Àwọn ọba aládé ilẹ̀ Yorùbá ti ṣetán àti pe àwọn alálẹ̀ àti òòṣà ilẹ̀ Yorùbá láti kojú ètò ààbò tó mẹ́hẹ.
Àwọn ládéládé bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ pé àwọn ti ṣetán báyìí láti pe àwọn alálẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá láti kojú àwọn agbésùnmọ̀mí, ajínigbé àti àwọn adàlúrú gbogbo.
Èyí ni èsì tí àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá fọ̀ sí ọ̀rọ̀ tí Ọ̀ọ̀ni Adeyeye Enitan Ogunwusi sọ pé kí àwọn ọba ó parapọ̀ fi àlálẹ̀ ìlú wọn gbógun ti àwọn ajínigbé.
Níbi àpérò tó wáyé ni Ọ̀ọ̀ni ti rọ àwọn lọ́balọ́ba láti gbé ìgbésẹ̀ yìí. – Àwọn ọba aládé ṣetán.

Wọ́n ti gbé ọmọ pásítọ̀ lọ ní Òǹdó.
Àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí Igbosi ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, wọ́n dáná sun ilé, wọ́n rọ̀jò ìbọn wọ́n sì gbé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án kan lọ.
Aago kan òru ni wọ́n ya wọ ìlú náà, ìbọn ń dún lákọlákọ, wọ́n dáná sun ilé méjì wọ́n sì gbé Oluwatobi ọmọ Pásítọ̀ Isaac Olaosebikan lọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀, wọ́n ní àwọn ti gba ìfisùn náà àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí bí wọn yóò ṣe mú àwọn ọ̀daràn náà tí wọn yóò sì gba ọmọ náà sílẹ̀.

Mo máa dárúkọ àwọn olóṣèlú tó lọ́wọ́ sí ìjìnigbé Oriire – Sunday Igboho.
Olóyè Sunday Igboho ti kìlọ̀ fún ìjọba láti gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí àwọn agbésùnmọ̀mí kó ní ìjọba ìbílẹ̀ oríire sílẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo àwọn olóṣèlú tó lọ́wọ́ nínú rẹ̀ ni àwọn yóò dárúkọ.
Ìdí ni pé mo fa ara mi kalẹ̀ láti lọ kojú àwọn agbésùnmọ̀mí náà kí n sì kó àwọn ọmọ náà wálé àmọ́ ìjọba pàṣẹ pé n kò gbọdọ̀ lọ. bẹ́ẹ̀ sì ni mi ò bèèrè owó tàbí ohun kan lọ́wọ́ ìjọba.
Lẹ́yìn ìgbà náà ni ìjọba Ọ̀yọ́ sọ fún mi pé àwọn agbésùnmọ̀mí náà ní kí wọn ó kìlọ̀ fún mi pé bí mo bá wá àwọn yóò pa àwọn ọmọ náà.
Bákan náà ni ìjọba àpapọ̀ ti fún mi láṣẹ láti lo ẹ̀ṣọ́ ààbò mi tí mo pè ní Iru ẹkùn àmọ́ ìjọba Ọ̀yọ́ takú pé àwọn kò fẹ́ kí n dá sí ọ̀rọ̀ náà.
Ohun tí mo ń ṣe yìí, fún àwọn aráàlú ni, wọn kò le jí mi gbé bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn mọ̀lẹ́bí mi kò sí ní ìlú yìí débi tí wọn ó jí wọn gbé, bí ìjọba Ọ̀yọ́ bá wá wí pé àwọn kò fẹ́ kí n gba àwọn ọmọ náà sílẹ̀, ó kù sí ọwọ́ wọn.

Ọkùnrin mẹ́jọ fi ipá ọmọbìnrin kan lò ní Anambra.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ti mú àwọn ọkùnrin mẹ́jọ kan tí wọ́n fi tìpátìkúùkù bá ọmọbìnrin kan ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún lò pọ̀.
A gbọ́ pé alágbàtọ́ ọmọ náà ló lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méje tí wọ́n sì jọ ń bá ọmọ náà lájọṣepọ̀. Ìbálòpọ̀ tìpátìkúùkù náà ti wáyé lọ́pọ̀ ìgbà tí ọmọ náà sì fẹ́rakù.
Kọmíṣọ́nà fún ọ̀rọ̀ obìnrin ìpínlẹ̀ Anambra; Esther Onyekesi barajẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó mú ọmọ náà ló fún àyẹ̀wò nílé ìwòsàn, àbájáde àyẹ̀wò fi hàn pé ojú ara ọmọbìnrin náà ti rí okó ńláńlá lọ́pọ̀ ìgbà ó sì ti lóyún oṣù méjì.
Ọ̀rọ̀ ọmọ náà ká Esther lára nítorí ẹni tó mú un sọ́dọ̀ láti wò bíi bàbá ló ṣe èyí fún un, àánú rẹ̀ ṣe Esther lọ́pọ̀lọpọ̀.
Ọmọ náà ṣe àlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí lọ́wọ́ alágbàtọ́ rẹ̀ yìí, ó ní alaalẹ́ ni ó máa ń bá òun lájọṣepọ̀, nígbà tó yá, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní wá bá òun lájọṣepọ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi pé mẹ́jọ lórí òun nìkan. Bíkan bá ṣe ń sọ̀ ni èkejì ó máa gun orí rẹ̀.
Ó wí pé ìyàwó alágbàtọ́ náà ní ààrùn rọpárọsẹ̀, èyí ló fà á tí kò fi le gba òun sílẹ̀ lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. ìgbà tí wọ́n tún fẹ́ ṣe bíi ìṣe wọn ni ẹnìkan wọlé wá tó sì gba òun kalẹ̀, ẹni náà ló mú un ló sí ọ́fíìsì kọmíṣọ́nà fún ọ̀rọ̀ obìnrin.
Wàyí o, yàtọ̀ sí àwọn mẹ́jọ tí wọ́n mú yìí, ọmọ náà tún ka àwọn mẹ́fà mìíràn tí wọ́n máa ń wá báa lájọṣepọ̀, àwọn ọlọ́pàá ti ń wá àwọn mẹ́fà náà báyìí.

