Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti rọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí tí wọ́n jápa lọ sí òkè òkun pé kí wọn darí wálé, àjò kìí dùn bí ilé àti wí pé ilé náà làbọ̀ ìsinmi oko.
Ó wí pé orílẹ-èdè Nàìjíríà ti kúrò ní bí wọ́n ṣe fi sí nígbà tí wọ́n jápa lọ sí òkè òkun, Nàìjíríà ti dára gan-an ni ó sì tún ti gòkè àgbà báyìí.
Ààrẹ sọ èyí níbi àpéjọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó wà ní Yokohama, Japan.
Olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí ìfitónilétí; Bayo Onanuga ló bu ọwọ́ lu àtẹ̀jáde yìí, nínú rẹ̀ la ti kà á pé ìṣèjọba Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti ṣe àtúnṣe sí ọrọ̀ ajé tó mẹ́hẹ ṣáájú kí ó tó gorí ipò, ó sì ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn àtúnṣe tí yóò pèsè iṣẹ́ lọ́pọ̀ yanturu, òkòwò ati àwọn ohun amáyédẹrùn.
Ọ̀rọ̀ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tẹ̀síwájú pé ‘Inú mi dùn láti ríi pé àwọn ọmọ Nàìjíríà kọ̀ọ̀kan ti ń darí wálé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan takú sí òkè òkun, a kò le fi ipá gbé wọn wálé nítorí pé òfin fi ààyè gba kí èèyàn ó gbé ibi tó wù ú.
Àmọ́ mo rọ̀ yín, nítorí ọrọ̀ ajé àti ìdàgbàsókè Nàìjíríà, ẹ má takú sí òkè òkun, ẹ padà wá sílé.
Bí ẹ bá kọ̀ látì wá kó ipa yín nínú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè yín, ta ni yóò bá a yín ṣe é?
Ìṣèjọba mi ti pèsè ètò ìlera tó péye láti dẹ́kun lílọ gba ìtọ́jú lókè òkun bẹ́ẹ̀ sì ni ọrọ̀ ajé ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.
Ẹ kò le dá ìdàgbàsókè ìlú dá ìjọba nìkan, ẹ máa bọ̀ nílé kí ẹ wá kópa, ẹ fi ẹnu rere sọ ọ̀rọ̀ Nàìjíríà.
Bí ẹ bá takú sí òkè òkun tí ẹ kò bá wálé wá kópa nínú ìṣèjọba yìí, á jẹ́ pé a kùnà nínú adarí ọjọ́ ọ̀la tí a ní a ń tọ́’ èyí ni àwọn ohun tí ààrẹ sọ.
Lẹ́yìn tí ààrẹ gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ké sí Mínísítà fún ìdásílẹ̀ àti àmójútó àwọn ilé iṣẹ́; Aṣòfin John Enoh àti igbákejì alága ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti àwọn ohun amáyédẹrùn; Khalil Suleiman Halilu láti ṣe àlàyé ibi tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu bá iṣẹ́ ìdàgbàsókè Nàìjíríà dé.
Wale Tinubu; ẹni tó jẹ́ àna ààrẹ Tinubu náà ṣe àlàyé bí àtúntò ètò òkòwò tí ààrẹ ṣe ṣe mú àyípadà rere bá ọrọ̀ ajé ilẹ̀ wa tí àwọn oníṣòwò sì ń ti orílẹ-èdè wọn wá ṣòwò ní Nàìjíríà.
Ààrẹ ẹgbẹ́ ọmọ Nàìjíríà tó wà ní Japan; Emeka Ebogota dúpẹ́ lọ́wọ́ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fún ṣíṣe àtìlẹ́yìn fún wọn àti àwọn àgbékalẹ̀ amáyédẹrùn tó ṣètò rẹ̀.
Láti kín ohun tí ààrẹ sọ nípa pípèsè àwọn ohun amáyédẹrùn yìí lẹ́yìn, ó ṣe pàtàkì láti sọ nípa àkànṣe iṣẹ́ omi tí ìjọba pèsè fún wọn ní abúlé Karu.
