Àwọn ọlọ́pàá mẹ́ta kan tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ṣekú pa àwọn èèyàn méje ní Owódé onírin ti gba ìtúsílẹ̀ báyìí.
A gbọ́ pé ẹnìkan tó jẹ́ ajagungbalẹ̀ ló kó àwọn ọlọ́pàá náà wá láti ìpínlẹ̀ Nasarawa wá ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó. Lọ́jọ́ náà, wọ́n yìnbọn pa àwọn èèyàn méje ní ọjà Owódé onírin wọ́n sì tún dáná un ọkọ̀ bíi àádọ́ta.
Ẹni tó ṣe àlàyé náà wí pé lọ́gbọ̀njọ́, oṣu Ògún ni ẹni náà kó awọn ọlọ́pàá náà dé láti ipínlẹ̀ Nasaraa tí wọ́n sì ṣe awọn èèyàn báṣubàṣu.
Ó wí pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò jẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá náà ó jẹ́jọ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó tí wọ́n ti ṣẹ̀, Abuja ni wọ́n kó wọn lọ, ibẹ̀ ni ẹjọ́ wọ́n ti ṣe mọ̀dàrú ẹjọ́ náà tí wọ́n sì dá àwọn ọlọ́pàá náà sílẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá dá wọn sílẹ̀ lórí àre pé wọ́n gba ara wọn sílẹ̀ tí wọ́n ń pè ní self defence ni wọ́n fi pa àwọn ẹni náà.
Bákan náà ni ẹni náà wí pé ọ̀rẹ́ tímọ́ ni ajagungbalẹ̀ náà àti kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Nasarawa.
Femi Falana; ẹni tó jẹ́ agbẹjọ́rò ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn bu ẹnu àtẹ́ lu ìdásílẹ̀ awọn ọlọ́pàá yìí, ó wí pé bí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò bá sṣe ẹjọ́ náà, òun ṣetán àti ṣe ẹjọ́ náà.
Bí wọ́n bá ní ìgbara-ẹni-sílẹ̀ làwọn fi pa èèyàn méje, kí wọ́n wá sọ ọ́ níwájú adájọ́.
Àwọn ẹbí àwọn tó ṣe àgbákò náà fi ẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá pé wọ́n ṣe màgòmágó ẹjọ́ náà wọ́n sì tún lọ́ àwọn lọ́wọ́ gbà.
Wọ́n wí pé àwọn ọlọ́pàá sọ fún àwọn pé ẹgbẹ̀ta òkú ni àwọn ṣì fẹ́ ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ kí wọ́n tó le ṣe àyẹ̀wò òkú wọn àti pé wọ́n ní láti san owó àyẹ̀wò.
Nígbà tí òkú Akinboye Oluaseyi ṣì wà nílé ìgbókùúsí, àwọn ọlọ́pàá ti dá àwọn tó pa á sílẹ̀. Ọmọ mẹ́ta ni Akinboye fi sáyé lọ – Moruf Olayemi; mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ṣàlàyé.
Moruf wí pé kò sí òfin mọ́ ní ìlú yìí, ẹni bá ti lówó lọ́wọ́ le ṣe ohun tó wù ú.
Owolabi Ganiu; ẹni tó jẹ́ òṣìṣẹ́ Wale Adebayo náà fi ẹ̀sùn kan àwọn olọ́pàá pé wọ́n kàn ń gba owọ́ lọ́wọ́ àwọn ni, ó ké sí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu láti dá sí ọ̀rọ̀ yìí.
Ọmọ ọdún mẹ́ta ni Adebayo fi sáyé lọ tí ìyá ìyàwó rẹ̀ sì ní ààrùn rọpárọsẹ̀ nígbà tó gbọ́ ikú rẹ̀.
Abiodun Babalola; ẹni tí ọmọ rẹ̀ Abraham náà kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe àlàyé pé owó tí àwọn ọlọ́pàá ń bèèrè fún ayẹ̀wò òkú náà ti pọ̀ ju ohun tí òun le rí lọ, ó rọ̀ wọ́n láti gbé òkú Abraham fún òun bí wọn kò bá le ṣe àyẹ̀wò náà.
Bàbá Akeem Adeoye náà fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé ìwà ìkà ni kí wọ́n bèèrè ẹgbèlẹ́gbẹ̀ owó kí wọ́n tó le ṣe ẹjọ́ ìpànìyàn náà.
