Àwọn ẹbí Patrick Peresousdei ti fi ẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bayelsa pé wọ́n fi ìyà jẹ Patrick títí tó fi kú.
Ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún ni Patrick, ọjọ́ kẹfà tó dé láti àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá ló dágbére fáyé. Àbúrò rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Destiny Peresousdei ló jáde fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọ́n ṣe òun àti Patrick mọ́kumọ̀ku tí wọ́n sì tún tì wọ́n mọ́lé, èyí ló fa àárẹ̀ sí Patrick lára tó sì gba ibẹ̀ kú.
Àwọn ọ̀dọ́ Yenagoa ti faraya, wọ́n jáde ṣe ìwọ́de pé kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe àlàyé ikú tó pa Patrick.
Àlàyé tí Destiny ṣe ni pé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bodmas Kemepadei ló kó àwọn ẹ̀ṣọ́ NSCDC wá ká òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mọ́lé, Badmus ní Patrick ń dúnkokò mọ́ òun, àwọn NSCDC bẹ̀rẹ̀ sí ní lù ú àti Destiny. Wọ́n wọ́ àwọn méjéèjì sínú ọkọ̀ Bodmas ó dilé rẹ̀. ibẹ̀ ni wọ́n ti jẹ ìyà àjẹbólórí, wọ́n lù wọ́n bíi aṣọ òfì àfi bíi bẹ̀m̀bẹ́, lẹ́yìn ìyà ọlọ́sẹ̀ kan ni wọ́n dá Destiny sílẹ̀ wọ́n sì mú Patrick lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, àwọn ọlọ́pàá náà lù ú títí tó fi bẹ̀rẹ̀ àárẹ̀.
Bodmas náà ló pè wọ́n kí wọ́n wá gbé e, nígbà tí ọkọ̀ rẹ̀ dé ibi tí wọ́n ti pàdé, wọ́n wọ́ Patrick jù sílẹ̀ wọ́n sì bá tiwọn lọ. Patrick kò le sọ̀rọ̀, kò le gbápá tàbí gbé ẹsẹ̀, àwọn ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé e lọ kò ríi tọ́jú títí tó fi padà kú lọ́jọ́ kẹfà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Bayelsa ti fèsì láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Musa Muhammad pé Patrick ti fi ara pa kí ó tó dé ọ̀dọ̀ wọn, Musa ní àwọn gba àkọsílẹ̀ Bodmas àti àwọn yòókù àmọ́ ara Patrick kò dá kò sì le è kọ àkọsílẹ̀ ni wọ́n bá kúkú gbé e lọ sílé ìwòsàn níbi tí àwọn dọ́kítà ti wí fún wọn pé kí wọn ó yọ̀ǹda rẹ̀ fún àwọn ẹbí rẹ̀ fún ìtọ́jú tó péye. Ọ̀sẹ̀ kejì tí àwọn dá a sílẹ̀ ni àwọn gbọ́ pé ó ti kú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn kò mọ̀ nípa ikú Patrick rárá àwọn yóò sì wádìí rẹ̀.
Ó di ẹbí mélòó tí irú èyí ti ṣẹlẹ̀ sí? Kò lóǹkà. Ṣé ẹ rántí Moses Mba? Bí òun náà fi fikú ṣèfà jẹ rèé , àwọn ẹbí rẹ̀ fi èsùn kan àwọn ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ ilé Gómìnà Bassey Otu.
Àwọn ẹbí Moses Mba ti tọ ìjọba ìpínlẹ̀ CrossRiver lọ láti bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú tó pa ọmọ wọn.
Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà ìpínlẹ̀ CrossRiver; Bassey Otu pé àwọn ló lu Moses pa.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé Moses Mba; ẹni ọdún mọ́kànlélógún lọ sí ilé Gómìnà Bassey lọ́jọ́ kìíní, oṣù Ògún pé òun fẹ́ jíṣẹ́ Olúwa fún Gómìnà náà.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé náà lu Moses lálùbami won sì tún yìnbọn fún un.
Ilé ìwòsàn Naval Reference Hospital tó wà ní Calabar ni wọ́n gbé e lọ kí wọ́n tó pe àwọn òbí rẹ̀.