Mínísítà fún olú ìlú wa; Nyesom Wike ló lọ ṣí asọ lójú omi naa.
Báyìí ni ìròyìn náà ṣe lọ:
Mínísítà fún olú ìlú wa Nyesom Wike ti tú pẹrẹpẹ́ẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ lórí àwọn ànfààní tó wà fún ẹni tó bá ṣe àtìlẹ́yìn fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lórí ìdìbò ọdún 2027.
Wike ṣe àlàyé pé ìrọ̀rùn ló wà fún gbogbo ẹni tó bá ṣe ti Tinubu nígbà tí àwọn alátakò rẹ̀ yóò jẹ ìyà bíi iyán.
Ní abúlé Karu, níbi tí wọ́n ti lọ ṣí àkànṣe iṣẹ́ omi tí wọ́n ṣe fún wọn ní abúlé náà ni Wike ti sọ pé:
‘Ẹ tẹ̀lé ẹni tó mọ̀nà, ẹ ṣe ti àwọn tí ìjọba yóò gba ọ̀rọ̀ wọn yẹ̀wò, àwa ni a le bá ààrẹ sọ̀rọ̀ tí yóò sì ṣe ohun tí ẹ bá fẹ́. Gbogbo awọn tó ti ṣe ìjọba sẹ́yìn, ìlérí lásán ni wọn yóò ṣe fún yín, kò sí èyí tó pèsè ohun amáyédẹrùn fún yín ní abúlé yìí, ṣé ẹ̀yin náà ti rí ìyàtọ̀ láàrin ìṣèjọba wọn àti ti ààrẹ Tinubu?
Ìbẹ̀rẹ̀ ní omi tí a ṣe fún yín yìí, a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni, gbogbo àwọn ọ̀nà tó wọ abúlé yìí ni a ó ṣe tí yóò máa yọ̀ kùlùlù, a ti bá ilé iṣẹ́ iná ọba sọ̀rọ̀ lórí bí ẹ ó ṣe máa ní iná tí kò ní lọ rárá tọ̀sán tòru.
Mo kí alága ìjọba ìbílẹ̀ yín fún iṣẹ́ takuntakun tó ń ṣe, gbogbo ipá rẹ̀ ló sà láti mú kí ìdàgbàsókè ó bá abúlé yìí, bí ẹ bá le dìbò fún un lẹ́ẹ̀kan síi, ẹ̀yin náà yóò rí bí ìdàgbàsókè yóò ṣe bá ìlú yín tó.
Ẹni tó bá ṣe ti ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ni èmi yóò ṣe àtìlẹ́yìn fún, nítorí pé ìṣèjọba rẹ̀ ló le so èso rere.
Nípa ojú ọ̀nà tí ẹ wí pé kò dára yẹn, ẹ gbà pé ó ti di ṣíṣe, lọ́gán tí alága yín bá ti wọlé ẹlẹ́ẹ̀kejì ni a ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí rẹ̀.
Ẹ̀yin náà ríi pé alága yín ló mú ìjọba wá ṣe títì Saburi, Kakuba-Kakushere, àti títì Deidei. Ohun tí ó bá sọ fún wa ni a ó ṣe, nítorí náà kí ẹ dìbò fún un.
A ti bá a yín ṣe àdéhùn pé bí ẹ bá dìbò fún alága yín lẹ́ẹ̀kejì, a ó pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn fún un yín, ó wá kù sọ́wọ́ yín láti pín àdéhùn yìí kí àwa náà ó le mú ìlérí wa ṣẹ.
Èyí já sí pé àwọn tí kò bá ti fi ọwọ́ sòwọ́pọ̀ tàbí ṣe àtìlẹ́yìn fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu kò ní ní anfààní sí àwọn ohun amáyédẹrùn.
Ṣé bẹ́ẹ̀ ló yẹ kó rí?





