ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn

Ẹ MÁ SỌ ÌRÈTÍ NÙ BÍ A ṢE Ń WỌ INÚ ỌDÚN TITUN LỌ – AGBẸNUSỌ FÚN ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢOJÚṢÒFIN RỌ ÀWỌN ỌMỌ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ.

Àti àwọn ìròyìn mìíran tó gbòde.

by Adeola Olanrewaju
January 3, 2026
in Ìròyìn, Ìròyìn Agbègbè, Ìròyìn Tó Gbòde
0
ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.
0
SHARES
7
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Agbẹnusọ fún ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin; Tajudeen Abass ti rọ gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti má sọ ìrètí wọn nú bí ọdún yìí ṣe parí.
Ó wí pé ìrètí yín ní láti dúró ṣinṣin kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìṣèjọba Nàìjíríà.
Ẹ fi ọkàn rere, àfojúsùn rere àti ìgbàgbọ́ wọ inú ọdún 2026 fún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdojúkọ nínú ọdún 2025 tó parí yìí, a ti ṣe ọ̀pọ̀ àṣeyọrí pàápàá lórí kíkojú ìgbésùnmọ̀mí àti ìfẹ̀míṣòfò. Ẹ jẹ́ kí a fi ìmọ̀ ṣọ̀kan nínú ọdún tí a fẹ́ nawọ́ mú yìí kí a le ṣe àṣeyọrí.
Àwọn àlàkalẹ̀ tí a ní fún ọdún tó ń bọ̀ yóò mú kí Nàìjíríà ó gòkè àgbà, ètò ààbò yóò dúró ṣinṣin, oúnjẹ yóò pọ̀ janturu, ọrọ̀ ajé yóò dúró wámú, ìlú yòó sì tòrò. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yín ni ìjọba nílò kí ó le ṣe é ṣe.

ÈTÒ ÀÀBÒ TÓ MẸ́HẸ DÁN WA WÒ NÍ ỌDÚN 2025 ÀMỌ́ A KÒ YẸSẸ̀ – GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ NIGER.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger; Muhammed Bago ti bá àwọn ará ìlú rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí bí ìṣèjọba rẹ̀ ṣe lọ lọ́dún yìí àti ètò tó ní fún wọn lọ́dún tó ń bọ̀ ìyẹn ọdún 2026.
Bago ṣe àlàyé pé ìjínigbé, ìgbésùnmọ̀mí àti ètò ààbò tó mẹ́hẹ ló fẹ́ mi ìṣèjọba òun wò lọ́dún yìí àmọ́ òun dúró ṣinṣin, òun kò jẹ́ kí èyí ó pa ìṣèjọba òun lára tàbí da ètò òun rú, òun dúró wámú òun sì kojú rẹ̀ láti ṣe àṣeyọrí ní ìpínlẹ̀ náà.
Ó gbé oríyìn fún àwọn ará ìpínlẹ̀ Niger tí wọ́n dúró ní ìṣọ̀kan, ìrẹ́pọ̀ àti ìgbàgbọ́ nínú ìṣèjọba rẹ̀. bago rọ àwọn èèyàn rẹ̀ láti má dẹ́kun àtìlẹ́yìn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn lọ́dún tó ń bọ̀, ó ní òun ti ṣètò àlàkalẹ̀ lórí ìṣèjọba rere, ètò ààbò, ọrọ̀ ajé àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ fún ọdún 2026.
Mo kí gbogbo ẹ̀yin ará ìpínlẹ̀ Niger àti ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀ kú ìpalẹ̀mọ́ ọdún titun nínú èyí tí ìrètí wa ó ti di ọ̀tun.
Ọdún tó parí yìí jẹ́ ọdún tó dán ìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀kan wa wò pàápàá nípa ti ètò ààbò tó mẹ́hẹ àmọ́ mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ yín fún ìgbàgbọ́ tí ẹ ní nínú ìṣèjọba mi.
Ìjọba nìkan kò le dá ìlú ṣe bíkòṣe pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yín, a gbọdọ̀ wà ní ìrẹ́pọ̀ àti ìṣọ̀kan kí a le tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀.
Mo fi ń dá a yín lójú pé ìṣèjọba mi wà fún ìlọsíwájú, ààbò, àti gbogbo ohun tó le mú kí ayé yín dẹrùn – Gómìnà Muhammed Bago.

