Ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ wa ti sọ̀rọ̀ lórí ìbúgbàmù àdó olóró tó wáyé ní mọ́ṣálásí ní ìpínlẹ̀ Borno. Wọ́n ní ọmọ ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí Boko Haram kan ló so àdó olóró náà mọra lọ darapọ̀ mọ́ wọn ní mọ́ṣáláṣí.
Nǹkan bíi aago méje àṣálẹ́ ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù Ọ̀pẹ ni àdó olóró bú gbàmù ní mọ́ṣáláṣí Al-Adum tó wà ní ọjà Gamboru lásìkò tí wón gbé irun Magiribu dúró.
Àwọn èèyàn márùn-ún ló kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí àwọn márùndínlógójì mìíràn wà ní ilé ìwòsàn.
Ọ̀gágun Sani Uba ṣe àlàyé pé ìwádìí fi hàn pé ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram kan ló wà nídìí ẹ̀, òun náà sì pẹ̀lú àwọn tó kú náà.
Ó wí pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn ti kó àwọn tó farapa náà lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Maiduguri.
Wàyí o, dípò àwọn èèyàn márùn-ún tí àwọn ará mọṣáláṣí ní wọ́n kú, èèyàn méjì ni Ọ̀gágun Sani ní ó kú tí àwọn méjìlélọ́gbọ̀ sì wà ní ilé ìwòsàn.
Ilé iṣẹ́ ológun ní àwọn ti kó àwọn ọmọ ogun dà sí àdúgbò náà bìbà kí àwọn aráàlú ó fi ọkàn balẹ̀.
Ọ̀tun ni èyí jẹ́ nínú ìkọlù àwọn agbésùnmọ̀mí yìí, lára àwọn ìkọlù tó ti wáyé ní ilé ìjọsìn ni èyí tó wáyé ní Isapa:
A gbọ́ pé ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ajé ni àwọn agbébọn náà tí iye wọn ń lọ bíi ogún sí ọgbọ̀n ya wọ àdúgbò náà tí wọ́n yìnbọn lákọlákọ, wọ́n pín ara wọn káàkiri gbogbo àbáwọ inú ìlú náà pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ màálù.
Wọ́n tọ àárín ìlú náà tí wọ́n sì ń yìnbọn mọ́ gbogbo ilé, ojú ọta ìbọn kún ojú fèrèsé àti ògiri nígbà tí wọ́n lọ tán.
Àwọn èèyàn mọ́kànlá ni wọ́n kó lọ pẹ̀lú aláboyún kan, méje nínú wọn lọ jẹ́ mọ̀lẹ́bí kan.
Àwọn tí wọ́n kó lọ náà ni Talatu Kabiru; ọmọ ọdún mẹ́fà, Magaji; ọmọ ọdún mẹ́fà, Kande; ọmọ ọdún márùn-ún, Hadiza; ọmọ ọdún mẹ́wàá, Mariam; ọmọ ọdún mẹ́fà, Saima; ọmọ ọdún márùn-ún, Habibat, Fatima Yusuf, Sarah Sunday; aláboyún ẹni ọdún méjìlélógún, Lami Fidelis àti Haja Na Allah tó ń tọ́mọ lọ́wọ́.
Àwọn ará ìlú náà ṣe àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi èyí tó burú jáì, inú fu àyà fu ni àwọn èèyàn wà wọn kò sì mọ ohun tí yóò tún ṣẹlẹ̀.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ti fèsì pé àwọn ti kán lu igbó láti wá àwọn èèyàn náà jáde nínú igbó tó pààlà Isapa àti Eruku.
Ṣé iṣẹ́ ọwọ́ Bello Turji ni èyí? Ẹ rántí pé aáwọ̀ ṣẹlẹ̀ láàrin òun àti ìjọba lórí owó gbà-má-bínù nígba tó ní òun kò gba mílíọ́nù mẹ́ta náírà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò fún òun ní ọkọ̀ kankan o.
Lóòótọ́ ni àwọn aṣojú ìjọba bá àwọn ṣe ìpàdé àmọ́ wọn kò fún àwọn ní nǹkankan, bí òun ṣe wà yìí, òun kò dá ní mílíọ́nù márùn-ún náírà lápò.