Ọmọ lu bàbá rẹ̀ pa ní Òǹdó.
Ọmọkùnrin ọmọ ọdún méjidínlógójì kan ti lu bàbá rẹ̀ pa ní ìpínlẹ̀ Òǹdó. Nsikak Kingsley ni orúkọ ọmọ yìí, bàbá rẹ̀ a máa jẹ́ Adone Peter, agbègbè Oda ní Akure tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Òǹdó ni Nsikak lu bàbá rẹ̀ pa sí.
Àlàyé tí a rí gbà láti ẹni agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà; Abayomi Jimoh ni pé ọ̀rọ̀ ló ṣe bí ọ̀rọ̀ láàrin Nsikak àti bàba rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà di aáwọ̀ láàrín wọn tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi lu bàbá rẹ̀ lálùpa.
Ẹni ọdún márùndínláàdọ́rin ni Adone lásìkò ikú rẹ̀. lọ́jọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní lùú nígbà tí aáwọ̀ náà wáyé, ó lùú títí tó fi orí ṣeṣe, nígbà tí ẹ̀jẹ̀ ń dà ní orí rẹ̀ ni àwọn ará ilé ṣe aájò rẹ̀ lọ sílé ìwòsàn àṣọ kò bá ọmọyẹ mọ́, Adone dákẹ́ sí ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀ náà.
Ẹ̀gbọ́n Nsikak ló fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí tí wọ́n sì gbé e lọ sí àhámọ́.
Baba fún ọmọ lóyún ó tún bá a ṣẹ́ ẹ ní Kwara.
ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti tẹ bàbá ẹni ogójì ọdún kan tó bá ọmọ rẹ̀ obìnrin sùn títí tó fi lóyún tó sì tún ṣẹ́ oyún náà fún ọmọ náà.
Ọmọbìnrin yìí kò ju ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lọ, agbègbè Alapa ní ìjọba ìbílẹ̀ Asa, ìpínlẹ̀ Kwara ni ó ń gbé pẹ̀lú bàbá rẹ̀.
Àwọn ará ilé rẹ̀ ni wọ́n kàn sí àwọn ọlọ́pàá nígbà tí wọn kò ṣàdédé rí ọmọ náà nílé mọ́, ṣáájú èyí ni bàbá fúnra rẹ̀ ti lọ sọ ní àgọ́ Àmọ̀tẹ́kùn pé òun kò rí ọmọ òun mọ́ pé kò padà sílé láti bíi ọ̀sẹ̀ mẹ́ta.
Àwọn ọlọ́pàá ṣe àwárí ọmọ náà ó sì ṣe àlàyé pé òun sá kúrò nílé nítorí bàbá òun ń fi ipá bá òun lò ó tún ṣẹ́yún fún òun ó sì halẹ̀ mọ́ òun pé ikú ni bí òun bá sọ fún ẹnikẹ́ni.
Ó wí pé a máa lu oun lálùbami bí òun bá kọ ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. ọ̀dọ ìyá rẹ̀ àgbà ló gbé dàgbà títí di oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2025, kété tó dé ọ̀dọ bàbá rẹ̀ náà ni ó ti ń fi ẹpọ̀n ṣe é lálejò títí tó fi sá lọ.
Àyẹ̀wò nílé ìwòsàn fi hàn pé ọmọ náà ṣẹ́ oyún nínú oṣù Èbìbí ìyẹn oṣù tó kọjá yìí. Síbẹ̀ bàbá rẹ̀ kò fi í lọ́rùn sílẹ̀, ó ra àwọn òògùn ìdènà oyún fún un kí ó máa lò.
Bàbá ọmọ yìí kò tilẹ̀ lọ́ àwọn ọlọ́pàá nífun púpọ̀ jù, ó jẹ́wọ́ pé òun a máa bá ọmọ náà sùn lóòótọ́.
Ẹ̀ka tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ọmọdé korò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, wọ́n ṣe ìlérí pé ìdájọ́ òdodo yóò wáyé.
