú ìkọlù náà àti pé Gómìnà mórí délé láyọ̀ àti àlàáfíà.
Ṣaajú ìdìbò náà ni wọ́n gbé Igbalaye àmọ́ wọ́n dá a sílẹ̀:
Teslim Igbalaye jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọlọ́wọ́ ọ̀tún Gómìnà Ademola Adeleke ti ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Ọjọ́rú ni àwọn ọlọ́pàá ya bo ilé Igbalaye tí wọ́n sì gbé e lọ sí àgọ́ wọn. Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án náà ni pé ó gba afurasí ọ̀daràn kan tí wọ́n ń wá sílé, owó tó lé ní mílíọ́nù mẹ́rin náírà ni wọ́n ní àwọn bá nílé rẹ̀, bákan náà ni wọ́n ní àwọn bá àwọn káàdì ìdìbò tí àwọn jàǹdùkú jí kó nílé rẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun wí pé gbogbo àwọn nǹkan tí wọ́n bá nílé Igbalaye yìí tọ́ka sí pé ó lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ó sì ń múra àti ra ìbò lọ́jọ́ ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà.
Láti ìgbà tí wọ́n ti gbé Igbalaye ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun; Ademola Adeleke ti kàn sí ọ̀gá ọlọ́pàá àgbà láti gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò.
Ní báyìí, wọ́n ti dá Igbalaye sílẹ̀ lẹ́yìn tí ọ̀gá ọlọ́pàá àgbà dá sí ọ̀rọ̀ náà. Agbẹnusọ fún ikọ̀ ìpolongo ìbò Ìmọ́lẹ̀; Pelumi Olajengbesi ló fi ìdásílẹ̀ Igbalaye tó àwọn akọ̀ròyìn létí.
Olajengbesi kọ ọ́ sí ojú òpó Facebook rẹ̀ pé ‘A dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀gá ọlọ́pàá àgbà ilẹ̀ yìí àti kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tí wọ́n gba èrò wa rò lórí ọ̀rọ̀ Igbalaye tí wọ́n gbé lọ́nà tí kò bá òfin mu. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò ní máa wòran kí ìyà ó jẹ aráàlú lọ́nà àìtọ́. Káàbọ̀ padà Olóyè Teslim Igbalaye, o kú akitiyan àti ìfọmọnìyànṣe.’
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun náà fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ti dá Igbalaye sílẹ̀. Agbẹnusọ wọn; Abiodun Ojelabi ló fi èyí léde.
Ojelabi wí pé àwọn márùn-ún ni wọ́n kó pẹ̀lú Igbalaye lọ́jọ́ tí wọ́n lọ ká a mọ́lé náà. Ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n bá nílé Igbalaye jẹ́ afurasí ọ̀daràn kan tí wọ́n ti ń wá tipẹ́ fún àwọn ọ̀ràn tó pọ̀ díẹ̀, orúkọ rẹ̀ ni Oladele Abiodun.
Ọ̀rọ̀ Ojelabi tẹ̀síwájú pé àwọn bá owó tó lé ní mílíọ́nù mẹ́rin náírà ni wọ́n bá nílé Igbalaye, ọ̀pọ̀lọpọ̀ káàdì ìdìbò, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kan, ẹ̀rọ kọ̀m̀pùtà alágbèéká kan àti àwọn nǹkan mìíràn.
Gbogbo àwọn nǹkan yìí ṣì wà ní àgọ́ àwọn ọlọ́pàá fún àyẹ̀wò fínní. Ìdí ni pé àwọn nǹkan yìí mú ìfura dání lórí ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà. Èyí ni yóò mú kí àwọn ó ṣe ìwádìí lórí bóyá Igbalaye ń ṣètò àti ra ìbò lọ́jọ́ ìdìbò nípa híhá owó tí wọ́n bá nílé rẹ̀ náà. Bákan náà ni àwọn tún le fi ẹ̀sùn ìlẹ̀dí-àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀daràn lórí ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà náà nípa pé ó gba àwọn afurasí ọ̀daràn sílé.
Agbẹnusọ fún ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun náà sọ sí ọ̀rọ̀ yìí; Adewale Egbedun wí pé kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ló pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó lọ gbé Igbalaye.
Ibrahim Gotan pàṣẹ yìí lẹ́yìn tó dé láti ìpàdé pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìdìbò INEC nítorí pé Igbalaye ń rẹ̀rìn-ín ní́bi ìpàdé náà.
Ìgbà tí Igbalaye yóò fi délé ni ìròyìn ti kàn án lára pé àwọn ọlọ́pàá ti yí ilé rẹ̀ po.
