Ìgbìmọ̀ onídàájọ́ ẹlẹ́ni mẹ́ta, tí Onídàájọ́ Wilfred Kpochi jẹ́ alága wọ́n ti kéde gbígbé ìdájọ́ wọn kalẹ̀ kàà lórí ìgbẹ́jọ́ ètò ìdìbò tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Edo ni èyí tí ẹgbẹ́ PDP pè lẹ́jọ́ tá ko èsì ìdìbò tó wáyé lórí rẹ̀, tó sì gbé ọmọ oyè ẹgbẹ́ òṣèlú APC wọlé gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà.
Lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kìn-ínni, oṣù kẹrin ọdún yìí 2025, ni ìgbìmọ̀ náà ti kéde pé kí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ tí ọ̀rọ́ kàn kóra jọ ní ọjọ́ kejì tíí ṣe Ọjọ́rùú, oṣù kẹrin ọdún yìí 2025.
Àmọ́ sí ìyàlẹ́nu àwọn aráàlú, òkú tí àwọn onídàájọ́ náà bò hẹ́hẹ́ ni ẹsẹ̀ rẹ̀ ti yọ síta yìí o. Kí ọjọ́ ìdájọ́ tóó pé ni wọ́n ti ń rí ẹ̀dà ìwé ìdájọ́ yẹẹríyẹ tó ti lu ìgboro pa lórí afẹ́fẹ́, tó sì tún fi bí èrò àwọn adájọ́ ṣe ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìdájọ́ wọn hàn.
Gẹ́gẹ́ bí àkọọ́lẹ̀ ìwé ìdájọ́ tó lùgboro pa, Alága ìgbìmọ̀ náà; Adájọ́ Kpochi àti onídàájọ́ mìíràn; A. B Yusuf gbé ìdájọ́ wọn kalẹ̀ láti ṣègbè lẹ́yìn Gómìnà Monday Okpebholo ti egbẹ́ APC; tí adájọ́ kẹta tí í ṣe Adájọ́ A. A Adewole ní òun ò fara mọ́ ẹjọ́ táwọn méjì àkọ́kọ́ dá rárá.
Nínú ìdájọ́ alásokan tirẹ̀, òún tilẹ̀ gbà pé Okpebholo kò kún ojú òṣùwọ̀n nínú ètò ìdìbò náà rárá nítorí àwọn àìṣedéédé tó gbalé-gboko lásìkò ètò ìdìbò náà. Ó sì pàṣẹ pé kí elétò ìdìbò (INEC) fún Ighodalo ní ìwé ẹ̀rí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà. A gbọ́ ọ pé Adájọ́ Adéwọlé gbé ìdájọ́ rẹ̀ lé orí ẹ̀rí pé elétò ìdìbò kò tẹ̀lé ìlànà àti òfin ètò ìdìbò gẹ́gẹ́ bí a ṣe là á kalẹ̀.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé ẹ̀rí ètò ìdìbò fi hàn pé gbogbo èsì ìdìbò tí Ighodalo ní jẹ́ ọ̀talérúgba-ó-dín-mẹ́rìndínlógún (243,113), nígbà tí Okpebholo ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní okòólérúgba-ó-dín-díẹ̀ (210,326) ìbò.
Ó tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn elétò ìdìbò kò ka ìbò ti ẹgbẹ́ PDP dáadáa, àti pé ẹ̀rí fara hàn pé èsì ìdìbò tí wọ́n kéde kò bójú mú un rárá ni.
Ní báyìí, kàyéfì ńlá tí aráàlú rí ni bí nǹkan ṣe ń lọ lórí irú ààbò àti ìpamọ́ tí wọ́n fún ìwé ìdájọ́ lórí ìgbẹ́jọ́ náà tí kò tí ì wáyé tó sì ti lùgboro pa láìtí ì gbé ìdájọ́ náà jáde. Irú orí ológbò wo làwọn èèyàn ń wò lórí àtẹ yìí o?
Ẹjẹ́ a fi ẹsẹ̀ kan dé ìpínlẹ̀ Benue níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti yapa kúrò lọ sínú ẹgbẹ́ ọ̀ṣèlú PDP. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ náà ni pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, LP àti NNPP tí iye wọn tó bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ló ti ya wọ inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Okpokwu ní ìpínlẹ̀ Benue.