Bàbá ọjà Owóde onírin; Abiodun Ahmed rọ àwọn mọ̀lẹ́bí náà láti ṣe sùúrù pé ìjọba ni yóò san owó àyẹ̀wò àwọn òkú náà.
Abiodun wí pé lóòótọ́ ni àwọn olọ́pàá ti dá àwọn afurasí náà sílẹ̀ wọ́n sì tún wí pé ara ajagungbalẹ̀ náà kò dá ni àwọn ṣe dáa sílẹ̀.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Abimbola Adebisi ní òun ṣẹ̀ ń gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni, Benjamin Hundeyin tí ó jẹ́ agbẹnusọ àgbà náà kò fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́.
Wàyí o, kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Moshood Jimoh ti pàṣẹ kí wọn ó tún ẹjọ́ náà ṣí.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí a máa mú ìròyìn wá nípa àwọn tí ọlọ́pàá sẹkú pa.
Èyí tó tún kàmọ̀mọ̀ bí èyí ni ti Moses Mba, ó kà báyìí pé:
Àwọn ẹbí Moses Mba ti tọ ìjọba ìpínlẹ̀ CrossRiver lọ láti bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú tó pa ọmọ wọn.
Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà ìpínlẹ̀ CrossRiver; Bassey Otu pé àwọn ló lu Moses pa.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé Moses Mba; ẹni ọdún mọ́kànlélógún lọ sí ilé Gómìnà Bassey lọ́jọ́ kìíní, oṣù Ògún pé òun fẹ́ jíṣẹ́ Olúwa fún Gómìnà náà.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé náà lu Moses lálùbami en sì tún yìnbọn fún un.
Ilé ìwòsàn Naval Reference Hospital tó wà ní Calabar ni wọ́n gbé e lọ kí wọ́n tó pe àwọn òbí rẹ̀.
Ìyá Moses ṣe àlàyé síwájú síi pé ọmọ òun jẹ́ ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ Red Cross, àwọn ni wọ́n sì san owó ìtọ́jú rẹ̀ tó fi wá padà kú lọ́jọ́ kẹsàn-án.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà Bassey yí ilé ìwòsàn náà po títí tó fi kú wọ́n sì tún gbìyànjú àti gbé òkú rẹ̀ lẹ́yìn tó kú tán.
Ìyá Moses; Victoria wí pé láti ìgbà tí Moses ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́wàá ló ti máa ń ríran, iṣẹ́ Olúwa ló fẹ́ jẹ́ fún Gómìnà Bassey tí wọ́n fi pa á yii.
Àlàyé tí ilé iṣẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ CrossRiver ṣe tako èyí tí àwọn ẹbí Moses ṣe yìí. Kọ́míṣọ́nà fún ìfitónilétí; Erasmus Ekpang wí pé Moses ní ààrùn ọpọlọ, ó lọ sí ilé tí Gómìnà ń gbé tẹ́lẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ òkò lu àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé náà.
Ekpang wí pé Moses tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ náà nígbà tí ara rẹ̀ balẹ̀ tán ó sì kúrò níbẹ̀, ó bu ẹnu àtẹ́ lu lílù tí wọ́n lu Moses àti bí wọ́n ṣe yìnbọn fún un àmọ́ ó wí pé kìí ṣe àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà Bassey.
Kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ CrossRiver náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, ó wí pé àwọn ti darí ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń gbọ́ ẹjọ́ aráàlú, ohun tí wọ́n bá sọ níbẹ̀ ni àwọn yóò ṣe.
Kò tán síbẹ̀ o, Victoria wí pé ọmọ òun kò ní ààrùn ọpọlọ, ó yege nínú ìdánwò WAEC ó sì gba máàkì mẹ́rìndínnígba nínú ìdánwò JAMB.
Ẹ̀kọ́ nípa òwò ṣíse ni Moses fẹ́ kọ́ ní ilé ìwé gíga Calabar kó tó kú yìí. Bákan náà ló wí pé láti ìgbà tí ọmọ òun ti kú ni àwọn ẹ̀ṣọ́ náà pàápàá Emmanuel Dickson ti ń dùnkokò mọ́ ìdílé òun pé gbogbo wọn ni yóò lọ bá Moses lọ́run bí wọn kò bá pa ẹnu wọn mọ́.