ÌJÀM̀BÁ ỌKỌ̀ OJÚ OMI TI MÚ Ẹ̀MÍ MẸ́FÀ LỌ NÍ ÈKÓ.

ADVERTISEMENT

Àwọn èèyàn mẹ́fà ló ti kú sínú omi nígbà tí ọkọ̀ ojú omi kan tó kó èrò mẹ́wàá dànù sínú alágbalugbú ní Igbologun chanel, Èkó.
Ọjọ́ ìṣẹ́gun, ìyẹn àná ni ọkọ̀ ojú omi náà gbéra ní etídò Ilashe ní déédé agogo mẹ́jọ àbọ̀ alẹ́ kó tó di pé ó dànù sódò.
Lọ́gán ni àwọn òṣìṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì inú omi dé síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà nígbà tí wọ́n gba ìpè pàjáwìrì, wọ́n rí àwọn èèyàn mẹ́rin yo láàyè wọ́n sì gbé wọn lọ sí ilé ìwòsàn, òkú àwọn mẹ́fà yòókù ni wọ́n rí yọ.

INÁ JÓ ỌJÀ ARENA NÍ BOLADE, OṢÒDÌ, ÈKÓ.

Nígbà tí iná tó jó ní ọjà Balogun ti wọ ọjọ́ kẹfà tó dẹ̀ ṣì ń jó lọ́wọ́ nínú ilé ìdójútòfò Great Nigeria, ọjà Arena ní Bolade, Oṣòdì náà ti gbaná.
Ìsọ̀ mẹ́wàá ló ti kanlẹ̀ báyìí, àwọn panápaná ló kápá rẹ̀ kò ní òun ò jó ju bẹ́ẹ̀ lọ.
Aṣọ ni wọ́n ń tà ní àwọn ìsọ̀ tó jó yìí, àwọn aṣọ ní ìdì-ìdì fún àwọn aláràtúntà ló jó gúrúgúrú.
Ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Èkó sọ̀rọ̀ láti ẹnu ọ̀gá àgbà; Magaret Adeseye pé nǹkan bíi aago mẹ́fà ku ìṣẹ́jú mẹ́wàá ní ìrọ̀lẹ́ àná ni àwọn gba ìpè pàjáwìrì lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Láàrín ìṣẹ́jú márùn-ún ni àwọn panápaná ti dé ibẹ̀ láti kojú rẹ̀. àwọn panápaná ẹ̀ka Bolade, Ikeja, Ilupeju àti Alausa ni wọ́n jọ kojú iná náà tí wọ́n sì pa á fínfín àmọ́ ìsọ̀ mẹ́wàá ti kanlẹ̀ lásìkò náà.

ÌYÁ KAN PÀDÁNÙ ỌMỌ MẸ́FÀ NÍNÙ ÌJÀM̀BÁ INÁ.

ADVERTISEMENT

Abúlé Mangu ní ìpínlẹ̀ Plateau rò gógó látàrí ìjàm̀bá iná tó mú ọmọ ìyá mẹ́fà lọ.
Saidu Nasir; ẹni tó jẹ́ ará àdúgbò ló ṣe àlàyé pé ìyá náà àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́sàn-án wà nínú ilé wọn, wọ́n ń wo ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán ní nǹkan bíi aago mọ́kànlá alẹ́, àwọn ọmọ mẹ́ta wọ yàrá lọ sùn ó ku ìyá àti àwọn mẹ́fà.
Nǹkan bíi aago méjì òru ni iná sẹ́yọ nínú ilé náà ní pálọ̀ tí àwọn ọmọ náà àti ìyá wọn sùn, kò sí ẹni tó le sọ pàtó ohun tó ṣe okùnfà iná náà àmọ́ kò pẹ́ tí iná ọba padà dé ni iná náà sẹ́yọ.
Gbogbo akitiyan àti dóòlà àwọn ọmọ náà já sí pàbó nígbà tí ìyá wọn náà fi ara pa nínú ìjàm̀bá náà.
Àwọn ọmọ tó kú náà jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́rin sí ọdún méjìlá, bàbá wọn kò sí nílé lálẹ́ ọjọ́ náà.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau; Caleb Mtfwang àti alága ìjọba ìbílẹ̀ Mangu ṣe àbẹ̀wò sí ilé yìí, wọ́n bá àwọn mọ̀lẹ́bí náà kẹ́dùn.

ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ MÚ ÌYÁ ÀTI ỌMỌ TÓ FẸ́ FI ỌMỌ ỌDÚN MẸ́WÀÁ ṢÈTÙTÙ.

Obìnrin kan àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé wọ́n gbìyànjú àti fi ọmọkùnrin kan ọmọ ọdún mẹ́wàá ṣe ètùtù.
Ilẹ̀ Olújìí ní ìpínlẹ̀ Òǹdó ni èyí ti wáyé níbi tí àwọn ọlọ́pàá já lu àwọn ẹni náà níbi tí wọ́n ti fẹ́ pa ọmọ náà fún ètùtù.
Adewale Jimoh; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Òǹdó ṣe àlàyé pé àwọn èèyàn ta àwọn lólobó pé àwọn fura sí ìyá àti ọmọ náà pé ìrìn wọn kò mọ́, àwọn ọlọ́pàá bá gbéra, wọ́n tọpasẹ̀ wọn wọ́n sì bá ìyá àti ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú babaláwo wọn níbi tí wọ́n ti fẹ́ lo ọmọ náà fún òògùn owó.
Àwọn ọlọ́pàá ti gba ọmọ náà kalẹ̀ wọ́n sì ti gbé e lọ sí ilé ìwòsàn. Maria àti ọmọ rẹ̀; Adewale jẹ́wọ́ pé àwọn fẹ́ fi ọmọ náà pèlò owó ni. Wọ́n ti wà ní àgọ́ ọlọ́pàá báyìí.

Ọ̀DỌ́ KAN TI KÚ SÍNÚ ODÒ ÌWẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀ṢUN.
Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a kò ní àǹfààní àti dárúkọ rẹ̀ ti kú sínú odò ìwẹ̀ ilé ìtura kan tó wá ní Owode-Ede ní ìlú Ẹdẹ, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
A gbọ́ pé ọmọ náà lọ sí ilé ìtura náà ní ọjọ́ ọdún titun, bí ó ṣe wá kú sínú odò ìwẹ̀ ni kò tíì yé ẹnikẹ́ni báyìí.
Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti ẹbí rẹ̀ ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ní ilé ìtura náà lọ́jọ́ Ẹtì pé àwọn fẹ́ àlàyé ikú tó pa ọmọ náà. Àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n dá síi tí kò fi di wàhálà lọ́jọ́ náà.
Ilé ìtura kò fi àlàyé kankan léde, àwọn ọlọ́pàá sì ní àwọn ń ṣe ìwádìí lọ́wọ́.

Facebook Comments Box

Related

ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ÀWỌN OBÌNRIN FI Ẹ̀SÙN ÌBÁLÒPỌ̀ KAN PÁSÍTỌ̀ CHRIS OKAFOR.

ÒJÍṢẸ́ ỌLỌ́RUN NI PÁSÍTỌ WA – ÀWỌN ỌMỌ ÌJỌ GBÈJÀ PÁSÍTỌ̀ CHRIS OKAFOR.

Recommended

Ìròyìn Jákèjádò.

ỌMỌ ỌLỌ́PÀÁ YÌNBỌN PA BÀBÁ RẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ANAMBRA.

11 months ago
TÈTÈ WỌ́ IGI LÉ ẸJỌ́ TÓ O DÁ FÚN SẸNẸTỌ NATASHIA , BÓ Ò BÁ FẸ́ RÍ ÌBÍNÚ ÒFIN: SERAP

TÈTÈ WỌ́ IGI LÉ ẸJỌ́ TÓ O DÁ FÚN SẸNẸTỌ NATASHIA , BÓ Ò BÁ FẸ́ RÍ ÌBÍNÚ ÒFIN: SERAP

1 year ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.