Àwọn tó ya wọnú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP náà dẹ̀bi ọ̀rọ̀ ru ẹgbẹ́ tó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ náà pé wọn kò ṣe dáadáa láti ìpele ìjọba àpapọ̀ dé ìjọba ìbílẹ̀.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ìdarapọ̀ mẹ́gbẹ́ mìíràn, àwọn olórí ikọ̀ náà, Ona Idoko, John Adole, Onímọ̀ ẹ̀rọ Adegbo àti àwọn mìíràn sọ pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó ń ṣèjoba ti kùnà nínú ojúṣe wọn fárá ìlú. Wọ́n sì yòǹbó Aṣòfin Abba Moro ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fún akitiyan àti ìgbòkègbodò rẹ̀ lórí ìdàgbàsókè gúúsù Ìpínlẹ̀ Benue.
Wọ́n ní aṣáájú gidi àti Akin ọmọ ní í ṣe, tó ń là kàkà, tó sì ń ṣe aápọn fún ìlọsíwájú àwọn ènìyàn agbègbè rẹ̀, àti pé àwọn ń rí ipa rẹ̀ sí rere. ” A ń dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ látinú onírúurú ẹgbẹ́ tó wà yíká agbègbè wa nítorí ìríjú rere tí ẹ jẹ́ fágbègbè wa yìí nílé ìgbìmọ̀ Aṣòfin tẹ́ ẹ ti ń ṣojú àwa èèyàn yín. A ti rí ipa yín lára gbogbo àwa tí a wà ní gúúsù Benue, a sì ti wá rí i pé lóòótọ́ eegun bí eyín ṣọ̀wọ́n, pé kò sí irú aṣáájú bíi tiyín lágbègbè yìí o!” Alàgbà Moro, ẹni tí inú rẹ̀ẹ́ dùn dé ẹ̀yìn lọ́jọ́ náà fi dá ènìyàn náà lójú pé òjò ń rọ̀, ẹní kò tíì tó tàná ni òun yóò fi èrèǹjẹ ìjọba ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀ún ṣe fún gbogbo àwọn olùgbé agbègbè ibi tí òún ti wá.
Ayẹyẹ gbígba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ titun náà sínú ẹgbẹ́ PDP kún fọ́fọ́ fún àwọn èèkànléèkàn àwọn aṣojú olóṣèlú gbogbo tó wà ní ìpínlẹ̀ náà.
Ká padà sí ìpínlẹ̀ Edo tí a ti ń bọ̀;
Ọ̀rọ̀ ti jáde láti ẹnu ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta náà àṣẹ sì tẹ̀lé e. Ohun tí wọ́n sọ náà ni pé kí àwọn tó pe ẹjọ́ náà ó kó ilà kúrò lẹ́kọ nítorí pé ẹ̀kọ ò kọlà, ewé ló kọlà fún un.
Wọ́n ni kò sọ́rọ̀ nínú ẹjọ́ tí wọ́n pè náà, gbogbo atótónú wọn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀. Àti ẹjọ́ tí wọ́n pè tako Okpebholo, àti èyí tí wọ́n pè tako ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti èyí tí wọ́n pè tako àjọ èlétò ìdìbò ni ìgbìmọ̀ náà yí dànù pátápátá, wọ́n ní òfúùtùfẹ́ẹ̀tẹ̀; aásà tí kò ní kánhún nínú ni àwọn ẹjọ́ náà.
Ìgbìmọ̀ yìí pàṣẹ kí Gómìnà Okpebholo; ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ó máa bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ láì fọ̀tápè.
Ní báyìí, ojú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti ti Labour ti bó ní ìpínlẹ̀ Edo, ìgbìmọ̀ náà fi ojú wọn gbolẹ̀ kìí ṣe díẹ̀ nínú ìdájọ́ náà. Bóyá wọn yóò gba kámú ni o, bóyá wọn yóò tún gbé ẹjọ́ náà lọ ibi gíga ni o, a kò tíì le sọ.
Discussion about this post