Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti sọ gudugbẹ ọ̀rọ̀ lórí ìdíjedupò ààrẹ ọdún 2027 lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú náà.
Wọ́n ní àwọn ló sọ pé eégún àwọn fẹ́ jó, bí àwọn bá ní kò jó mọ́, ẹnìkan ò le mú àwọn síi.
Àwọn ló sọ wí pé ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ni yóò díje dupò ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC lọ́dún 2027, èyí kò ti ilẹ̀kùn mọ́ ẹni tó bá wù láti díje dupò lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ náà ọ, ẹni tó bá wù ní ànfààní láti jáde.
Akọ̀wé ẹgbẹ́ òṣèlú APC gbogbogbò; Sulaiman Mohammad Argungu ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ lórí ìfòròwánilénuwò kan tó ṣe lọ́jọ́rú, ọ̀sẹ̀ yìí.
Argungu wí pé gbogbo àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti olórí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin; Godswill Akpabio ti fi ọwọ́ síi kí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ó díje dupò ààrẹ lọ́dún 2027 lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC nítorí iṣẹ́ rere tí ó ń ṣe.
Nítorí pé a jẹ́ egbẹ́ tó mọ òfin ìjọba alágbádá, a kò ní ti ilẹ̀kùn mọ́ ẹni tó bá wù láti díje dupò náà, a ó ṣe ìdìbò abẹ́lé láàrin àwọn tó bá jáde àti Tinubu, ẹni tó bá wá jáwé olúborí ni a ó fún ní ìwé ìdíje.
Ohun tí a kàn ń gbìyànjú àti sọ fún àwọn èèyàn ni pé yinni-yinni kẹ́ni ṣèmíì, ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti ṣe àwọn iṣẹ́ àkànṣe àti ìdàgbàsókè rẹpẹtẹ tó fi yẹ ká san ẹ̀san oore pẹ̀lú fífún un ní ànfààní láti ṣe sáà kejì, kò yẹ kí a fi ojú olóore gúngi.
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ni a fẹ́ kó díje lóòótọ́ àmọ́ bí a bá rí ẹni tí òun náà fẹ́ díje, a ó ṣe ìdìbò abẹ́lé. Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Sulaiman Mohammad Argungu sọ
Ṣáájú àkókò yíì náà ni Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti sọ fúnra lára rẹ̀ pé òun ń ṣètò ìgbé ayé ìrọ̀rùn fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Nàìjíríà.
Níbi ayẹyẹ ọdún kejì lórí ipò ni ó ti sọ wí pé ohun tí òun fi gbogbo ọdún méjì náà ṣe ni láti ṣètò ìpìlẹ̀ rere, ìpìlẹ̀ tó níkìmí fún ọjọ́ iwájú Nàìjíríà.
Ààrẹ wí pé ìjọba òun ti ṣètò ìgbé ayé ìrọ̀rùn, ètò ọrọ̀ ajé tó yè koro àti àtìlẹ́yìn fún àwọn ọmọ orílẹ̀-ède Nàìjíríà. Iṣẹ́ ìdàgbàsókè àti ìpìlẹ̀ rere náà ń tẹ̀síwájú.
Tẹrú tọmọ ti gbogbo mùtúmùwà ni yóò máa gbádùn bíi èèrà inú ṣúgà nígbà tí gbogbo rẹ̀ bá délẹ̀ tán.
Ẹ̀yin náà ṣá mọ̀ pé ìkòko tí yóò bá játa, dandan ni kí ìdí rẹ̀ ó gbóná, ààrẹ ò sùn bẹ́ẹ̀ sì ni kò wo lórí bí orílẹ̀-ède Nàìjíríà ó ṣe dùn yùngbà yùngbà. Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ààrẹ sọ.
Bákan náà ni ààrẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-ède Nàìíríà fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti àtìlẹ́yìn wọn, ó wí pé kò sí ohun tí òun le dá ṣe bí ẹ kò bá ṣe àtìlẹ́yìn fún òun. Ààrẹ wí pé kí ẹ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, kí ẹ má ṣe mikàn tàbí ṣiyè méjì nípa ìṣejọba òun, ìrọ̀rùn igi ni ìrọ̀rùn ẹyẹ, ìgbàgbọ́ yín ni ó le mú kí òun ó ṣe àṣeyọrí.
