ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ààyè Olóòtú

ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ DÁÀBÒ BO AJỌ́MỌGBÉ, WỌ́N TÚN TI ÀWỌN ÒBÍ ỌMỌ NÁÀ MỌ́LÉ – AGBẸJỌ́RÒ MỌ̀LẸ́BÍ.

Irọ́ lásán ni wọ́n pa - ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Òndó.

by Adeola Olanrewaju
September 29, 2025
in Ààyè Olóòtú, Ìgbé-Ayé, Ìròyìn, Ìròyìn Agbègbè, Ọ̀rọ̀ Ààbò
0
ÌYÀWÓ NI OLAMIDE FẸ́ FỌ́ IRIN MỌ́ LÓRÍ TÓ FI BA ỌMỌ RẸ̀, ỌMỌ ỌDÚN KAN.
0
SHARES
18
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Agbẹjọ́rò ẹbí Onah; Tope Tomekun ti fi ẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo pé wọ́n fẹ́ pa iná ẹ̀sùn ajọ́mọgbé mọ́lẹ̀ wọ́n tún wá ti àwọn òbí ọmọ tí wọ́n jí gbé náà.
Àlàyé tó ṣe náà ni pé ikọ̀ ajọ́mọgbé kan jí ọmọbìnrin ọmọ ọdún márùn-ún kan gbé ní ìpínlẹ̀ Ondo wọ́n sì ta ọmọ náà sí ìpínlẹ̀ Delta.
Ọmọ yìí jẹ́ ọmọ bíbí inú arábìnrin Nneka Onah ó sì jẹ́ ọmọ àgbàtọ́ sí Ifeanyi Onah tó jẹ́ ọkọ ìyá rẹ̀.
Nínú ìtọpinpin ni wọ́n ti rí ọmọ náà gbà padà tí wọ́n sì mú àwọn afurasí kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Amaka Chukwuemeka.
Amaka jẹ́wọ́ pé òun ra ọmọ náà ní mílíọ̀nù mẹ́ta ó lé díẹ̀ náírà ó sì dárúkọ ọ̀gá wọn; Vivian Ngozi.
Ọ̀gbẹ́ni Tope Tomekun sọ wí pé láti ìgbà tí orúkọ Vivian ti jáde nínú ìwádìí ni àwọn ọlọ́pàá ti pa ìlù dà, wọ́n dá Amaka sílẹ̀ wọ́n sì ti ìyá àti ọkọ ìyá ọmọ náà mọ́lé. Lẹ́yìn náà ni wọ́n ṣe àyípadà orúkọ àwọn òbí ọmọ náà sí Sunday Kingsley àti Sunday Happiness nínú ìwé ìpẹjọ́.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo; Olayinka Ayanlade fi léde pé àwọn gba ọmọ náà sílẹ̀ àwọn sì ti fà á lé àwọn òbí rẹ̀ lọ́wọ́.
Agbẹjọ́rò ẹbí náà tako èyí, ó wí pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ń gbìyànjú láti da ẹjọ́ náà bolẹ̀ kí wọn ó sì yíi mọ́ àwọn òbí ọmọ náà lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n fẹ́ dáàbò bo Vivian tó jẹ́ olórí ikọ̀ náà.
Tomekun tẹ̀síwajú pé àwọn òbí ọmọ yìí wà ní àhámọ́ títí di àsìkò yìí tí wọ́n sì ń dúnkokò mọ́ wọn tí wọ́n tún ń mú wọn tọwọ́ bọ̀wé ní tipátipá.
Ó wí pé òun sọ èyí síta láti jẹ́ kí àwọn èèyàn ó mọ irú itú tí àwọn ọlọ́pàá ń pa lórí ọmọ tí wọ́n jí gbé náà.
Olayinka Ayanlade ti fèsì sí ẹ̀sùn yìí, ó ní irọ́ lásán ni agbẹjọ́rò náà ń pa, ó kàn fẹ́ pe àkíyèsí sí àwọn ẹbí náà lásán ni. Olayinka ní akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni àwọn ọlọ́pàá, bí àwọn bá ti èèyàn mọ́lé, nítorí ìwádìí ni.
Bákan náà ló wí pé àwọn kò pa ọ̀rọ̀ kankan mọ́lẹ̀, irọ́ ni wọ́n pa mọ́ àwọn.

