Olóyè Bode George; ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ igbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú alábùradà PDP fi èrò rẹ̀ hàn lórí àbá tí ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin gbé kalẹ̀ pé kí a dá àwọn ìpínlẹ̀ mọ́kànlélọ́gbọ̀n titun sílẹ̀.
Olóyè Bode George bá àwọn ikọ̀ akọ̀rọ̀yìn News agency of Nigeria sọ̀rọ̀ lónìí, nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ti sọ pé àbá ìdásílẹ̀ àwọn ìpínlẹ̀ titun náà kò ní anfààní kankan tí yóò ṣe nínú ìdàgbàsókè Nàìjíría bíkòṣe pé yóò dá kún ìṣoro tó wà nílẹ̀ ni.
Olóyè ṣe àlàyé pé ètò ìṣèjọba kan náà ni a ń lò pẹ̀lú ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí àwọn èèyàn wa ń sá lọ, ó ní a kò ṣe tiwa bí ìlú Amẹrika ṣe ń ṣe tirẹ̀ tó fi gún régé.
Ohun tó yẹ kí a ṣẹ ni kí ìjọba àpapọ̀ ó ró àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ lágbára, kí wọn ó le dá ṣe àmójútó àwọn ohun àlùmọ́nì ìlú wọn, kí wọn ó sì máa jábọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ bíi orí. Olóyè wí pé bí a kò bá ṣe èyí tó jẹ́ pé ìjọba àpapọ̀ ni gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ ó máa ganu sí lọ́dọ̀ kí wọn ó tó le dá nǹkan ṣe, a jẹ́ pé a kò tíì ṣetán tí a fẹ́ tún Nàìjíría tò nìyẹn.
Olóyè Bode George tẹ̀síwájú nínú àlàyé rẹ̀ pé kí wọn ó má tilẹ̀ sọ̀rọ̀ ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ titun ní ìtòsí òun rárá ni.
Bákan náà ni olóyè wí pé kí wọn ó ṣe àtúntò ìwé òfin ilẹ̀ Nàìjíría sí èyí tí yóò fún àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀ lágbára àti le dá nǹkan ṣe láìní máa dúró de ìjọba àpapọ̀.
Ọ̀rọ̀ olóyè yìí jẹ́ èsì sí àbá tí ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin gbé kalẹ̀ lọ́sẹ̀ tó kọjá pé kí a dá àwọn ìpínlẹ̀ mọ́kànlélọ́gbọ̀n titun kalẹ̀.
Àlàkálẹ̀ àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n dábàá àti dá sílẹ̀ náà ni ìpínlẹ̀ mẹ́fà ní àárín gbùngbùn Àríwá, ìpínlẹ̀ mẹ́rin ní ìlà oòrùn àríwá, ìpínlẹ̀ márùn-ún ní ìwọ̀ oòrùn àríwá, ìpínlẹ̀ márùn-ún ní gúúsù àti àwọn ìpínlẹ̀ titun méje ní ìwọ̀ oòrùn gúúsù.
Àbá náa wí pé wọn yóò ṣẹ̀dá ìpínlẹ̀ Okun, Okura àti Confluence láti ara ìpínlẹ̀ Kogi, ìpínlẹ̀ Benue Ara àti Benue Apa yóò jáde láti ara ìpínlẹ̀ Benue, ìpínlẹ̀ Adamawa yóò pọ ìpínlẹ̀ Amana, a ó ṣẹ̀dá ìpínlẹ̀ Katagum láti ara ìpínlẹ̀ Bauchi, ìpínlẹ̀ Savannah yóò ti ara ìpínlẹ̀ Borno jáde, ìpínlẹ̀ Taraba yóò pèse ìpínlẹ̀ Muri, ìpínlẹ̀ New Kaduna àti Gujarat yóò ti ara ìpínlẹ̀ Kaduna jade, ìpínlẹ̀ Tiga àti Ari yóò jáde láti ara ìpínlẹ̀ Kano, ìpínlẹ̀ Kebbi yóò pọ ìpínlẹ̀ Kainji, ìpínlẹ̀ adada yóò jáde láti ara ìpínlẹ̀ Enugu lẹ́yìn náà ni àwọn ìlú wọ̀nyìí; Etiti, Orashi, Orlu àti Aba yóò dá dúrò gẹ́gẹ́ bíi ìpínlẹ̀.
Kò tán síbẹ̀ o, àbá yìí wí pé a ó ṣẹ̀dá ìpínlẹ̀ Lagoon láti ara ìpínlẹ̀ Èkó, a ó ṣẹ̀dá ìpínlẹ̀ Ogoja láti ara Ìpínlẹ̀ Cross-River, ìpínlẹ̀ Warri láti ara ìpínlẹ̀ Delta, ìpínlẹ̀ Ori àti Obolo yóò jáde láti ara ìpínlẹ̀ Rivers, ìpínlẹ̀ Torumbe yóò jáde láti ara ìpínlẹ̀ Òndó, ìpínlẹ̀ Ìbàdàn láti ara ìpínlẹ̀ Oyo, ìpínlẹ̀ Ijebu láti ara ìpínlẹ̀ Ogun àti ìpínlẹ̀ Oke Ogun láti ara ààlà àwọn ìpínlẹ̀ Osun, Ogun àti Oyo.