Ọ̀rọ̀ ààrẹ tẹ̀síwájú pé òun mọ rírí sùúrù àti ẹ̀mí ìfaradà tí ẹ ní lásìkò yìí, ó wí pé kí ẹ mọ̀ dájú pé gbogbo rẹ̀ ni yóò dẹ̀rọ̀ pẹ̀sẹ̀ pẹ̀sẹ̀ láìpẹ́ jọjọ. Ààrẹ wí pé orílẹ̀-ède Nàìjíríà tí kò ní jẹ gbèsè sí ilé ìfowópamọ́ àgbáyé tàbí jẹ orílẹ̀-èdè kankan lówó tí yóò sì le dá gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, pàápàá tí owó Náírà yóò gbera sọ tí yóò sì níyì ju owó òkè òkun lọ ni òun ń kọ́ lọ́wọ́ báyìí, nígbà tí òun bá sì ṣetán, gbogbo yín lẹ ó máa jó mùkúlú mùkẹ.
Ẹni tó ń parọ́ ni yóò wí pé ẹlẹ́rìí òun wà lọ́run, àwọn èèyàn lóríṣiríṣi ti ròyìn iṣẹ́ ribiribi tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ń ṣe, àwọn ará Àríwá ilẹ̀ yìí gan-an ti fi òǹtẹ̀ lù ú pé Tinubu ni àwọn yóò dìbò fún lọ́dún 2027.
Wọ́n wí pé:
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC Ariwa tí wọ́n pe ara wọn ní Northern Progressive Coalition ti sọ̀rọ sókè níbi ìpàdé tó wáyé pé kò sí ẹni méjì tí àwọn yóò dìbò fún lọ́dún 2027 ju ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lọ.
Àwíjare wọn náà ni pé ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ṣe bẹbẹ fún àwọn ní Ariwa ní gbogbo ẹ̀ka, ó tún àwọn ilé ìwé ṣe, ó ṣe àgbékalẹ̀ ètò ẹ̀yáwó-kàwé tí àwọn jẹ anfààní rẹ̀, ó pèsè iná, ó pèsè omi tó já geere, ó tún ṣe ètò ẹ̀kọ́ fún àwọn Almanjiri.
Ẹgbẹ́ NPC wí pé àwọn kò tíì gbádùn ìjọba kankan bíi ti Tinubu yìí rí, gbogbo nǹkan ni ó fi mú ayé rọrùn fún àwọn.
Usman Abdullahi, ẹni tí egbẹ́ NPC fi ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu ló ṣe àlàyé èyí, ó wí pé kò sí ẹni méjì tí àwọn yóò tún dìbò fún ju Tinubu lọ.
Yàtọ̀ sí àwọn ètò ẹ̀kọ́, oríṣìí àwọn iṣẹ́ àkànṣe bíi ọ̀nà tó yọ̀ kùlùlù, iná ọba tó ranjú kankan, oúnjẹ àjẹyó àjẹbì àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ni ààrẹ ti pèsè fún àwọn.
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti dá ìrètí àwọn tó ti sọnù láti ọjọ́ tó ti pẹ́ padà, àwọn ti ń gbé ayé ìrọrùn àti ìgbádùn, fún ìdí èyí, tewúré tàgùntàn Ariwa ni yóò fi ìdùnnú àti ayọ̀ dìbò fún Tinubu lọ́dún 2027.
Gbogbo èèyàn ló ń fọn rere ààrẹ Bola Ahmed Tinubu, tẹrú tọmọ ló ń gbáyé ìrọ̀rùn, oúnjẹ pọ̀ yanturu, ètò ààbò dúró digbí, ètò ẹ̀kọ́ ń lọ bó ṣe yẹ, eku ń ké bí eku, ẹyẹ ń ké bí ẹyẹ, ọmọ èèyàn gan-an ń fọhùn bí èèyàn.
Àbí ẹ̀yin ò ríi pé ìgbà yìí dùn?