ADVERTISEMENT

Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn èèyàn náà fi ẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá.
Oríṣìí irú ìròyìn báyìí ló ti jáde sẹ́yìn. Nínú ọdún yìí nìkan, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ti fi ẹ̀sùn kan ọlọ́pàá tàbí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá pé wọ́n fi ìyà jẹ àwọn lọ́nà àìtọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni oríṣìí fọ́nrán ló ti jáde níbi tí àwọn ọlọ́pàá ojú pópó ti ń kó ìyà fún awakọ̀, ó tilẹ̀ ní ọ̀kan tí ọlọ́pàá náà ti ń rọ̀jò ìgbátí fún bàbá kan.
Èyí tó tún fi ara pẹ́ èyí ni ti Moses Mba ní ìpínlẹ̀ CrossRiver tí àwọn ẹbí rẹ̀ fi ẹ̀sùn kan àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà Bassey pé àwọn ló sẹkú pa ọmọ náà.
A mú ìròyìn náà wá pé:
Àwọn ẹbí Moses Mba ti tọ ìjọba ìpínlẹ̀ CrossRiver lọ láti bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú tó pa ọmọ wọn.
Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà ìpínlẹ̀ CrossRiver; Bassey Out pé àwọn ló lu Moses pa.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé Moses Mba; ẹni ọdún mọ́kànlélógún lọ sí ilé Gómìnà Bassey lọ́jọ́ kìíní, oṣù Ògún pé òun fẹ́ jíṣẹ́ Olúwa fún Gómìnà náà.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé náà lu Moses lálùbami en sì tún yìnbọn fún un.
Ilé ìwòsàn Naval Reference Hospital tó wà ní Calabar ni wọ́n gbé e lọ kí wọ́n tó pe àwọn òbí rẹ̀.
Ìyá Moses ṣe àlàyé síwájú síi pé ọmọ òun jẹ́ ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ Red Cross, àwọn ni wọ́n sì san owó ìtọ́jú rẹ̀ tó fi wá padà kú lọ́jọ́ kẹsàn-án.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà Bassey yí ilé ìwòsàn náà po títí tó fi kú wọ́n sì tún gbìyànjú àti gbé òkú rẹ̀ lẹ́yìn tó kú tán.
Ìyá Moses; Victoria wí pé láti ìgbà tí Moses ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́wàá ló ti máa ń ríran, iṣẹ́ Olúwa ló fẹ́ jẹ́ fún Gómìnà Bassey tí wọ́n fi pa á yii.
Àlàyé tí ilé iṣẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ CrossRiver ṣe tako èyí tí àwọn ẹbí Moses ṣe yìí. Kọ́míṣọ́nà fún ìfitónilétí; Erasmus Ekpang wí pé Moses ní ààrùn ọpọlọ, ó lọ sí ilé tí Gómìnà ń gbé tẹ́lẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ òkò lu àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé náà.
Ekpang wí pé Moses tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ náà nígbà tí ara rẹ̀ balẹ̀ tán ó sì kúrò níbẹ̀, ó bu ẹnu àtẹ́ lu lílù tí wọ́n lu Moses àti bí wọ́n ṣe yìnbọn fún un àmọ́ ó wí pé kìí ṣe àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà Bassey.
Kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ CrossRiver náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, ó wí pé àwọn ti darí ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń gbọ́ ẹjọ́ aráàlú, ohun tí wọ́n bá sọ níbẹ̀ ni àwọn yóò ṣe.
Kò tán síbẹ̀ o, Victoria wí pé ọmọ òun kò ní ààrùn ọpọlọ, ó yege nínú ìdánwò WAEC ó sì gba máàkì mẹ́rìndínnígba nínú ìdánwò JAMB.
Ẹ̀kọ́ nípa òwò ṣíse ni Moses fẹ́ kọ́ ní ilé ìwé gíga Calabar kó tó kú yìí. Bákan náà ló wí pé láti ìgbà tí ọmọ òun ti kú ni àwọn ẹ̀ṣọ́ náà pàápàá Emmanuel Dickson ti ń dùnkokò mọ́ ìdílé òun pé gbogbo wọn ni yóò lọ bá Moses lọ́run bí wọn kò bá pa ẹnu wọn mọ́.

Ohun tó pa ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yìí pọ̀ ni ẹ̀sùn ìdúnkokò mọ́ ẹbí àwọn ṣe àgbákò yìí.
Ṣé lóòótọ́ ni pé àwọn ọlọ́pàá a máa dúnkokò mọ́ ẹni tó yẹ kí wọn ó gbè níjà?

ADVERTISEMENT
Facebook Comments Box

Related

Tags: detainedKidnappedondoOndo policeondo statepolicePoliceman
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ÀWỌN AJÍNIGBÉ BÈÈRÈ FÚN IGBA MÍLÍỌ̀NÙ NÁÍRÀ OWÓ ÌTÚSÍLẸ̀ BASHERAH.

ÀWỌN AJÍNIGBÉ BÈÈRÈ FÚN IGBA MÍLÍỌ̀NÙ NÁÍRÀ OWÓ ÌTÚSÍLẸ̀ BASHERAH.

Recommended

ỌMỌ AJIMOBI TI DÁGBÉRÉ FÁYÉ O!

ỌMỌ AJIMOBI TI DÁGBÉRÉ FÁYÉ O!

1 year ago
WỌ́N TI KÓ DONALD TRUMP NÍ PÁPÁMỌ́RA!

WỌ́N TI KÓ DONALD TRUMP NÍ PÁPÁMỌ́RA!

1 year ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.