Àwọn tí wọ́n ń gbá ilẹ̀ ojú títì lábẹ́ ẹ̀ka LAWMA ìpínlẹ̀ Èkó ti fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn lórí ohun tí wọ́n ń kojú lọ́dọ̀ àwọn awakọ̀ àti àwọn aráàlú lápapọ̀. Wọ́n ní iṣẹ́ ribiribi ni àwọn ń ṣe fún ìlú àmọ́ níṣe ni wọ́n ń ṣe wọ́n bíi ẹ̀gbin.
Àwọn awakọ̀ á wò wọ́n tìka tẹ̀gbin, àwọn tó ń kọjá lọ náà á ṣe wọ́n bíi ohun èérí ohun ẹ̀gbin, wọ́n ní ohun tí ojú àwọn ń rí kọjá bẹ́ẹ̀.
Kafilat; ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ LAWMA yìí ṣe àlàyé pé àwọn awakọ̀ yóò páàkì ọkọ̀ wọn sí ojú pópó ní èyí tí ó ń di iṣẹ́ tiwọn lọ́wọ́, bí wọ́n bá wá ní kí wọn ó gbé ọkọ̀ wọn, wọ́n á fèsì pé kò sí ibi tí àwọn le páàkì sí kí wọn ó lọ gbá ibòmíràn.
Olatitoye náà ṣe àlàyé pé àwọn èèyàn yóò gbé ilẹ̀ wá láti ilé wọn wá sọ ojú títì tí àwọn ti gbá, bí àwọn bá sọ̀rọ̀ wọ́n ṣetán láti lu àwọn. Wọn yóò ní ọkọ̀ akólẹ̀ kò wá kó ilẹ̀ náà ní ilé ni àwọn ṣe gbé ilẹ̀ náà wá sí ìta.
Taiwo Ologunro náà ṣe àlàyé pé bí àwọn ṣe àlàyé pé bí àwọn ṣe ń gbá ilẹ̀ ni àwọn ọlọ́jà ṣe ń dọ̀tí rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bí wọ́n bá gbá ibìkan tán, tí ọ̀gá wá tẹ̀lé àwọn wá wo iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, gbogbo rẹ̀ ni yóò ti dọ̀tí padà bí ọ̀gá ó bá fi dé.
Taiwo ní àwọn ọ̀làjú èkó ni wọ́n ń dọ̀tí èkó, wọn yóò sọ ilẹ̀ lu àwọn láti inú ọkọ̀ wọn, wọn yóò tún wí pé ṣé ẹ kò gba owó iṣẹ́ yín ni?
Bákan náà ló sọ̀rọ̀ nípa ìgbẹ́ yíyà síta gbangba. Ó ní ojoojúmọ́ ni àwọn ń fi ojú àti imú kó ìgbẹ́ tí àwọn èèyàn ń yà sí ẹ̀gbẹ́ títì, ó ní òun lérò pé ìjọba yóò wá nǹkan ṣe síi.
Victoria Bamgbose náà sọ tirẹ̀, ó ní àwọn ọmọ ìta náà ń ṣe tiwọn, wọn yóò ríi pé àwọn ń gbálẹ̀ wọn kò ní sọ ìdọ̀tí nù, ibi tí àwọn ti gbá yẹn gan-an ni wọn yóò sọ ọ̀rá ọtí tí wọ́n bá mu sí. Wọn yóò tún fọ́ ìgò sílẹ̀ ó sì di dandan kí àwọn ó tún ilẹ̀ náà gbá nítorí pé ọ̀gá máa wá ṣe àyẹ̀wò iṣẹ́ tí wọ́n bá ṣe.
Fatimo Akinduro náà sọ sí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní àwọn ló ń kó àwọn ohun ẹ̀bọ ojú títì, oríṣìí ẹbọ ni àwọn máa ń kó kúrò ní títì bí àwọn bá ń ṣiṣẹ́. Àti wí pé àwọn a máa rí òkú ọmọ titun nínú ilẹ̀ tí wọ́n yí lọ́ràá, bí àwọn bá rí irú èyí, ọ̀gá ni àwọn máa ń ké sí.
Kehinde Ajibade ní owó oṣù àwọn dáa àmọ́ àwọn kò ní àǹfààní sí ètò ìlera. Bí àwọn bá lọ sí ilé ìwòsàn, níṣe ni wọ́n ń dẹ́yẹ sí àwọn.
