Timileyin Ajayi fojú ba ilé-ẹjọ́ giga Lafia lónìí, àwọn ẹlẹrìí mẹ́ta ni awon agbẹjọ́rò olùpẹjọ́ kó wá láti tako òun nìkan.
Ohun tí àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta náà wí ni pé ilé Àjàyí ni wọ́n ti bá òkú Salome. Ajayi ti kọ́kọ́ fojú ba ilé-ẹjọ́ ní oṣù Ṣẹẹrẹ àmọ́ ó wí pé òun kò jẹ̀bi ni wọ́n fi sún ìgbẹ́jọ́ náà síwájú.
Nílé ẹjọ́ lónìí ni àwọn olùpẹjọ́ ti béèrè fún pé kí ilé ẹjọ́ ó yí orúkọ rẹ̀ padà kúrò ní Timileyin Ajayi sí Oluwatimileyin Daniels Ajayi.
Lẹ́yìn gbogbo atótónu Adájọ́ Simon Aboki sún ìgbẹ́jọ́ di ogúnjọ́ oṣù yìí.
Agbẹjọ́rò Ajayi wí pé ìrètí ṣì ń bẹ nítorí pé ẹjọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni.
Bí ẹ bá ń fọkàn bá wa lọ, a mú ìròyìn wá fún yín nígbà náà pé ọwọ́ tẹ afurasí olórin ẹ̀mí tó sẹkú pa Salome, a kọ ọ́ báyìí pé ‘Akọrin ẹ̀mí ni Timilehin Ajayi, orí àfẹ́sọ́na rẹ̀; Salome Enejo ni wọ́n bá lọ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì bá àwọn ẹ̀ya ara yòókù tó ti gé lékìrìlékìrì sínú àpò nílé rẹ̀.
Ọjọ́ Àìkú ni ọjọ́ yìí, Timilehin gbé orí Salome sínú àpò, ìsìń ṣì ń lọ lọ́wọ́, olùjọ́sìn kan ló fura sí Timilehin pé ìrìn rẹ̀ mú ìfura dání bó ṣe ń lọ sí etídò kan tí kò jìnnà sílé ìjọsìn.
Ẹni yìí pe àwọn èèyàn mọ́ra, wọ́n sì tọ ipasẹ̀ rẹ̀, bí Timilehin ṣe rí wọn ló sọ àpò náà sódò. Wọ́n mú un pé kó yọ àpò náà kó sì tú u, ó feré gée àmọ́ wọ́n lé e mú, títú tí yóò tú àpo yìí, orí àfẹ́sọ́nà rẹ̀; Salome ni wọ́n bá nínú rẹ̀.
Ìdájọ́ ọwọ́ ni wọ́n fẹ́ ṣe fún un àmọ́ àwọn ọlọ́pàá gbà á kalẹ̀, lẹ́yìn náà ni wọ́n lọ tú ilé rẹ̀ tí wọ́n sì bá àwọn ẹ̀yà ara Salome nínú àpò méji.
Àwọn ẹbí Salome ṣe ìdámọ̀ ọmọ wọn, ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún ni Salome, àgùnbánirọ̀ sì ni pẹ̀lú.
Olùkọ́ni Bibeli ilé ìjọsìn náà; Caleb Umaru ṣe àlàyé fún àwọn ọlọ́pàá pé ọmọ ìjọ kan ló fura sí Timilehin nígbà tí ara rẹ̀ kò balẹ̀, ó ṣọ́ ọ títí tó fi dé etídò náà kí wọn ó tó wá mú un’
Lẹ́yìn ìgbà náà ni àwọn akọ̀ròyìn bá Timileyin Ajayi sọ̀rọ̀ pé báwo ni ó ṣe rí lára rẹ̀? Ẹ ka ohun tó wí ‘Timileyin Ajayi; akọrin ẹ̀mí tí ọwọ́ tẹ̀ nígbà tó pa Salome wí pé òun kò kábàámọ̀ pé òun pa ọmọbìnrin náà rárá, òun pa á òun pa á náà ni kò sí bàbàrà kankan níbẹ̀, Timilehin ní kí ẹ yé pọ́n jẹ̀bẹ̀ lákìísà.
Àwọn akọ̀ròyìn bá Timileyin sọ̀rọ̀ pé báwo ni ó ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí wọ́n mú un fún ìpànìyàn àti pé báwo ni ó ṣe rí lára rẹ̀ pé ó pààyàn?