Ìyá Moses ṣe àlàyé síwájú síi pé ọmọ òun jẹ́ ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ Red Cross, àwọn ni wọ́n sì san owó ìtọ́jú rẹ̀ tó fi wá padà kú lọ́jọ́ kẹsàn-án.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà Bassey yí ilé ìwòsàn náà po títí tó fi kú wọ́n sì tún gbìyànjú àti gbé òkú rẹ̀ lẹ́yìn tó kú tán.
Ìyá Moses; Victoria wí pé láti ìgbà tí Moses ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́wàá ló ti máa ń ríran, iṣẹ́ Olúwa ló fẹ́ jẹ́ fún Gómìnà Bassey tí wọ́n fi pa á yii.
Àlàyé tí ilé iṣẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ CrossRiver ṣe tako èyí tí àwọn ẹbí Moses ṣe yìí. Kọ́míṣọ́nà fún ìfitónilétí; Erasmus Ekpang wí pé Moses ní ààrùn ọpọlọ, ó lọ sí ilé tí Gómìnà ń gbé tẹ́lẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ òkò lu àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé náà.
Ekpang wí pé Moses tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ náà nígbà tí ara rẹ̀ balẹ̀ tán ó sì kúrò níbẹ̀, ó bu ẹnu àtẹ́ lu lílù tí wọ́n lu Moses àti bí wọ́n ṣe yìnbọn fún un àmọ́ ó wí pé kìí ṣe àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà Bassey.
Kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ CrossRiver náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, ó wí pé àwọn ti darí ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń gbọ́ ẹjọ́ aráàlú, ohun tí wọ́n bá sọ níbẹ̀ ni àwọn yóò ṣe.
Kò tán síbẹ̀ o, Victoria wí pé ọmọ òun kò ní ààrùn ọpọlọ, ó yege nínú ìdánwò WAEC ó sì gba máàkì mẹ́rìndínnígba nínú ìdánwò JAMB.
Ẹ̀kọ́ nípa òwò ṣíse ni Moses fẹ́ kọ́ ní ilé ìwé gíga Calabar kó tó kú yìí. Bákan náà ló wí pé láti ìgbà tí ọmọ òun ti kú ni àwọn ẹ̀ṣọ́ náà pàápàá Emmanuel Dickson ti ń dùnkokò mọ́ ìdílé òun pé gbogbo wọn ni yóò lọ bá Moses lọ́run bí wọn kò bá pa ẹnu wọn mọ́. Títí di àsìkò yìí, ikú Moses kò fi orí tì síbìkan, àwọn ẹbí rẹ̀ padà gba kámú.
Kìí ṣe àwọn èyí ni àkọ́kọ́, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n ti jáde fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá, láti orí ìlọ́nilọ́wọ́gbà dé orí ìṣenimọ́kumọ̀ku. David kò le gbàgbé ìrírí rẹ̀ bọ̀rọ̀:
David Owolabi ní wọ́n gba ẹ̀rọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ òun wọ́n sì bà á jẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wọ́ ọ ní ìwọ́kúwọ̀ọ́, àwọn mẹ́wàá mìíràn ni wọ́n kó pẹ̀lú rẹ̀.
Nígbà tí wọ́n dé àgọ́, wọn kò bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn, ogún ẹgbẹ̀rún náìrà ni wọ́n bèèrè lọ́wọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan tó bá fẹ́ padà sílé. David ní òun takú pé òun yóò rí ọ̀gá nítorí akẹ́kọ̀ọ́ lòun àmọ́ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tí ọ̀gá ní kí òun ó san owó náà.
Àlàyé David tẹ̀síwájú pé òun àti ọ̀rẹ́ òun tí wọ́n jọ kó bẹ̀ wọ́n pé akẹ́kọ̀ọ́ láwọn wọn kò ní irú owó bẹ́ẹ̀ àmọ́ wọ́n ní kò kan àwọn. Nígbà tó yá, wọ́n gbà láti gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà lọ́wọ́ òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀.
Wọ́n tẹ̀lé ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà lọ sí òde láti gba owó náà lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe POS àmọ́ gbogbo wọn ti lọ ilé, wọ́n wá pe èèyàn kan fi àkáńtì rẹ̀ ránṣẹ́, ogún ẹgbẹ̀rún náírà ni wọ́n san sínú àkáńtì náà fún ìdásílẹ̀ òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀. Aago méjì òru ni wọ́n dá David àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílẹ̀.
ọjọ́ wo ni èyí máa dópin?




