Ìkọlù tó wáyé láàárín àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn àti àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ yìí mú ẹ̀mí Samuel Tope lọ.
Agbègbè Ijeda Ìjèṣà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀.
A gbọ́ pé àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn mú afurasí adigunjalè kan wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò ní ọjọ́ Ẹtì.
Nígbà tó di ọjọ́ Àbámẹ́ta, Fiyinfoluwa Opejobi; ọmọ ológun tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò lórí ìdigunjalè tó wáyé náà kó àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ méjì lọ ká Samuel mọ́ ibùdókọ̀ wọ́n sì lù ú lálùbami.
Èyí ló mú kí àwọn akẹgbẹ́ Samuel ó kóra jọ láti lọ kojú àwọn ọmọ ológun náà, wọ́n bá wọn nílé ìtura tí wọ́n ti ń gbafẹ́, ọ̀rọ̀ di bóòlọ-o-yàgò.
Wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀, ọta ba Samuel àti akẹgbẹ́ rẹ̀ kan, ọ̀nà ilé ìwòsan ni Samuel ti dákẹ́ nígbà tí èkejì rẹ̀ ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn.
Ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun; Ọ̀gbẹ́ni Adekunle Omoyele fi ẹ̀sùn kan Fiyinfoluwa Opejobi tó jẹ́ ọmọ ogun pé ó sẹkú pa Tope láìṣẹ̀.
Wọ́n ní Ojelabi sọ wí pé ìdí tí òun fi dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni láti le dá ṣèríà fún àwọn ẹ̀ṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn nítorí pé wàhálà wọn ti pọ̀ jù.
Irin ni Ojelabi kọ́kọ́ fọ́ mọ́ Tope lórí nígbà tí wọ́n ṣe ìkọlù sí i tí wọ́n sì fi sílẹ̀ sínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀.
Omoyele ní àwọn ti fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Ijeda àti ní ilé iṣẹ́ ológun.
ÀWỌN ỌDẸ ÌBÍLẸ̀ LU OKHANI LÁLÙBAMI.
Àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ ṣe ìkọlù sí Okhai Okhani, wọ́n lù ú bíi kíkù bíi yíyè.
Okhai Okhani ni ajìjàǹgbara ní ẹ̀kun Àríwá ìpínlẹ̀ Edo.
Ó ṣe àlàyé pé ọdọọdún ni òun máa ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn olóṣèlú ẹ̀kun náà láti jábọ̀ ohun tí wọ́n ti ṣe lórí ipò náà.
Níbi gbọ̀ngàn ayẹyẹ tí ìpàdé ọdún yìí ni àwon ọdè ìbílẹ̀ ti ṣigún dé, wọ́n ṣe àwọn èèyàn náà léṣe àmọ́ Okhani gan-an ni wọ́n wá wá.
Wọ́n lù ú bíi kó kú, wọ́n fọ́ ìdí ìbọn mọ́ ọn lórí, lẹ́yìn náà ni wọ́n wọ́ ọ sínú ọkọ̀.
Àgọ́ ọlọ́pàá ni wọ́n gbé e lọ, wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé kò gba ìwé àṣẹ fún gbọ̀ngàn tó lò fún ìpàdé náà.
Okhani wí pé òun gba ìwé àṣẹ fún ìpàdé náà àti fún gbọ̀ngàn náà, ó ní àwọn olóṣèlú tí ìpàdé náà kò ní so èso rere fún ni wọ́n bẹ àwọn ọdẹ náà lọ́wẹ̀.
Ó wá rọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá láti ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kí ìdájọ́ òdodo ó sì wáyé.
ỌWỌ́ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TẸ OBÌNRIN KAN TÓ JÍ ỌMỌ ÌKÓKÓ GBÉ NÍ BAUCHI.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi ti tẹ obìnrin kan tó jí ọmọ ìkókó gbé tó sì tún sẹkú pa àwọn ọmọdé méjì.
Esther Gambo ni orúkọ obìnrin yìí, ẹni ọdún mọ́kàndínlógún níí ṣe. Abúlé Lemoro tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Toro, Bauchi ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀.
