ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ààyè Olóòtú

ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC ṢE ÌWỌ́DE ÌFẸ̀HÓNÚHÀN, WỌ́N NÍ ÀWỌN KÒ FẸ́ OJELABI ÀTI FALEKE NÍPÒ MỌ́.

Wàhálà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú.

by Adeola Olanrewaju
July 28, 2025
in Ààyè Olóòtú, Ìgbé-Ayé, Ìròyìn, Ìròyìn Agbègbè, Òṣèlú
0
ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC ṢE ÌWỌ́DE ÌFẸ̀HÓNÚHÀN, WỌ́N NÍ ÀWỌN KÒ FẸ́ OJELABI ÀTI FALEKE NÍPÒ MỌ́.
0
SHARES
5
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Èkó ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ní iwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin Èkó lónìí.
Ohun tí wọ́n ń bèèrè fún náà ni ìyọnípò alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Èkó; Pásítọ̀ Corlenius Ojelabi àti Amòfin James Faleke.
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n náà ni pé wọ́n ń fi ọwọ́ rọ́ àwọn sẹ́yìn nínú ìṣèjọba àwarawa, wọ́n ń yan àwọn adarí fún àwọn wọ́n sì ń kàn án nípá, wọn kò fún àwọn ní anfààní àti yan ẹni tó wu àwọn sípò.
Àwọn olùwọ́de yìí wí pé àwọn kò ní ẹ̀hónú nípa àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ àṣẹ̀ṣẹ̀yàn àmọ́ àwọn lẹ́tọ̀ọ́ àtiyan akọ̀wé àti alákòóso àmọ́ níṣe ni Ojelabi àti Faleke lẹ̀dí àpò pọ̀ tí wọ́n sì yan àwọn akọ̀wé àti alákòóso sípò láì bu àwọn gbọ́.
Oríṣìí akọ̀lé ni wọ́n gbé lọ́wọ́ tí wọ́n sì ń kọ orin ìfẹ̀hónúhàn.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà pọ̀ bìbà láti ríi pé kò mú rògbòdìyàn dání.
Igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó; Dọ́kítà Obafemi Hamzat wá sí ibi ìfẹ̀hónúhàn náà láti bá wọn sọ̀rọ̀ àmọ́ ó kúrò níbẹ̀ nígbà tí wọn kò fún un láàyè àti sọ̀rọ̀.
Otumba Adetunbosun; ọ̀kan nínú àwọn olùwọ́de náà láti Ikorodu bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀. Ó wí pé èyí tí Ojelabi ṣe nípò alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Èkó ti tó kó kúrò nípò náà. Ogunba fi ẹ̀sùn kan Ojelabi pé ó ń fi ọwọ́ la ilẹ̀ fún àwọn kò fún àwọn ní anfààní àtiyan ẹni tí àwọn fẹ́ sípò.
A kìí ṣe jàǹdùkú, ìjoba àwarawa ni a ń bèèrè fún bíi ti ìgbà Bayo Oshinowo – Adetunbosun ló sọ èyí.

Arábìnrin Babalola aya Balogun láti Àgbàdo Òkè – odò náà sọ̀rọ̀. Ó fi ẹ̀sùn kan àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC pé wọ́n ń kọyán àwọn aráàlú kéré wọn kò sì fi ààyè sílẹ̀ fún ìjọba àwarawa.
Gómìnà Babajide Sanwoolu ní wọn kò gbọdọ̀ yan akọ̀wé ìjọba àti alákòóso fún oṣù mẹ́fà gbáko nitori kí wọn ó le yàn fún àwọn.
Àwa la dìbò fún ààrẹ Tinubu àti Gómìnà Babajide Sanwoolu, kò yẹ kí wọn ó máa wá fi ọwọ́ lalẹ̀ fún wa – Aya Balogun.
Arábìnrin Balogun rọ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu láti yanjú ọ̀rọ̀ tó délẹ̀ yìí kí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ó má bàa wó lulẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó.
Asabi Adejuwon náà sọ̀rọ̀, ó wí pé àwa la ṣe ìpolongo ìbò fún wọn kí wọ́n tó wọlé sípò, wọ́n wọlé tán ni wọ́n dà wá nù bí omi ìṣanwọ́.
Àwọn èèyàn kò fẹ́ dìbò fún àwọn olùdíje wa nítorí pé kò sí oúnjẹ nílùú, kò sówó, wọn kò jẹ anfààní kankan lára ẹgbẹ́ òṣèlú APC, àwa la bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n fi dìbò fún yín, ẹ wá pa wá tì nísìn yìí. Ibí ni Asabi sọ̀rọ̀ dé tó fi bú sẹ́kún.

