Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ bàbá ẹni àádọ́ta ọdún kan tó ki ọmọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́sàn-án mọ́lẹ̀ tó sì fa abogundé rẹ̀ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
Agbègbè Bulkachuwa ní ìjọba ìbílẹ̀ Katagum, ìpínlẹ̀ Bauchi ni èyí ti ṣẹ̀. Ọmọdébìnrin náà ń kiri ọjà ni bàbá náà tàn án wọlé tó sì fi ipá báa lájọṣepọ̀.
Bàbá ọmọ yìí ló lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá tó fi tó wọn létí, wọn ṣe ìwádìí lóòótọ́ wọ́n sì fi òfin gbé bàbá náà.
Bàbá àgbà yìí jẹ́wọ́ pé gbogbo ìgbà tí ọmọ náà bá ti kiri wàrà díndín kọjá níwájú ilé rẹ̀ ni ó máa ń mú un lọ sí ilé àkọ́kù kan tó wà ní tòsí tí yóò sì báa sù̀n dáadáa.
Bàbá yìí kò le sọ iye ìgbà tó ti bá ọmọ yìí sùn, ó ti ń ṣe é tipẹ́. Ọ̀bẹ ni ó fi dúnkokò mọ́ ọmọ náà pé kò gbọdọ̀ sọ.
Àyẹ̀wò nílé ìwòsàn fi hàn pé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń bá ọmọ náà lájọṣepọ tí gbogbo ojú ara rẹ̀ ló sì ti dégbò.
Muhammadu Audu kò jampata, ó ṣe àlàyé pé ọjọ́ ti pẹ́ ọ̀nà sì ti jìn tí òun ti ń jin ọmọ náà níjìnkujìn, inú ilé àkọ́kù ni ó máa ń mú un lọ láti ṣe níṣekúṣe.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi; Sani Omolori Aliyu bara jẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó pàṣẹ kí ìwádìí ó wáyé kí bàbá náà ó sì fi ojú ba ilé ẹjọ́ láìpẹ́.
Ìbálòpọ̀ ọmọdé ń gbilẹ̀ láàrín àwùjọ wa, lára àwọn èyí tó ti ṣẹ̀ sẹyìn ni ti bàbá kan ẹni àádọ́ta ọdún kan tó ki ọmọ ọdún mẹ́wàá mọ́lẹ̀ tó sì já ìbálé rẹ̀:
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ti tẹ bàbá kan ẹni àádọ́ta ọdún tó fi ipá gba ìbálé ọmọ ọdún méjìlá kan.
A gbọ́ pé ìyá ọmọ yìí ló fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Iléṣà nígbà tó rí ikun funfun nínú pátá ọmọ rẹ̀ náà.
Ọmọ náà jẹ́wọ́ pé bàbá náà tó jẹ́ alábàágbé wọn ló fipá bá òun lájọṣepọ̀. Àyẹ̀wò nílé ìwòsàn fi hàn pé ìjákújàá ni bàbá yìí já ìbálé ọmọ náà, gbagada ló fa abógundé rẹ̀ ya.
Ọmọ yìí ṣe àlàyé pé láti inú oṣù Agẹmọ, odun 2025 ni bàbá yìí ti ń bá òun lájọṣpọ̀ tí yóò sì fún un ní igba náírà kó fi ra oúnjẹ.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun; Ibrahim Gotan korò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó rọ àwọn òbí láti mójútó àwọn ọmọ wọn.
Kò tán síbẹ̀ o:
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí ìyá ọmọbìnrin ọmọ oṣù mẹ́jọ́ fi kan ọ̀gá ilé ìwé tí ó ti ń ṣiṣẹ́.
