Abubakar Malami; ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ mínísítà fún ètò ìdájọ́ ilẹ̀ yìí tó tún wá jẹ́ adarí ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress ní ìpínlẹ̀ Kebbi ni àwọn jàǹdùkú ti ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ akọ́wọ̀ọ́rìn rẹ̀ nígbà tí ó ń kọjá lọ.
A gbọ́ pé Malami lọ ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ẹbí àwọn tí ọ̀fọ̀ ìkọlù àwọn agbésùnmọ̀mí ṣẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kebbi ni àwọn jàǹdùkú náà dá ọkọ̀ rẹ̀ lọ́nà tí wọ́n sì ṣe ìkọlù síi.
Ọkọ̀ bíi mẹ́wàá ni wọ́n bàjẹ́ tí àwọn èrò inú rẹ̀ sì farapa.
Malami wí pé òun fura pé àwọn olóṣèlú ló bẹ àwọn jàǹdùkú náà lọ́wẹ̀, ó ní òun lọ kí àwọn èèyàn náà ní ti ẹlẹ́ran ara ni òun kò bá ti òṣèlú lọ rárá.
Ó wí pé nínú ilé ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí àwọn gba iwájú rẹ̀ kọjá ni àwọn jàǹdùkú náà ti jáde pẹ̀lú ìbọn àti àwọn ohun ìjà olóró lọ́wọ́ tí wọ́n ṣe ìkọlù náà.
Malami gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú òun kò ní fà sẹ́yìn nítorí àwọn alátakò náà.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC fèsì sí ẹ̀sùn tí Malami fi kàn wọ́n yìí. Akọ̀wé ẹgbẹ́ náà; Isa Assalafy bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà, ó wí pé ìlú tó tùbà tùṣẹ ni ìpínlẹ̀ Kebbi.
Isa wí pé kò sí ìjọba tó ń gbádùn àtìlẹ́yìn àwọn ará ìpínlẹ̀ kan tó sì dáa lójú pé wọn yóò dìbò fún un lọ́dún 2027 tí yóò wá ṣe ohun tí ó le da àlàáfíà ìpínlẹ̀ náà rú.
Bákan náà ló wí pé àwọn ọlọ́pàá Malami ṣíná ìbọn mọ́ àwọn jàǹdùkú náà ló jẹ́ kí ìkọlù náà ó le.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kebbi kò ṣe bí ẹni tó gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà títí di àsìkò yìí.
WỌ́N DÁNÁ SUN AFURASÍ ADÁNILỌ́NÀ KAN NÍ ÌPÍNLẸ̀ BENUE.
Àwọn èrò ti dáná sun afurasí kan tí wọ́n ní ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń já ọ̀kadà gbà lójú pópó.
Àlàyé náà lọ báyìí pé ikọ̀ náà jẹ́ ẹlẹ́ni mẹ́ta, àwọn méjì dá ọ̀kadà dúró pé kó gbé àwọn dé ojú irin ní Makurdi nígbà tí ẹnikẹ̀ta lọ dúró dè wọ́n ní ibẹ̀.
Nígbà tí ọ̀kadà náà gbé wọn dé ibẹ̀, ẹnìkẹta wọn náà jáde sí wọn bí ìgbà tí ó fẹ́ san owó ọ̀kadà náà, òjijì ni ó yọ amuga sí ọlọ́kadà náà tó sì gún un níkùn, wọ́n wọ́ ọlọ́kadà náà bọ́ sílẹ̀ wọ́n sì sáré jókòó lé orí ọ̀kadà náà láti wà á lọ.
Orí tako ẹni tó jókòó sí ẹ̀yìn pátápátá, ó jábọ́ lórí ọ̀kàdà, àwọn èèyàn ṣùrù bò ó, wọn kò bèèrè ẹjọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n fi tú epo bẹntiróòlù lée lórí tí wọ́n sì dáná sun ún.
