Ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Samuel Alozie ti ké gbàjarè síta lẹ́yìn tí ó pàdánú àwọn ọmọ rẹ̀ ìbejì ọkùnrin lẹ́yìn wàkátì mẹ́rìnlélógún tí wọ́n gba abẹ́rẹ́ àjẹsára.
Bàbá ìbejì fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn ìjọba alábọ́dé kan ní ìpínlẹ̀ Èkó pé òun kó àwọn ọmọ òun, ìbejì ọkùnrin àwọn ọmọ oṣù mẹ́sàn-án lọ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Ọ̀pẹ.
Ó ní àwọn ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní gbóná òun sì fún wọn ní parasitamọ́ọ̀ bí nọ́ọ́sì náà ṣe sọ. Ó fi omi tutu wẹ àwọn ọmọ náà àmọ́ ìgbóná náà kò dínkù bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọmọ náà kò ní okun nínú mọ́. Ọjọ́ kejì tíí ṣe ọjọ́ ọdún kérésì ni àwọn ọmọ náà kú sílé ìwòsàn.
Alozie ṣe àlàyé pé ilé ìwòsàn náà wí pé oúnjẹ tí òun fún wọn jẹ ló pa àwọn ọmọ náà. Ó ní òun kò gba èyí nítorí pé oúnjẹ náà kò pa wọ́n láti oṣù kan títí oṣù mẹ́sàn-án.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé àwọn ọmọ náà kò ṣe àìsàn láti ìgbà tí òun ti bí wọn, lọ́jọ́ tí wọ́n lọ gba abẹ́rẹ́ náà, koko lara wọn le, ìgbà tí wọ́n gba abẹ́rẹ́ náà tán ni wọn kò le jẹun, sọ̀rọ̀ tàbí ṣeré mọ́.
Àwọn ọmọ náà kò gba abẹ́rẹ́ níbòmíràn láti ìgbà tí ó ti bí wọn, lọ́jọ́ tí wọ́n gba àgbàkẹ́yìn náà, nọ́ọ̀sì titun ló fún wà lẹ́nu iṣẹ́ lọ́jọ́ náà kìí ṣe èyí tí wọ́n mọ̀ tẹ́lẹ̀.
Alozie ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn agbẹjọ́rò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn pé kí wọn ó dìde ìrànlọ́wọ́ fún òun láti rí ìdájọ́ òdodo lórí ikú àwọn ọmọ náà. Ó ní wọ́n ṣe àyẹ̀wò àwọn ọmọ náà nílé ìwòsàn ìjọba wọ́n sì ní kòkòrò inú oúnjẹ ló pa wọ́n, ó ní òun kò gba èyí gbọ́ nítorí ilé ìwòsàn ìjọba ni wọ́n ti ṣe àyẹ̀wò náà òṣìṣẹ́ ìjọba sì ni ó fún wọn ní abẹ́rẹ́.
Alozie ti sin òkú àwọn ọmọ náà àmọ́ ó ní ẹ̀mí wọn kò sinmi nítorí ikú àìtọ́jọ́ ni wọ́n kú.
Èsì ìjọba Èkó:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó; Babajide Sanwoolu ti pàṣẹ kí ìwádìí ìjìnlẹ̀ ó wáyé lórí ikú àwọn ọmọ ìbejì tí wọ́n kú lẹ́yìn wákàtí mẹ́rìnlélógún tí wọ́n gba abẹ́rẹ́ àjẹsára.
Gómìnà sọ èyí lẹ́yìn tí bàbá àwọn ọmọ náà fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn ìjọba alábọ́dé kan tó wà ní Èkó pé abẹ́rẹ́ àjẹsára wọn ló pa àwọn ọmọ rẹ̀ ìbejì ọkùnrin méjì.
Gómìnà bá Samuel Alozie; bàbá àwọn ọmọ náà kẹ́dùn, ó ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú àwọn ọmọ méjì náà. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé wọ́n ti fún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ní abẹ́rẹ́ àjẹsára tí wọ́n fún àwọn ìbejì náà ṣáájú wọn àti lẹ́yìn tí wọ́n fún wọn tí kò sì sí èyí tó gbòdì lára rẹ̀.
Èsì àyẹ̀wò òkú àwọn ọmọ náà yóò jáde síta lọ́gán tí àyẹ̀wò náà bá parí – ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó.
Ohun tó fi ara pẹ́ èyí náà ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kano níbi tí àwọn ẹbí Aishatu Umar ti fi èsùn kan ilé ìwòsàn Abubakar Umar pé wọ́n ṣekú pa Aishatu nípa gbígbàgbé àlùmọ́gàjí sínú rẹ̀ nígbà tó ṣe iṣẹ́ abẹ nílé ìwòsàn náà.
Èkúnrẹ́rẹ́ ìròyìn náà kà báyìí:
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano ti pàṣẹ kí ìwádìí ó wáyé lórí ikú tó pa ìyàwó ilé kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aishatu Umar lẹ́yìn tí wọ́ fi ẹ̀sùn ikú rẹ̀ kan ilé ìwòsàn Abubakar Umar Urology tó wà ní ìpínlẹ̀ náà.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano sọ èyí di mímọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Samira Suleiman, nínú rẹ̀ ni wọ́n ti kọ ó pé àwọn bá ẹbí Aishatu Umar kẹ́dùn, ìwádìí ìjìnlẹ̀ yóò wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ilé ìwòsàn Abubakar Umar yóò ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́.
Ọ̀rọ̀ náà tẹ̀síwájú pé àwọn kò ní fi igbá kan bọ̀kan nínú nínú ìwádìì náà. Ẹ̀mí àwọn èèyàn ṣe pàtàkì, àwọn yóò ríi dájú pé ilé ìwòsàn náà fi ojú winá òfin bí wọ́n bá fi le jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.