Ọ̀rọ̀ yìí ni èsì sí ọ̀rọ̀ tí aṣojú ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara lọ́dọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí; Musa Kamarawa sọ pé gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara ìgbà náà fún Bello Turji ní mílíọ́nù mẹ́ta nạírà àti ọkọ̀ bọ̀gìnì láti ti ọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọ aṣọ.
Muhammad Matawalle ni gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara nígbà náà òun sì ni mínísítà fún ètò ààbò nísìn yìí.
Bello Turji ní òun fi orúkọ Allahu búra pé irọ́ ni wọ́n pa mọ́ òun wọn kò fún òun ní kọ́bọ̀ tàbí ọkọ̀ kankan, kódà, òun kò dá ní owó tí iye rẹ̀ tó mílíọ́nù márùn-ún náírà. Gbogbo ohun tí a ń ṣe kìí ṣe nítorí àpò tiwa, kò sí tiwa gan-an nínú ohun tí a ń ṣe wọ̀yìí.
Ó fi ẹ̀sùn kan Kamarawa pé ó dalẹ̀ àdéhùn wọn nígbà ìpàdé àlàáfíà náà, gbogbo ohun tí o ní oó fún wa ni a kò rí tó sì tún wá parọ́ pé a gba owó àti ọkọ̀.
Inú wa kókọ́ dùn nígbà tí ìjọba Zamfara yàn ọ́ ní agbódegbà wa nítorí pé a rò pé o ó ṣe tiwa àmọ́ ìwà ọ̀dalẹ̀ ni ó hù, o kò fún wa lówó kankan ó sì tún wá parọ́ pé o fún wa.
Gbogbo ohun tí a ń ṣe kò ní ọwọ́ ìṣèlú nínú bí àwọn èèyàn ṣe rò bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìmọtara-ẹni-nìkan nínú rẹ̀, àwọn ń ṣe ti àwọn fún Allah ni.
Bákan náà ló dá ìjọba lẹ́bi ètò ààbò tó mẹ́hẹ, ó ní gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto tẹ́lẹ̀’ Attahiru Bafarawa àti gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara tẹ́lẹ̀; Ahmed Yerima ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìgbésùnmọ̀mí kí Matawalle tó tẹ̀síwájú níbi tí wọ́n bá a dé.
Bello Turji ní Allah ni ẹlẹ́rìí òun lórí gbogbo oghun tí òun sọ yìí.
Àwọn ará Sokoto kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ dànù, wọ́n ní ọgbọ́n àti ète lórí ìdìbò ọdún 2027 ni gbogbo èyí tí ìjọba ń sọ tí Bello náà ń fèsì, wọ́n ní ọgbọ́n àti pín àwọn yẹ́lẹyẹ̀lẹ kí ìdìbò tó dé ni wọ́n ń dá pé kò sí èdè àìyedè láàrín wọn rárá.
Alhaji Sani Aliyu; ẹni tó jẹ́ adarí ìletò kan ní Sokoto ní kí ẹ má dá àti ìjọba àti Bello Turji lóhùn, eré ìtàgé ni wọ́n ń fi ẹ̀mí àwọn èèyàn ṣe, mẹ̀kúnnù ń kú lójoojúmọ́ nígbà tí àwọn olówó ń jiyàn ẹ̀bi.
Malam Abdullahi Bello náà sọ̀rọ̀, ó ní kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé ọgbọ́n ìdìbò ọdún 2027 ni wọ́n ń dá tí wọn fi ń sọ gbogbo èyí, lọ́gán tí wọ́n bá dé ipò tán ni ìfẹ̀míṣòfò ó tún burẹ́kẹ síi.
Gbogbo ohun tí Bello Turji sọ yìí kò ní kí ilé iṣẹ́ ológun ó yọ orúkọ rẹ̀ kúrò nínu àwọn agbésùnmọ̀mí. Bello jẹ́ ògbóǹtarìgì agbésùnmọ̀mí tí àwọn ológun ti fi orúkọ rẹ̀ síta tipẹ́ pé àwọn ń wá a.