Esther tan àwọn ọmọdébìnrin méjì kan tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún méje lọ láti lọ jí ọmọ ìkókó náà gbé wá, ní kété tí wọ́n gbé ọmọ náà fún un ni ó tàn wọ́n lọ sínú oko àgbàdo pé kí wọn ó wá lọ gba owó, nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Esther fi àdá ṣá àwọn ọmọ náà pa ó sì gbé ìkókó náà sá lọ.
Ahmed Wakil; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde.
ILÉ ÌWÉ GÍGA UNIPORT FI ÌWÉ Ẹ̀RÍ DÁ WIKE LỌ́LÁ.
Ilé ìwé gíga UNIPORT ti fi ìwé ẹ̀rí ìkẹ́kọ̀ọ́jáde dá mínísítà fún Olú ìlú wa; Nyesom Wike lọ́lá.
Ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ni wọ́n fi dá Wike lọ́lá.
Níbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́gboyè àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní èyí tí Wike jẹ́ àlejò pàtàkì ni wọ́n ti fi ìwé ẹ̀rí náà dá a lọ́lá.
A gbọ́ pé ilé ìwé náà ni Wike ti kẹ́kọ̀ọ́jáde tẹ́lẹ̀.
Ijó àti ayọ̀ ni Wike fi gba ìwé ẹ̀rí yìí, a rí fọ́nrán ijó tí Wike ti ń gbé bọ́dì tó sì ń yọ ayọ̀ ẹ̀yẹ náà.
ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ MÚ ONÍṢÒWÒ ỌMỌ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ANAMBRA.
Ikọ̀ ajọ́mọgbé kan ni ọwọ́ pálábá wọn ti sẹ́gi báyìí ní agbègbè Nnewi, ìpínlẹ̀ Anambra.
Àwọn ọmọdé mọ́kànlá ni wọ́n rí gbà kalẹ̀ nígbà tí ọwọ́ tẹ afurasí obìnrin kan.
Ikọ̀ yìí máa ń lọ láti ìpínlẹ̀ dé ìpínlẹ̀ láti jí àwọn ọmọdé gbé.
Àwọn tí wọ́n ń wojú Olódùmarè fún ọmọ tí wọ́n sì fẹ́ gba ọmọ tọ́ di tiwọn ni ikọ̀ yìí máa ń ta àwọn ọmọ náà fún. Mílíọ̀nù kan náírà ni wọ́n ń ta ọmọkùnrin nígbà tí wọ́n ń ta ọmọbìnrin ní ẹgbẹ̀rin náírà.
Tochukwu Ikenga; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀. Ó wá rọ àwọn tí wọ́n fẹ́ gba ọmọ tọ́ láti ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ kí wọ́n má kó sí ọwọ́ àwọn ilé ìwòsàn ayédèrú tí wọ́n ń jí ọmọ gbé.
ỌKỌ̀ TẸ OBÌNRIN KAN PA NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ.
Arabinrin kan ni ọkọ̀ àjàgbé ti tẹ̀ pa ní Ita Oluwo, ìpínlẹ̀ Èkó.
A gbọ́ pé ọkọ̀ àjàgbé kan pàdánù ìjánu rẹ̀ ó sì lọ rún obìnrin náà mọ́ ọkọ̀ àjàgbé mìíràn níbi tó dúró sí.
.
ỌMỌ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN ÌPÍNLẸ̀ EDO MÉJÌ TI JAPA LỌ SÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC.
Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Edo méjì ni wọ́n ti gbéra kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n ń sọ lọ́wọ́, ìyẹn ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Ṣèbí ibi tí ayé bá yí sí náà ni ó yẹ kí èèyàn ó bá wọn yí sí. Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló ta lẹ́nu lásìkò yìí, dandan ni kí a gbọ́ irú nǹkan báyìí.
Orúkọ àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin méjì náà ni; Eugene Inegbeboh tó ń ṣojú ẹ̀kun Igueben àti Andrew Uzamere tó ń ṣojú ẹ̀kun Ovia.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni wọ́n kí pé ó dìgbà tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC sì tẹ́wọ́ gbà wọ́n.




