Ilé ẹjọ́ ti ni kí olórin sàsusé, HABEEB OKIKIOLA OLALOMI lọ san owó ìtanràn mílíọ̀nù méjì fún ẹ̀sun oníkókó márùn-ún tí wọ́n fi kan òun àti àwọn jàndùkú rẹ̀ lóṣù yìí, ọjọ́ karùn ún ní ilé ọtí rẹ̀; ODÓGÚ tó wà ní ìlú Ọ̀tà ìpínlẹ̀ Ògùn. Ilé ẹjọ́ gíga ti ìlú Ìṣábọ̀ Abẹ́òkúta ìpínlẹ̀ Ògùn ni ìgbẹ́jọ́ náà ti wáyé lánàá látàrí bí ó ti na àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní ànàdojúbolẹ̀ tí ó sì dáwọn lọ́wọ́ kọ́ lẹ́nu iṣẹ́.
Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án náà ni ìdìtẹ̀mọ́jọ̀ba, Ìfìyàjẹni lọ́nà àìtọ́, Ìdínilọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba, lílo ohun ìjà olóró bíi ìbọn àti àdá pẹ̀lú ìwà jàgídíjàgan tó le è ṣekú pani.
Fùnra ara Portable náà ló lọ farahàn ní àgọ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹ̀lẹ̀múyẹ́ Pàntì ní ìlú Èkó lỌ́jọ́rú, ọ̀sẹ̀ yìí lẹ́yìn tí ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn fi ìwé síta pé àwọn ń wá olórin yìí. Kíá! ọlọ́pàá Èkó tarí rẹ̀ sí àgọ́ ọlọ́pàá Eléwéẹran tó wà ní Abẹ́òkúta ìpínlẹ̀ Ògùn lánàá. Ẹ̀sùn márùn ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọn fi kan HABEEB Òkìkì Ọlálọmí àti àwọn ẹmẹ̀ẹ́wa rẹ̀ , ó ní òun kò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà.
Àgbẹjọ́rò fún àwọn afurasí bẹ̀bẹ̀ pé kí ilé ẹjọ́ bojú àánú wo HABEEB OKIKI OLALOMI nítorí ó ti mọ ẹ̀bi rẹ̀ lẹ́bi, ọmọdé kìí mọ orí jẹ, kó má ráa lọ́wọ́, ó ti gbọ́n báyìí, kò sì ní dáṣọ irú rẹ̀ ṣorò mọ́.
Ọ̀gá Mágísíréètì O.L Ọ̀KẸ̀ ní kí HABEEB OKIKIOLA OLALOMI san owó ìtanràn mílíọ̀nù méjì pẹ̀lú onídùúró kan ṣoṣo, ó sì sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ karùn ún oṣù kẹta ọdún yìí. Portable nìkan kọ́ ló fojú ba ilé ẹjọ́, òun pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀ẹ́wa rẹ ló n bẹ látìmọ́lé ní ìpínlẹ̀ Ògùn. Àwọn Arúfin náà ni:
Nurudeen Waris; ọmọ ọdún mọ́kànlélógún
Adétọ́lá Alashe; ọmọ ọdún márùndínlọ́gbọ́n
Samuel Adélékè; ọmọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n
Olúwaṣeun Ayénúwà, ọmọ ọdún méjìdínlógún
Olúwapẹ̀lúmi Adéọ̀ṣun; ọmọ ogún ọdún
Gospel Kanu; ọmọ ogùn ọdún
Ìfẹ́olúwa Babátúndé; ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n àti
Arábìnrin Fatimo Muhammed, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn ní aláìnírònú àti oníjọ̀gbọ̀n ni HABEEB OLALOMI látàrí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án lóṣù yìí nípa lílù àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ẹ̀ka town planning ní ànàdojú bolẹ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ náà ni: ABIDEMI ONABANJO, RAHMON LATEEF àti AKINPẸ̀LÚ OYERÓ.