Alhaji Talibu Lawal náà ṣe àlàyé pé àsìkò ti tó fún Ojelabi àti Faleke àti Alhaja Akerele láti kúrò ní ipò. Ó fi ẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ti jẹ Ikeja run, bí wọ́n bá ṣì wá nípò, wọn yóò jẹ Èkó run.
Wọ́n ní àwọn yóò kọ ìwé sí Gómìnà Babajide Sanwoolu lórí ohun tí àwọn ń fẹ́ yìí.
Títí di àsìkò yìí, ilé iṣẹ́ Gómìnà kò tíì wí nǹkankan nípa ìwọ́de yìí .

ADVERTISEMENT
ADVERTISEMENT

Bákan náà la gbọ́ nípa bí ẹgbẹ́ òṣèlú SPD ṣe fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún Nasir El-Rufai tí wọ́n sì tún fi òfin ọgbọ̀n ọdún dè é.

Ẹgbẹ́ òṣèlú SDP ti yọ Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna tẹ́lẹ̀; Nasir El-Rufai nínú ẹgbẹ́ náà wọ́n sì fi òfin lé e pé kò le è padà sínú ẹgbẹ́ náà àfi lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún sí àsìkò yìí.
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án náà ni pé ó ń gba ẹ̀yìn ba ẹbọ jẹ́. Wọ́n ní El-Rufai pe ara rẹ̀ ní ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú SDP àmọ́ níṣe ló ń dá wàhálà abẹ́nú sílẹ̀ nínú ẹgbẹ́ náà tó sì ń jábọ̀ fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Akọ̀wé àgbà ẹgbẹ́ náà; Araba Aiyenigba ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé níbi ìpàdé àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ ni wọ́n ti fi ẹnu kò pé kí El-Rufai ó máa lọ tí wọ́n sì tún fi òfin ọgbọ̀n ọdún dè é.
Wọ́n ní títí di àsìkò yìí, El-Rufai kò tíì fi orúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ẹgbẹ́ ní ẹ̀kun rẹ̀ lẹ́yìn tó ti kéde pé òun ti dara pọ̀ tó sì tún bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà ya àwòrán.
‘A fi ọ̀wọ̀ pé àgbà olóṣèlú ni ó jẹ́ a sì fún un ní àsìkò láti fi orúkọ sílẹ̀ àmọ́ ó kọ̀ láti fi orúkọ sílẹ̀ ní èyí tó lòdì sí òfin ẹgbẹ́.
Yàtọ̀ sí èyí, níṣe ni El-Rufai ń bá àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ náà sọ̀rọ̀ pé kí wọn ó wá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC, gbogbo ohun tí ó ń ṣe yìí fi hàn pé ó fẹ́ tú ẹgbẹ́ náà ni’. Èyí ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Nasir El-Rufai.

Lẹ́nu lọ́lọ́ yìí, oríṣìí rogbodiyan ló ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ́ kọ́kọ́ ń dàrú ní èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà fi yapa lọ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú ADC.
Ẹgbẹ́ òṣèlú SDP tirẹ̀ kò ní ìdààmú títí di àsìkò tí Nasir El-Rufai darapọ̀ mọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n sọ.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó ń fi àwọn ẹgbẹ́ yòókù ṣe yẹ̀yẹ́ lásìkò tí wọ́n ń ní adojúkọ náà ni àwọn náà ti bẹ̀rẹ̀ ìjà abẹ́nú yìí.
Wọ́n tilẹ̀ ní kí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ó wá kọ́ ìṣèlú lọ́wọ́ wọn nígbà náà, àwọn yìí náà ni wọ́n tún wá ń fi ẹ̀sùn ìjẹgàba kan àwọn adarí wọn yìí.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnline#newsupdatesÌròyìnIwe Iroyin Yorubanews onlinenewsinyorubatrending
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ Logo

ÀWỌN OLÓGUN SẸKÚ PA Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ ÀMỌ̀TẸ́KÙN NÍ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀ṢUN.

Recommended

ILÉ ẸJỌ́ FAGI LÉ ẸJỌ́ ÌTẸNIPA TÓ WÁYÉ NÍ ÌBÀDÀN.

ILÉ ẸJỌ́ FAGI LÉ ẸJỌ́ ÌTẸNIPA TÓ WÁYÉ NÍ ÌBÀDÀN.

1 year ago
ỌKỌ̀ OJÚ OMI MÉJÌ TÓ KÓ Ọ̀PỌLỌPỌ̀ ÀWỌN ÈRÒ DÀNÙ NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA.

ỌKỌ̀ OJÚ OMI MÉJÌ TÓ KÓ Ọ̀PỌLỌPỌ̀ ÀWỌN ÈRÒ DÀNÙ NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA.

1 year ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.