Àwọn afurasí adigunjalè méje ni ọwọ́ ti tẹ̀ báyìí nígbà tí àwọn ọlọ́pàá ya bo ilé kan tí wọ́n sí pé ó jẹ́ buba wọn ní abule Ikot Osong ni ijọba ìbílẹ̀ Obot Akara.
Timfon John; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀.
Timfon ṣe àlàyé pé àwọn mú àwọn afurasí adigunjalè méje tí wọ́n ń da Ikot- Ekpene àti agbègbè láàmú.
Orúkọ àwọn afurasí náà ni David Effiong Silas, Etido Udo Lazarus, Etimbuk Thursday Udofia, Ime Effiong Silas, Joseph John Nelson, Nduese Solomon John àti Imo Effiong Udofia.
Àwọn tí ọwọ́ tẹ̀ yìí ni wọ́n júwe ibùdó olórí wọn ní ìpínlẹ̀ Imo.
Oríṣìí àwọn nǹkan ni wọ́n bá lọ́wọ́ wọn, lára rẹ̀ ni ìbọn, fìlà ọlọ́pàá, fìlà ológun, agbanápamọ́ méjì àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé ìwádìí ṣì ń lọ láti mú àwọn yòókù tó ti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ.
Ní ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom yìí kan náà ni ọwọ́ ti tẹ Cletus Bassey, ẹni tó jẹ́ oníṣègùn tó ń ró àwọn adigunjalè lágbára.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom ti tẹ Cletus Bassey lórí ẹ̀sùn pé ó ń ró àwọn adigunjalè lágbára ó sì tún ṣe ayẹta fún wọn.
Timfon John; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé lọ́jọ́ kọkándínlọ́gbọ̀n, oṣù Agẹmọ tó kọjá yìí ní nǹkan bíi aago méje alẹ́ ni àwọn ọlọ́pàá ya bo ilé Cletus tó wà ní abúlé Nung Oku ní ìjọba ìbílẹ̀ Uruan.
Ẹni ọgbọ̀n ọdún ni Cletus, ẹ̀sùn tí ìjọba fi kàn án náà ni pé ó ń ró àwọn adigunjalè lágbára ó sì tún ń ṣe ayẹta fún wọn.
Ìwádìí ṣì ń lọ lórí àwọn oníbàárà Cletus.
Ní ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom yìí kan náà ni a ti mú ìròyìn wá nípa Pius tí wọ́n bá odidi agbárí èèyàn lọ́wọ́ rẹ̀ pé:
Ọkùnrin kan tí wọ́n fura sí pé ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni wọ́n bá odidi agbárí èèyàn lọ́wọ́ rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom.
Pius Pius ni orúkọ ọkùnrin yìí, ẹni ogójì ọdún níí ṣe. Agbègbè Oku Abak ní ìjọba ìbílẹ̀ Abak ni ó ń gbé.
Afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn àti jàǹdùkú ni Pius lágbègbè náà.
Ìfimúfínlẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi lọ ká a mọ́lé ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà tí wọ́n sì tú gbogbo yẹ̀wù rẹ̀ tútú. Wọ́n bá odidi agbárí èèyàn kan, àwọn ẹ̀yà ara ẹ̀rọ amúnáwá tiransifọ́mà àti àwọn nǹkan mìíràn tó ti sọnù ládùúgbò.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom; Timfon John ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde.
Ó wí pé ní ogúnjọ́, oṣù Agẹmọ ni àwọn lọ ká Pius mọ́lé lórí ìró rẹ̀ tí àwọn ń gbọ́.
Pius kò jiyàn, ó jẹ́wọ́ pé ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Iceland ni òun. Oríṣìí itú ni ẹgbẹ́ òkùnkùn Iceland ti pa ní Abak àti agbègbè rẹ̀.
Timfon wí pé ìwádìí kò tíì parí lórí ọ̀rọ̀ Pius yìí, ní kété tí wọ́n bá parí ìwádìí ni yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́.
Akwa-Ibom náà la ṣì wà, ṣé ẹ rántí ọkúnrin kan tó ṣá ìyá rẹ̀ pa?