Andrew Tergu; ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣe àlàyé pé àwọn ẹni náà ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ni, wọ́n tan ọlọ́kadà náà wá sí ibẹ̀ kí wọn ó le gba ọ̀kadà rẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá ló wá palẹ̀ àjókù ẹni náà mọ́.
Udeme Edet; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Benue ṣe àlàyé pé afurasí náà jẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ni lórí ẹ̀sùn olè jíjà.
Edet bu ẹnu àtẹ́ lu ìdájọ́ ọwọ́ tí àwọn èèyàn náà ṣe fún afurasí náà, ó wí pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò ní fi ààyè gba irú ìwà bẹ́ẹ̀.
ÀWỌN ẸBÍ MOSES BÈÈRÈ FÚN ÌDÁJỌ́ ÒDODO LÓRÍ IKÚ TÓ PA MOSES MBA.
Àwọn ẹbí Moses Mba ti tọ ìjọba ìpínlẹ̀ CrossRiver lọ láti bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú tó pa ọmọ wọn.
Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà ìpínlẹ̀ CrossRiver; Bassey Otu pé àwọn ló lu Moses pa.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé Moses Mba; ẹni ọdún mọ́kànlélógún lọ sí ilé Gómìnà Bassey lọ́jọ́ kìíní, oṣù Ògún pé òun fẹ́ jíṣẹ́ Olúwa fún Gómìnà náà.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé náà lu Moses lálùbami en sì tún yìnbọn fún un.
Ilé ìwòsàn Naval Reference Hospital tó wà ní Calabar ni wọ́n gbé e lọ kí wọ́n tó pe àwọn òbí rẹ̀.
Ìyá Moses ṣe àlàyé síwájú síi pé ọmọ òun jẹ́ ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ Red Cross, àwọn ni wọ́n sì san owó ìtọ́jú rẹ̀ tó fi wá padà kú lọ́jọ́ kẹsàn-án.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà Bassey yí ilé ìwòsàn náà po títí tó fi kú wọ́n sì tún gbìyànjú àti gbé òkú rẹ̀ lẹ́yìn tó kú tán.
Ìyá Moses; Victoria wí pé láti ìgbà tí Moses ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́wàá ló ti máa ń ríran, iṣẹ́ Olúwa ló fẹ́ jẹ́ fún Gómìnà Bassey tí wọ́n fi pa á yii.
Àlàyé tí ilé iṣẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ CrossRiver ṣe tako èyí tí àwọn ẹbí Moses ṣe yìí. Kọ́míṣọ́nà fún ìfitónilétí; Erasmus Ekpang wí pé Moses ní ààrùn ọpọlọ, ó lọ sí ilé tí Gómìnà ń gbé tẹ́lẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ òkò lu àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé náà.
Ekpang wí pé Moses tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ náà nígbà tí ara rẹ̀ balẹ̀ tán ó sì kúrò níbẹ̀, ó bu ẹnu àtẹ́ lu lílù tí wọ́n lu Moses àti bí wọ́n ṣe yìnbọn fún un àmọ́ ó wí pé kìí ṣe àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà Bassey.
Kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ CrossRiver náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, ó wí pé àwọn ti darí ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń gbọ́ ẹjọ́ aráàlú, ohun tí wọ́n bá sọ níbẹ̀ ni àwọn yóò ṣe.
Kò tán síbẹ̀ o, Victoria wí pé ọmọ òun kò ní ààrùn ọpọlọ, ó yege nínú ìdánwò WAEC ó sì gba máàkì mẹ́rìndínnígba nínú ìdánwò JAMB.
Ẹ̀kọ́ nípa òwò ṣíse ni Moses fẹ́ kọ́ ní ilé ìwé gíga Calabar kó tó kú yìí. Bákan náà ló wí pé láti ìgbà tí ọmọ òun ti kú ni àwọn ẹ̀ṣọ́ náà pàápàá Emmanuel Dickson ti ń dùnkokò mọ́ ìdílé òun pé gbogbo wọn ni yóò lọ bá Moses lọ́run bí wọn kò bá pa ẹnu wọn mọ́.