Kí àbá yìí tó le di mímúṣẹ, ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin gbọdọ̀ fi ọwọ́ síi.
Ikọ̀ afẹ́nifẹ́re ló kọ́kọ́ tako àbá náà, wọ́n ní àbá yìí dàbí ìgbà tí èèyàn bá fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ tó wá ń pa làpálàpá ni o.
Akọ̀wé gbogbogbò fún ikọ̀ afẹ́nifẹ́re; ọ̀gbẹ́ni Abagun Kole Omololu wí pé àbá yìí tako ohun tí afẹ́nifẹ́re dúró fún nípa ìṣèjọba tó yanrantí. Ó ní ikọ̀ afẹ́nifẹrẹ̀; èyí tó ń ṣojú ẹ̀ya yoruba kò fara mọ́ irú àbákábǎ báyìí nítorí pé kò le tán àdojúkọ tí Nàìjíría ń kojú lọ́wọ́lọ́wọ́ bíkòṣe pé yóò dá kún un nnípa pé bùkátà tí Nàìjíría ó máa gbọ́ yóò tún wá pọ̀ síi.
Ikọ̀ afẹ́nifẹ́re ṣe àlàyé ipò tí àwọn ìpínlẹ̀ tó ti wà nílẹ̀ wà pé wọn kò le dá gbé bùkátà ara wọn, ìjọba àpapọ̀ ló ń gbé e, bí a bá wá ṣe àfikún àwọn ìpínlẹ̀, ṣé bùkátà kò ní pá Nàìjíría lórí?
Wọ́n gba ìjọba nímọ̀ràn láti gbé àbá yìí tì nítorí kò le so èso rere, wọ́n rọ̀ wọ́n láti ró àwọn ìpínlẹ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀ lágbára kí wọn ó le gbọ́ bùkátà ara wọn kí wọn ó sì máa jábọ̀ fún ìjọba àpapọ̀.
Ikọ̀ Arewa Consultative Forum tó ń sojú àríwá ilẹ̀ yìí náà tako àbá yìí. Akọ̀wé gbogbogbò wọn; Ọ̀jọ̀gbọ́n Tukur Muhammad- Baba wí pé ìpínlẹ̀ titun kọ́ ni a fẹ́ dá sílẹ̀ o, ìṣòro titun ni.
Wọ́n ní kò sí ànfààní kankan tí àwọn ìpínlẹ̀ titun yóò ṣe ju pé kí wọn ó jẹ́ àlékún bùkátà fún Nàìjíría.
Tukur wí pé àwọn tí wọ́n nífọ̀n léèkánná ni wọn yóò wà ní àwọn ipò náà tí wọn ó sì máa fẹlá ní tiwọn.
Gbogbo wa kò le sùn ká kọrí síbi kan náà, ààrẹ ikọ̀ ààrin gbùngbùn Nàìjíría; Dọ́kítà Bitrus Pogu fara mọ́ àbá yìí. Pogu sọ wí pé èyí yóò mú kí ìṣèjọba ó kárí nípa pé àwọn èèyàn ó le ṣojú ẹ̀kun wọn nínú ìṣèjọba.
Ó ṣe àpẹẹrẹ Borno pé ará gúúsù Borno kò tíì jẹ Gómìnà rí, àmọ́ bí ó bá pín báyìí, wọn yóò ní anfààní láti jẹ Gómìnà tiwọn.
Pogu wí pé ohun tí àwọn ti ń retí tipẹ́ ni èyí.
Àjọ tó ń ṣojú ẹ̀ya Igbo tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ohanaeze Ndigbo Worldwide wí pé kò yẹ kó jẹ́ ìpínlẹ̀ márùn-ún péré ni yóò kan ẹ̀ya Igbo.
Akọ̀wé gbogbogbò àjọ náà; Dọ́kítà Ezechi Chukwu wí pé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti máa ń yan ẹ̀ya náà jẹ, ó wí pé ẹ̀ya Igbo ni ìpínlẹ̀ rẹ̀ kéré jù, ṣé ó tún yẹ kí wọn ó fún wọn ní ìpínlẹ̀ márùn-ún péré lọ́tẹ̀ yìí.
Ní báyìí, olóyè Bode George kún àwọn èèyàn tó tako àbá ìdásílẹ̀ àwọn ìpínlẹ̀ titun yìí, ó wí pé ó dàbí ìgbà tí èèyàn bá fẹ́ fi òògùn ẹ̀tẹ̀ wo làpálàpá lásán ni kò leè so èso rere kankan.