Àwọn afurasí méjì kan tí wọ́n máa ń fi ọkọ̀ ṣe ‘one-chance’ ní Abuja lọ́wọ́ tẹ̀. Àwọn èrò pé pitimu lé wọn lórí, wọ́n dáná sun àwọn àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn.
Agbègbè Lugbe ní Abuja ni ọwọ́ ti tó wọn, Ẹnìkan tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ fún àwọn akọ̀ròyìn . Ahmed ṣe àlàyé pé wọ́n ti ẹnìkan bọ́ sílẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, àwọn èèyàn rí wọn pé ehn ehn, ẹ tún ti gbé ìṣe yín dé. Wọ́n lé ọkọ̀ náà mú nítòsí ilé ìjọsìn Dunamis.
Àwọn mẹ́ta ló wà nínú ọkọ̀ náà, ọ̀kan nínú wọn rọ́nà sá lọ tèfètèfè nígbà tí wọ́n lu ọ̀kan pa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, èkejì padà dákẹ́ sílé ìwòsàn lẹ́yìn ìyà àjẹbólórí.
Àwọn èrò náà lù wọ́n lálùbami, lẹ́yìn náà ni wọ́n dáná sun ọkọ̀ wọn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá sọ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Josephine Adeh pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Nígbà tí èyí ṣẹlẹ̀ ní Abuja, ẹ̀ẹ̀mọ̀ mìíràn tún sẹ́yọ ní ìpínlẹ̀ Ogun níbi tí arábìnrin Joy Idem ti ń fi àwọn ọmọdébìnrin ṣe òwò nàbì.
Ọwọ́ àwọn ẹṣọ́ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn ti Ifọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn tẹ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kan tó n fi àwọn ọmọdébìnrin tí ọjọ́ orí wọn kò ju méjìlá lọ ṣòwò nàbì, ìyẹn gbélépawó.
Iye àwọn tó n gun orí àwọn ọmọdébìnrin yìí lójoojúmọ́ tó mẹ́wàá, ẹgbẹ̀rún kan náírà sì ni owó iṣẹ́ tí wọ́n san fún wọn. Ọ̀gá ni wọ́n n ṣiṣẹ́ sìn lójoojúmọ́.
Ọjọ́rú, ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ọwọ́ pálábá wọn ségi nígbà ti àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn náà dáná ogun yá wọn ní bùbá wọn, èèyàn mẹ́ẹ̀dógún sì ni ọwọ́ bà pẹ̀lú ọ̀gá burúkú yìí tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ Joy Idem.
Agbègbè ojú irin reluwé tó wà ní Báńkì Ifọ̀, ìpínlẹ̀ Ògùn ni ọwọ́ ti tẹ̀ wọ́n. Àwọn ọmọdébìnrin náà jẹ́wọ́ pé tìpá-tìkúùkù ni iṣẹ́ òwò nàbì náà ní ṣíṣe fún àwọn láti fi sin ọ̀gá bí bẹ́ẹ̀kọ́, ikú ni yóò jásí. A gbọ́ pé ọ̀gá ti ni kí wọ́n mulẹ̀ pé àwọn kò ní tú àṣírí náà síta fún ẹnikẹ́ni. Ọjọ́ tí wọ́n bá sọ fún èèyàn ni wọn yóò jáde láyé.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan bí owó tó tó ẹdẹ̀ẹ́gbẹ̀rin náírà, òògùn olóró, rọ́bà ìdáàbòbò, ohun afákọlágbára ìbálòpọ̀ bí I jápátá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò bá ní bùbá àwọn ẹni ibi yìí.
Ọ̀gá àgbà àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn ; Ọ̀gágun Alade Adedigba ní ọmọdébìnrin mọ́kànlá ló wá láti ìpínlẹ̀ Akwa Ibom tí àwọn tókù sì wá láti ìpínlẹ̀ Cross Rivers àti Delta. Àsìkò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ni àṣírí tú pé ìbẹ̀rubojo ni àwọn ọmọdébìnrin náà fi mulẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni irú iṣẹ́ láabi tí wọ́n n ṣe. Ọ̀gá tún fá irun orí àti abẹ́ wọn fún ìmùlẹ̀ náà, èyí kìí ṣe ojú lásán ooo, Joy Idem fẹ́ kí àwọn ọmọ náà le è máa ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti máa siṣẹ́ sìn ín ni.
Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà tí a fi orúkọ bo láṣìírí ni oṣù kọkànlá ọdún tó kọjá lòun darapọ̀ mọ́ wọn, òun mulẹ̀ àṣírí, ọ̀gá Joy ní òun yóò ṣiṣẹ́ ọdún kan ṣángílítí. Ọmọdébìnrin náà ni ọkùnrin mẹ́wàá sí méjìlá ni oníbàárà òun lójoojúmọ́ pẹ̀lú owó iṣẹ́ ẹgbẹ̀rún kan lọ́wọ́ ẹnikọ̀ọ̀kan wọn tí òun yóò sì kó fún ọ̀gá Joy Idem pátápátá.
Èèmọ̀ dé ooo! Ẹ̀yin òbí àti ará, Ẹ ò ráyé lóde bí? Gbogbo wa lá ni iṣẹ́ ṣe oooo. Ẹ jẹ́ a mójútó àwọn ògo wẹẹrẹ wa, Àṣá àjọ́mọgbé kò ní ṣe deede àwọn ọmọ wa o.
***** **** ***** ****** ***** **** **** ****
Irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò fẹ́rẹ̀ jẹ́ ìròyìn mọ́ ní orílẹ̀-èdè wa, onírúurú àwọn afọmọṣòwò àti agbénipa báyìí ni wọ́n wà káàkiri àwùjọ wa.
A mú ìròyìn wá fún yín nígbà kan nípa ilé ìtura tí ìjọba dà wó ní Anambra.
Ilé ìtura ni àwọn èèyàn ń wò lórí ilẹ̀ náà, àmọ́ abattoir èèyàn ni ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.
Udoka Golden point hotel tí wọ́n tún dà pè sí La Cruise hotel ni àsìrí rẹ̀ lu síta.
Ó lé ní ọgbọ̀n sàrê tó wà ní ìsàlẹ̀ ilé náà, ọ̀pọlọpọ̀ àwọn ohun ìjà olóró, oògùn dúdú, igbá ẹbọ àti àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ló farasin sí abẹ́ ilé ìtura yìí.
Omi gbígbóná kò gbọdọ̀ pẹ́ lẹ́nu, ọwọ́ kò gbọdọ̀ pẹ́ nísà akekě, ìjọba ti da ilé náà wó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ojú ọ̀nà márosẹ̀ Onitsha sí Owerri ní ìpínlẹ̀ Anambra ni ilé ìtura yìí wà, àwọn ajinigbe àti agbénipa ló tẹ̀dó sí ibẹ̀ àmọ́ tí wọ́n fi ilé ìtura ni wọ́n fi bo ojú ilé náà.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra ló fúnra rẹ̀ kéde ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lójú òpó X rẹ̀ pé àwọn da ilé ìtura là cruise wó nítorí àwọn èèyàn ni wọ́n ń pa tà ní ibẹ̀.