Kalejaiye Adenike náà sọ wí pé àwọn èèyàn ó gbé ike ilẹ̀ wọn wá láti ilé wọn wá dà sí ojú títì, bí òun bá sọ̀rọ̀, wọ́n á ní ṣebí òun ń gba owó iṣẹ́.
Èyí tó burú jù ni pé bí àwọn bá ní ìjàm̀bá, àwọn awakọ̀ kìí dúró gbé àwọn tàbí ṣe ìrànwọ́ kankan fún wọn, ọ̀pọ̀ wọn ló ti kú látàrí pé kò sí ìrànlọ́wọ́ nígbà tó ní ìjàm̀bá.
Adarí ẹ̀ka LAWMA; Muyiwa Gbadegeshin fèsì sí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní òun mọ rírì iṣẹ́ wọn òun sì ní ìmọ̀lára àdojúkọ wọn. Ó ṣe àlàyé pé Gómìnà Sanwoolu ti bu ọwọ́ lu ètò ẹ̀dínwó ètò ìlera fún gbogbo wọn pátá, bí wọ́n bá ti lọ sí ilé ìwòsàn báyìí, wọn yóò rí ìtọ́jú láì san owó gọbọi.
Gbadegeshin tako bí àwọn èèyàn ṣe ń da ilẹ̀ sí ojú títì, ó ní ó lòdì sí òfin àwọn sì ń mú àwọn tó bá rú òfin yìí. Àwọn ti mú ọ̀pọ̀ lọ́dún tó kọjá tí àwọn kan sì wá lẹ́wọ̀n báyìí lórí pé wọ́n da ilẹ̀ sí ojú títì.
Bákan náà ló wí pé àwọn ti fi ẹ̀wọ akáwòránsíle¬̣ há gbogbo ojú pópó láti ṣọ́ awakọ̀ tó bá fi ẹ̀mí agbálẹ̀ wé ewu. Ìdí ni pé àwọn ti pàdánù ọ̀pọ̀ agbálẹ̀ nípasẹ̀ èyí wọn kò sì fẹ́ irú rẹ̀ mọ́.
Kò sí irọ́ nínú pé àwọn awakọ̀ ń fi ẹ̀mí àwọn agbálẹ̀ náà wéwu, ọ̀pọ̀ ìròyìn ni a ti mú wá rí nípa bí ọkọ̀ ṣe ń gbá wọn lẹ́nu iṣẹ́. Ọ̀kan ṣẹlẹ̀ ní kòpẹ́kòpẹ́ yìí ní Ìyànà ẹkọ̀rọ̀:
Ọkọ̀ akérù aládàáni kan ti tẹ obìnrin kan tó ń gbá ilẹ̀ ojú títì pa ní ìyànà Ẹkọ̀rọ̀ ní Meiran, ìpínlẹ̀ Èkó.
A gbọ́ pé obìnrin náà ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ni ọkọ̀ Ford náà fi ẹ̀yìn rìn tó sì kọlù ú, kò tún dúró lẹ́yìn tó kọlu obìnrin yìí, ó fi ẹ̀yìn gun orí àti apá rẹ̀ mọ́lẹ̀ ó sì ní sá lọ bẹ́ẹ̀.
Àwọn èèyàn ló gbé ọ̀kadà tẹ̀lé e tí wọ́n sì mú un, wọ́n tilẹ̀ fẹ́ pa á ni àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ló gbà á kalẹ̀ tí wọ́n sì mú un lọ sí àgọ́ wọn.
Adebayo Taofiq; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún àjọ LASTMA ṣe àlàyé pé àwọn ta mọ́ra dé ibẹ̀ nígbà tí àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà.
Wọ́n pe àwọn ọlọ́pàá àgọ́ Meiran mọ́ra, wọ́n fa awakọ̀ náà lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ wọ́n sì gbé òkú obìnrin náà lọ sí ilé ìgbókùúsí.
Olalekan Bakare-Oki; ẹni tó jẹ́ adárí àjọ LASTMA bá àwọn ẹbí obìnrin náà kẹ́dùn, ó gbà á ládùúrà kí Ọlọ́run ó fún wọn ní ìlọ́ra lórí ọ̀fọ̀ náà.
Olalekan bu ẹnu àtẹ́ lu fífi ẹ̀yìn ọkọ̀ rìn lójú pópó, ó ní ó lòdì sí òfin ìwakọ̀ tí ìjọba bu ọwọ́ lù lọ́dún 2018.
Bákan náà ló gbé oríyìn fún àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò lórí bí wọ́n ṣe mú awakọ̀ náà.





