Eéfín Iná Gba Emí Arákùnrin Kan Nínú Iyẹ̀wù Rẹ̀ . Arákùnrin Tolú Falansa, ẹni ọdún mẹ́tadílọ́gbọ̀n tí ó ń gbé ní Owódé-Yewa ni ó ti di ẹni àná látàrí bí ọ̀kadà rẹ̀ ṣe gba iná nínú yàrá rẹ̀ tó ń tọ́jú rẹ̀ sí.
Inú ìyẹ̀wù ni Tolu àti àlùpùpù rẹ̀ jọ ń sùn, kò sí ẹni tó mọ̀ pé ó ti kú sínú yàrá rẹ̀ títí di ọjọ́ kẹta tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjì kan wá bẹ̀ẹ́ wò kan òkú rẹ̀ gèlètè nílẹ̀.
https://gmlyrics.com/emi-ba-negberun-ahon-yoruba-hymn/
https://iweiroyinyoruba.com/ajo-ko-ni-dun-titi-konile-ma-rele/
Alábàágbé rẹ̀; Kafaya bá àwọn ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ pé àwọn ará ilé kò fura rárá pé Tolu kò jáde síta fún bíi ọjọ́ mẹ́ta kí ó tó di pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá bèèrè rẹ̀ tí òun sì nawọ́ yàrá rẹ̀ sí wọn.
Ohun tí àwọn ọlọ́pàá fura pé ó gba ẹ̀mí rẹ̀ náà ni èéfín tó tú jáde láti ara ọ̀kadà rẹ̀ tó jóná náà ó fà símú tó sì gba ẹ̀mí rẹ̀.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ́ Ogun; Odutola Omolola fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé wọ́n ti gbé òkú arákùnrin náà lọ sí ilé ìgbókùúsí ti ìlàròó.