Èyí jẹyọ lẹ́yìn tí àwọn ẹbí Aishatu Umar fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn náà pé wọ́n dágúlá nígbà tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ abẹ fún obìnrin náà. Èyí mú kí inú bẹ̀rẹ̀ sí ní run ún tí ó sì ń padà lọ sí ilé ìwòsàn náà.
Òògùn inú rírun ni wọ́n ń fún un fún odidi oṣù mẹ́rin láìṣe àyẹ̀wò ohun tó ṣe okùnfà inú rírun náà. Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin ni wọ́n tó ṣe àyẹ̀wò fínní inú rẹ̀ tí wọ́n sì bá àlùmọ́gàjí nínú rẹ̀. èyí já sí pé wọ́n gbàgbé àlùmọ́gàjí sínú obìnrin náà nígbà tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ náà lóṣù mẹ́rìn sẹ́yìn. Wọ́n dájọ́ iṣẹ́ abẹ mìíràn tí wọn yóò fi yọ ọ́ àmọ́ Aishatu kú kó tó di ọjọ́ náà.
Àwọn ẹbí rẹ̀ fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn Abubakar Umar Urology pé wọ́n kò ṣe iṣẹ́ wọn bíi iṣẹ́ wọ́n sì fi àiàbìkítà wọn pa Aishatu. Ọmọ márùn-ún ni Aishatu fi sílẹ̀ sáyé lọ.

Kò tíì tó ọ̀sẹ̀ méjì tí gbajúgbajà òǹkọ̀wé Ngozi Chimamanda fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn Euracare pé wọ́n fi àìbìkítà wọn pa ọmọ rẹ̀. a mú ìròyìn náa wá báyìí:
Gbajúgbajà òǹkọ̀wé Chimamanda Ngozi Adichie ti fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn Euracare tó wá ní Èkó pé wọ́n fi àìbìkítà wọn gba ẹ̀mí ọmọ rẹ̀, ọmọ kékéré tó ń lọ pé ọdún méjì.
Ngozi ṣe àlàyé pé àwọn wá ṣe ọdún kérésì ní Èkó ni ọmọ náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nkanu bẹ̀rẹ̀ àìsàn, wọ́n kọ́ rò pé otútù ni àmọ́ àyẹ̀wò nílé ìwòsàn fi hàn pé àwọn kòkòrò àìfojúrí ló fà á, wọ́n ṣètò àti gbé e lọ sí orílẹ̀-ède United Kingdom fún ìtọ́jú, gbogbo ètò ti tò àmọ́ àwọn dọ́kítà lọ́hùn-ún bèèrè fún àwọn àyẹ̀wò kan kí ó tó lọ sí ọ̀hún.
Ó ku ọ̀la tó máa lọ sí UK ni wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn Euracare fún àwọn àyẹ̀wò ara náà. Àyẹ̀wò náà gba kí ọmọ náà ó wọ inú ẹ̀rọ wọn kò sì fẹ́ kí ó mira, wọ́n sọ fún ìyá rẹ̀ pé àwọn yóò pa iyè Nkanu ní ráńpẹ́ kí ó má baà mira nínú ẹ̀rọ náà, nígbà tó yá ni dọ́kítà gbé e ní pàjáwìrì lọ sí ẹ̀ka pàjáwìrì tí àwọn nọ́ọ̀sì sì ń sáré kiri, ìgbà náà ni Ngozi mọ̀ pé nǹkan ti yíwọ́.
Ngozi ní dọ́kítà tó kun ọmọ náà lóorun fún un ní àpọ̀jù òògun apaniníyè tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní propofol wọn kò tún yẹ ọmọ náà wò títí tó fi di pé èémí rẹ̀ lọ sílẹ̀.
Wọ́n de ẹ̀rọ ìmí mọ́ ọn nímú, wọ́n sì gbìyànjú àti jíi sáyé. Ọmọ náà jí sáyé padà ó sì nílò àti lọ sí yàrá pàjáwìrì. Ngozi ní dọ́kítà náà yọ ẹ̀rọ tí ọmọ náà fi ń mí ó sì gbé e lé èjìká láti yàrá iṣẹ́ abẹ lọ sí yàrá pàjáwìrì, nígbà tí yóò fi dé ibẹ̀, èémí rẹ̀ ti lọ sílẹ́ pátápátá, ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní sẹ́ gìrì ọkàn rẹ̀ sì da iṣẹ́ sílẹ̀. Bí ọmọ náà ṣe kú nìyẹn.
Ngozi Adichie fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn Euracare pé wọ́n fún ọmọ òun ní àpọ̀jù òògun propofol wọn kò sì tún yẹ ọmọ náà wò, nígbà tó tún jí sáyé, dọ́kítà náà tún yọ ẹ̀rọ èémí nímú rẹ̀ ó sì gbé e bẹ́ẹ̀ lọ sí yàrá pàjáwìrì. Ngozi ní ìwà ọ̀daràn gbáà ni dọ́kítà náà hù.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé àwọn èèyàn méjì ló ti fi ẹjọ́ sùn báyìí nípa dọ́kítà kan náà, wọ́n ní bí ó ṣe máa ń fún àwọn ọmọdé ní àpọ̀jù òògùn nìyẹn, kìí ṣe ti Nkanu làkọ́kọ́.
Ngozi bèèrè ìdí tí ilé ìwòsàn Euracare fi gbà á láàyè láti máa ṣiṣẹ́ lọ? Ó ṣe ìlèrí láti fa ẹjọ́ náà, ó ní òun yóò ríi dájú pé ọmọ mìíràn kò ṣe àgbákò dọ́kítà yìí.
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ilé ìwòsàn wa?




