Pásítọ̀ àgbà ìjọ Mountain of Liberation and Miracle Ministries; Chris Okafor ti gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ olúwa fún oṣù kan gbáko. Ó ṣe àlàyé pé olúwa ní kí òun ó dúró náà àti wí pé òun nílò láti sinmi pẹ̀lú ìyàwó àṣẹ̀ṣẹ̀gbé rẹ̀. ṣebí ẹ mọ̀ pé n kò tíì sinmi láti ìgbà tí mo ti ṣe ìgbéyàwó.
Ọjọ́ Àìkú ni pásítọ̀ Chris Okafor kúnlẹ̀ níwájú ìjọ rẹ̀ tó sì tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ Doris Ogala àti àwọn mìíràn tí ó ṣẹ̀, ó ní òun bẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ohun tí òun bá ti ṣe fún Doris àti àwọn mìíràn tó dùn wọ́n, ó ní àṣìṣe ìgbà àìmọ̀ ni ó sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní orúkọ Ọlọ́run.
Ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Ọ̀pẹ ni Pásítọ̀ Chris Okafor ṣe ìgbéyàwó lẹ́yìn tí Doris Ogala fi oríṣìí fọ́nrán léde tako ìgbéyàwó náà. Doris fi ẹ̀sùn kan Pásítọ̀ Chris pé ó yẹ ilérí ìgbéyàwó tó ṣe fún òun lẹ́yìn tí àwọn ti fẹ́ra fún ọ̀pọ̀ ọdún.
Àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ kó ọ̀rọ̀ Doris dànù, wọ́n ní ó tàbùkù ìránṣẹ́ Ọlọ́run náà láti gba owó lọ́wọ́ rẹ̀ ni. Ikọ̀ àwọn pásítọ̀ gbé ìgbìmọ̀ dìde láti ṣe ìwádìí ẹ̀sùn tí Doris àti àwọn obìnrin mìíràn fi kàn án.
Nígbà tí ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́, Pásítọ̀ Chris ní òun yóò gba ìsinmi oṣù kan gbáko gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe darí òun, ó di inú oṣù Èrèlé kí ó tó padà sí ẹnu iṣẹ́ olúwa.
Pásítọ̀ kan nínú ìjọ náà ṣe àlàyé pé ìpalẹ̀mọ́ ọdún ni kò jẹ́ kí ìwádìí náà ó parí, ó wí pé àjọ àwọn pásítọ̀ nìkan kò le yanjú ọ̀rọ̀ náà, àwọn ọlọ́pàá gbọdọ̀ dá síi nítorí pé ìwà ọ̀daràn ni ẹ̀sùn ìfipábánilò tí wọ́n fi kan pásítọ̀ náà, àwọn pásítọ̀ kìí mú ọ̀daràn, iṣẹ́ ọlọ́pàá ni wọ́n sì ní láti dá síi. Ó wí pé àwọn pásítọ̀ ló pàṣẹ fún Chris pé kí ó yẹra ná títí ìwádìí ó fi parí.
Ẹ̀sùn tí Doris fi kan Pásítọ̀ Chris.
Òṣèré ni arábìnrin Doris Ogala, ó fi èsùn kan Pásítọ̀ Chris Okafor pé odidi ọdún mẹ́sàn-án ló fi bá òun lájọṣepọ̀ pẹ̀lú ìlérí pé yóò fẹ́ òun níyàwó. Ọdún 2017 ni àwọn bẹ̀rẹ̀ eré ìfẹ́ títí tó fi wá fẹ́ obìnrin mìíràn ní ọdún 2025.
Doris ní nítorí Pásítọ̀ Chris ni òun ṣe kọ ọkọ òun nígbà tó ṣe ìlérí pé yóò fi òun ṣe aya. Ó tún wí pé Pásítọ̀ Chris fi fọ́nrán ìbálòpọ̀ òun síta fún ayé wò. Kò tán síbẹ̀ o, Doris fi ẹ̀sùn kan Pásítọ̀ Chris pé ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó lọ́wọ́ òun tó sì dá òun ní gbèsè.
Bákan náà ni Doris fi àwọn àwòrán léde pé Pásítọ̀ Chris fún òun ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá dọ́là kí òun ó pa ohùn dà sọ pé pásítọ̀ kan tó jẹ́ ọ̀tá rẹ̀ ló ní kí òun ó ba orúkọ rẹ̀ jẹ́.
Bílíọ́nù kan náírà ni Doris bèèrè lọ́wọ́ Pásítọ̀ Chris fún owó gbà-má-bínú fún gbogbo ìbálòpọ̀ ọdún mẹ́sàn-án àti bí àwọn ọlọ́pàá ṣe fi ìyà jẹ òun lórí ọ̀rọ̀ náà.
Lẹ́yìn tí Doris sọ̀rọ̀ jáde, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin mìíràn náà ló ti jáde sọ̀rọ̀ pé Pásítọ̀ Chris bá àwọn lájọṣepọ̀. Lára wọn ni ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀; Bessem Okafor.
Bessem ṣe àlàyé nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pé nítorí ìtìjú ni òun ṣe kọ Pásítọ̀ Chris látàrí pé gbogbo obìnrin ló máa ń bá ní àjọṣepọ̀.
