Gómìnà Ademolá Adélékè ti gba àwọn olóṣèlú nímọ̀ràn láti ṣe ohun gbogbo ni ìlànà òfin, bẹ́ẹ̀ náà ló tún pàrọwà fún àwọn olùdìbò kí wọ́n lọ ṣe ojúṣe wọn wọ́ọ́rọ́wọ́ ni ọjọ́ Àbámẹ́ta níbi ètò ìdìbò sí ìjọba ìbílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun.
Nínú ìkéde rẹ̀ ní ìlú Òṣogbo, gómìnà sọ ọ́ ní àsọyán pé àlàáfíà ti padà jọba ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun báyìí lẹ́hìn rògbòdìyàn tó ṣú yọ nítorí ìfipá gorí àlééfà ipò alága ìjọba ìbílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun tí àwọn alága ẹgbẹ́ APC tí wọ́n rọ̀ lóyè tẹ́lẹ̀ fẹ́ẹ́ ṣe. Àmọ́, báyìí ohun gbogbo ti tùbà-tùṣẹ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Ìpínlẹ̀ tí àlàáfíà ti ń jọba jù lọ ní ilẹ̀ Nàìjíríà.
Nígbà tó ń kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ẹbí tó pàdánù àwọn èèyàn wọn àti àwọn tó fara pa nínú rògbòdìyàn náà, gómìnà ní ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò dùn mọ́ni nínú yìí tún ránni létí pé kí á fààyè gba àlàáfíà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun ló ṣe Pàtàkì, tó sì ṣe kókó.
“Èmi pàápàá gbé òṣùbà ràbàǹdẹ̀ ọpẹ́ àti ìmọ rírì àwọn tó tẹ̀ lé ohun tí mo sọ pé kí wọ́n jìnnà sí sẹkitéríàtì ìjọba ìbílẹ̀ gbogbo nípìn-ínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Gbígba ìmọ̀ràn yìí ló jé kí ọ̀rọ̀ mọ bó ṣe mọ o.
” Ó ṣe mí láàánú láti tún sọ fún yín pé àwọn alága tá a ti rọ̀ lóyè yìí tún padà sí ọ́fíìsì náà ní Ọjọ́rùú – 19/02/25,wón sì fi tìpá-tìkúùkù já ilẹ̀kùn àbáwọlé ọ̀pọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ náà. Mo rọ gbogbo yín lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun láti jìnnà gédégédé sí gbogbo oríkò ìjọba ìbílẹ̀ tó wà ní Ìpínlẹ̀ yìí, kí ìforí-gbárí mìíràn má bàa tún ṣẹlẹ̀. Ìlànà òfin nípa ètò ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ náà la á fi yanjú ọ̀rọ̀ ní ìtúnbí-ìnùbí.
“Àwọn tí wọ́n ní àwọn ti gba ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ tó dá wọn padà sórí àlééfà yẹ kí wọ́n tún padà sílé ẹjọ́ láti tẹ̀ lé ìlànà òfin tó máa mú wọn bọ́ sórí ipò wọn lẹ́rọ̀, dípò tí wọ́n fi ń ṣe ohun gbogbo ní jàgídí-jàgan. Ètò ìdájọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà ní tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Tí ẹ bá ní ojúlówó ìwé ìdájọ́ tó dá yín padà sípò, ẹ tẹ̀ lé ìlànà ilé-ẹjọ́ láti mú un ṣẹ… “