A mú ìròyìn náà wá pé:
Arákùnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Alexander Peter ti ṣá ìyá rẹ̀ ládàá pa ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.
Ẹni ọdún mọ́kànléláàdọ́rin ni ìyá Alexander, abúlé Ikot Inyang ní ìjọba ìbílẹ̀ Oruk Anam, ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ni ó ń gbé pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ Alexander.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù Okúdù tí a wà yìí ni Alexander ṣá ìyá rẹ̀ náà ládàá pa.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ṣì ń ṣe ìwádìí ohun tó mú kí Alexander ó ṣá ìyá rẹ̀ pa nítorí títí di àsìkò yìí, Alexander kò tíì rí àlàyé kankan ṣe.
Èyí tí a ó fi kásẹ̀ rẹ̀ ńlẹ̀ ní Akwa-Ibom náà ni ìròyìn pásítọ̀ Victor tó ṣá ìyàwó rẹ̀ pa sínú ilé:
Ọ̀gá ọlọ́pàá ti ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ní ọwọ́ ti tẹ Pásítọ̀ ìjọ Ìràpadà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Victor Okoh. Ọmọ ọdún méjìlélógójì ni Victor, ẹ̀sùn tó fi kan ìyàwó rẹ̀ náà ni pé ó ń ṣe àgbèrè.
Victor Okoh kò ká ọkùnrin pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, ó ní òun fura síi ni pé ó ń yan àlè mọ́ òun lára.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ pasitọ Victor Okoh, ó ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá níbi tí wọ́n ti n fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò láti mọ ohun tó rí lọ́bẹ̀, tó fi waro ọwọ́. Ikú victoria ti dá ọ̀fọ̀ nlá sílẹ̀ ní agbègbè rẹ̀ nítorí ṣe ni tọmọdé tàgbà n kárí bọnú, tí wọ́n dáró, tí wọ́n n kọ hàà! hàà! Irú kí lèyí?
Timfon John; ọlọ́pàá tí yóò ṣe ẹjọ́ náà wí pé ẹjọ́ ti dé ọ̀dọ̀ àwọn, ọwọ́ sì ti tẹ àfurasí ọ̀daràn náà, wọ́n sì ti gbé òkú Victoria lọ sí ilé ìgbókùúsí ti ilé ìwòsàn ìjọba ìpínlẹ̀ náà.
Ní kété tí pásítọ̀ Victor Okoh ti ṣiṣẹ́ láabi rẹ̀ tán ló bá lọ fara pamọ́ sábẹ́ òrùlé, ibẹ̀ ni ọwọ́ ti bà á. Àwọn ará àdúgbò ní kìí ṣèní kìí ṣàná ni gbọ́nmi-si-ò-tó ti n wáyé lààrín tọkọ tayà yìí, bí wọ́n ti máa n ṣe ní gbogbo ìgbà nìyí, kò jọwá lójú àmọ́ tọjọ́ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ nítorí ọ̀rọ̀ ọjọ́ yìí di fàá-kája débi pé pasitọ victor okoh ti pilẹ̀ ní kí ìyàwó máa lọ ilé àwọn òbí rẹ̀, ó ní òun kò ṣe mọ́.
Ṣàdéédé ló tún pè é wọlé padà, a ò mọ bí ọ̀rọ̀ ti padà bẹ́yìn yọ tó fi di pé pasitọ Victor fi ṣá Victoria pa sínú ilé. Ní àkókò yìí, pásítọ̀ Victor Okoh ti ilẹ̀kùn gbọingbọin pa látinú ní èyí tí kò fún àwọn olùlàjà kankan láàyè láti làwọ́n. Gbogbo bí ìyàwó ṣe ń kígbe , ‘ẹ gbà mí oooo, ó ti fẹ́ pamí oooo, yééè! A kò le è gbà á sílẹ̀ nítorí kò ṣeéṣe fún wa ni á bá pe aago àwọn ọlọ́pàá kí wọ́n tètè wá dá sí ọ̀rọ̀ náà kó tó bẹ́yìn yọ.
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá náà ti dé, wọ́n sì fi tipàtipá fa ilẹ̀kùn já ní wọ́n bá bá Victoria nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àti àdá tó n kán tó tó tó fún ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀.