Ebere; ẹni tó jẹ́ akọrin ìjọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ náà jáde sọ̀rọ̀, ó ní òun kúrò nínú ìjọ náà nígbà tí Pásítọ̀ Chris fẹ́ fi okó tú ìfun òun jáde. Ó ní ọdún 2015 ni òun bẹ̀rẹ̀ sí ní lájọṣepọ̀ pẹ̀lú reṛ̀ tí òun sì ṣẹ́ oyún mẹ́rin fún un, oyún karùn-ún ni òun kọ̀ láti ṣẹ́ tí òun sì fi bí ọmọ.
Obìnrin mìíràn náà jáde pé òun àti àbúrò òun ni Pásítọ̀ Chris ń kó ìbásùn fún, nígbà tí àwọn lóyún ni àwọn tó kọ̀, ó ní ọmọ tí àwọn bí jọ Chris bíi ìmumu, obìnrin yìí ní àwọn ṣetán láti ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ náà fún ẹ̀rí ohun tí àwọn sọ yìí.
Chidera Okafor; ọmọ Pásítọ̀ Chris náà fi fọ́nrán kan léde, ó ṣe àlàyé pé ọdún 2020 ni òun sá kúrò nílé nígba tí bàbá òun bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ọwọ́ pa òun lára. Pásítọ̀ Chris fèsì sí èyí pé irọ́ ni ọmọ náà ń pa.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ní àwọn kò le mú Pásítọ̀ Chris nítorí pé àwọn ẹni náà kò fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá.
Pásítọ̀ Chris kọ́ ni àkọ́kọ́ nínú irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí, ọ̀pọ̀ pásítọ̀ ni wọ́n ti fi irú ẹ̀sùn báyìí kàn sẹ́yìn.
Oṣù Bélú, ọdún tó kọjá ni a mú ìròyìn wá nípa pásítọ̀ Olawale tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ọmú obìnrin kan ṣeré.
Pásítọ̀ Aka-Bashorun Olawale; ẹni tó tún jẹ́ agbẹjọ́rò ti balẹ̀ síwájú adájọ́ Hakeem Oshodi ti ilé ẹjọ́ gíga Ikeja lórí ẹ̀sùn pé ó fi ọwọ́ tẹ ọmú ọmọdébìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan.
Ìròyìn fi yé wa pé Pásítọ̀ Olawale jẹ́ pásítọ́ ní ìjọ ìràpadà, ẹ̀sùn oníkókó kan tí ìjọba fi kàn án náà ni pé ó fi ọwọ́ tẹ ọmú ọmọdébìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan ní agbègbè Iwaya, ìpínlẹ̀ Èkó.
Agbẹjọ́rò ìjọba; Funmilola Aluko wí pé ohun tí pásítọ̀ Olawale ṣe yìí tako òfin ipínlẹ̀ Èkó àmọ́ agbẹjọ́rò Olawale wí pé Olawale ko jẹ̀bi ẹ̀sùn náà. Morenikeji Oyekunle rọ ilé ẹjọ́ láti gba onídùúró Olawale nítorí pé kò le sá lọ àti wí pé pásítọ̀ ni.
Agbẹjọ́rò fún ìjọba; Funmilola Aluko tako ẹ̀bẹ̀ Morenikeji ó sì rọ ilé ẹjọ́ láti wo ọ̀rọ̀ náà dáadáa.
Adajo Hakeem Oshodi gba onídùúró Olawale pẹ̀lú àṣẹ pé ó gbọ́dọ̀ yọjú ní gbogbo ìgbẹ́jọ́ tió yóò wáyé.
Àlàyé tí ọmọdébìnrin ìgbà náà; ẹni tó ti pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nísìn yìí ṣe ni pé lọ́dún 2010 nígbà tí òun wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ ni bàbá òun mú òun lọ gbé ní ilé pásítọ̀ Olawale kí òun le tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ kí òun sì le máa kópa nínú ẹgbẹ́ akọrin ìjọ. Ó wí pé bí òun ṣe dé ibẹ̀́ ni Olawale ti ń ṣe òun mọ́kumọ̀ku, yóò fi ọwọ́ tẹ gbogbo ọmú rẹ̀ yóò sì tún lù ú lálùbami bí ó bá fìdí rẹ́mi nílé ìwé.
Ó ní òun padà sá kúrò nílé Olawale lọ́dún náà lọ́hùn-ún tí òun sì ṣe àlàyé fún ìyá òun.
Lọ́dún 2023 tí òun gbọ́ pé Olawale ṣe irú èyí fún ọmọdébìnrin mìíràn ni òun pe ẹjọ́ náà. Ó wí pé ẹlẹ́rìí òun ni olùkọ́ òun nígbà náà; Arábìnrin Akingbeoyewa nítorí pé òun sọ fún un nígbà náà.
Adájọ́ Oshodi pàṣẹ kí Olawale ó san ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà fún ọmọbìnrin náà ṣáájú ìgbẹ́jọ́ tó ń bọ̀. Ó sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Ọ̀pẹ.