Timilehin kó àlàyé ṣe, ó kó ẹjọ́ rò pé kò sí nǹkan bàbàrà nínú pé òun pa Salome o, ó ti lé lọ́dún kan tí òun ti ń fẹ́ Salome, Timilehin ní òun fura síi pé ó ń fẹ́ àwọn ọkùnrin mìíràn ni òun ṣe pa á.
Ohun tí tí àwọn ẹbí Salome wí ni pé Timilehin jí Salome gbé ni pé àwọn kò ríi mọ́ ọmọ àwọn rí. Wọ́n ní ó pa á nípakúpa fún ìdí tí ó yé òun nìkan. Àbúrò bàbá Salome wí pé ìgé tó gé ẹran ọmọ náà lékìrìlékìrì fi hàn pé ó fẹ́ sè é jẹ tàbí tà á fún àwọn tí yóò jẹ ẹ́ ni. Wọ́n ní ìdájọ́ òdodo ni awon ń retí láti ọ̀dọ ìjọba.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé Timilehin yóò fojú ba ilé-ẹjọ́ láìpẹ́, bó bá sì fi le jẹ̀bi, yóò jìyà lábẹ́ òfin’
Ní báyìí, ó dàbí pé àwọn ọlọ́pàá ti fẹ́ mú ìlérí wọn ṣe nípa gbígbé Àjàyí lọ sí ilé ẹjọ́.
Nígbà tí ti olórin èmí wà lápá kan, ǹjẹ́ ẹ gbọ́ ti Alfa tó kun ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ bí ẹran iléyá?
AbdulRahman ni orúkọ afurasí alápatà yìí, ìlú Ilorin ló tẹ̀dó sí, inú ilé rẹ̀ náà ló sọ di odò ẹran tó ti ń pa á kun ún. Èyí tó bu ú lọ́wọ́ yìí ni ti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tó pa, Hafsoh lọ kí AbdulRahman nílé ni kò dé mọ́. Ìtọpipin àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi mú AbdulRahman, ó ti pa ọmọ náà ó sì ti gé e níkèéníkèé sínú ike ọ̀dà ọlọ́mọrí.
Ó ti fojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́ẹ̀kan níbi tó ti sọ pé òun kò jẹ̀bi, adájọ́ sì sún ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ síwájú.
Ǹjẹ́ kí ọjọ ìgbẹ́jọ́ tó pé ńkọ́? Ọjọ́ Àìkú ọ̀sẹ̀ yìí ni àwọn ẹ̀ṣọ́ àláàbò ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi sí wí pé àwọn ọlọ́pàá ti wá gbé e kúrò lọ́dọ̀ àwọn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti fèsì pé àwọn kò wá gbé e o, lọ́rọ̀ kan, AbdulRahman ti dàwátì lọ́gbà ẹ̀wọn, láì ṣe abẹ́rẹ́!
Nígbà tí àwọn èèyàn kò tíì rán ti AbdulRahman tán ni wòlíì kan tú ṣekú pa akẹ́kọ̀ọ́jáde ilé ìwé gíga Èkó.
Ọmọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n ni Adedamola Ogunbode ṣaájú kí wòlíì náà tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò. Nígbà tí Adedamola dàwátì ni ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tẹnu mọ́ ọn pé ilé ìjọsìn náà ló dágbére.
Wòlóì yìí wí pé òun kò rí Adedamola, ó tilẹ̀ wí pé òun kò sí nílé lọ́jọ́ náà. Àṣẹ̀yìnwá àṣèyìnbọ̀, wọ́n ríi pé owó kúrò ní àpò owó Adedamola bọ́ sí àpò wòlíì yìí lọ́jọ́ náà gan-an, ìgbà náà ló tún wí pé owó tó fẹ́ kí òun ó fi ṣe iṣẹ́ fún òun ni àmọ́ ó ti lọ, àwọn ará àdúgbò bá wọn dá síi, wọ́n wì pé inú ọgbà ilé ìjọsìn náà ló sin ọmọ náà sí, àwọn ọlọ́pàá kọ́kọ́ kó ọ̀rọ̀ náà dànù àmọ́ nígbà tó dójú ẹ̀, wọ́n lọ ṣe àyẹ̀wò ọgbà náà wọ́n sì hú òkú Adedamola jáde.
Àti wòlíì àti Alfa ló ti ń ṣiṣẹ́ alápatà èèyàn ní ìlú yìí, ẹ jẹ́ ká máa ṣọ́ra, a kò ní kó sọ́wọ́ o.