Gloria Umukoro ni orúkọ obìnrin yìí, ó jẹ́ olùkọ́ ó sì ń tọ́ ọmọbìnrin ọmọ oṣù mẹ́jọ lọ́wọ́. Ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù yìí, àwọn ọmọ ti jáde iléèwé àmọ́ Gloria dúró láti parí àwọn ìbéèrè ìdánwò. Ó fi ọmọ rẹ̀ ṣọ́ ọ̀gá ilé ìwé àmọ́ olùdásílẹ̀ ilé ìwé náà; Ọ̀gbẹ́ni Korede Afuye wá gbé ọmọ náà tó sì gbé e ọ, lẹ́yìn ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ni ó dá ọmọ náà padà fún ọ̀gá iléèwé.
Gloria ṣe àlàyé pé ojú òun ni Ọ̀gbẹ́ni Afuye ti dá ọmọ náà padà tí ọ̀gá sì tẹ́ ọmọ náà sílẹ̀ tó sì jáde. Ìyá ọmọ ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ lọ àmọ́ ó ríi pé ara ọmọ náà kò lélẹ̀ àmọ́ kò kọbi ara síi. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́wàá tí ó ríi pé ọmọ náà kò fi ara lélẹ̀ ni ó lọ yẹ̀ ẹ́ wò.
Ìlédí tí ó wà nídìí rẹ̀ kò jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ ó ṣàn síta àmọ́ ipa ẹjẹ tí ìyá rẹ̀ rí ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ó fi tú ìlédí ìdí rẹ̀, gbogbo abẹ́ ọmọ náà kún fún ẹ̀jẹ̀ láti ojú ara rẹ̀ pẹ̀lú ojú egbò, ó jọ pé wọ́n bá ọmọ náà lò pọ̀.
Àlàyé Gloria tẹ̀síwájú pé òun lọ ya bá olùdásílẹ̀ tó gbé ọmọ náà lọ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú pé kín ni ó fi ṣe ọmó? Èsì tí Afuye fọ̀ ni pé kí ó ṣe sùúrù kí àwọn ó yanjú rẹ̀ ní tùbí-ǹ-nùbí.
Gloria ní òun gbé ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn tí àwọn dọ́kítà sì fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n bá ọmọ náà lò pọ̀ ni, inú ìnira ni ọmọ náà wà báyìí. Lẹ́yìn tí ó gbé ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn ni ó lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá.
Afuye tún padà sọ fún Gloria pé ṣebí òun ní kó má lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá kí àwọn ṣe é ní òkú òru.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ti gba ìfisùn náà àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí rẹ̀.
Nígbà tí a kọ ìròyìn yìí, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló kàn sí wa pé a ti bu iyọ̀ já a pé kò irú rẹ̀ kò le ṣẹlẹ̀, a fi ẹ̀rí hàn wọ́n torí àwa kìí parọ́ lórí ìkànnì yìí.
Ó yani lẹ́nu lóòótọ́ pé kò sí ọmọ tí àwọn oníkínní-kò-mọ-busstop yìí ò le bá lò pọ̀.
Lára àwọn ìròyìn báyìí tó tún tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni ti Olajobi Taiwo ti oun náà ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ẹ̀sùn ìfipábánilò.
Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni Olajobi nígbà tí ọmọbìnrin náà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún.
Ìyá rẹ̀ fẹ́ nà án ló ṣe sá kúrò nílé, ọwọ́ Olajobi àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló kó sí, wọ́n tàn án wọlé wọ́n sì fi ipá báa ní àjọṣepọ̀. Agbègbè Oke ila ní Ado Ekiti ni èyí ti ṣẹ̀.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkìtì; Sunday Abutu wí pé ọwọ́ àwọn ti tó Olajobi o lórí ẹ̀sùn pé ó fi ipá bá ọmọdébìnrin náà lò. Wọ́n ní àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà ṣọwọ́ sí ẹ̀ka tó kàn gbọ̀ngbọ̀n.
Ta ni ká di ẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí rù? Ṣé ìyá tó lé ọmọ síta nítorí pé ó ṣẹ̀ ni àbí ọmọ tó sá kúrò nílé nítorí ẹgba?
