ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Sunday, May 31, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ààyè Olóòtú

ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ ṢE ÀWÁRÍ IBI TÍ WỌ́N TI Ń FI ỌMỌ ṢÒWÒ.

wọ́n ní oore ni àwọn ń ṣe - Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ṣe àwárí ibi tí wọ́n ti ń fi ọmọ ṣòwò

by Adeola Olanrewaju
April 23, 2026
in Ààyè Olóòtú, Ìgbé-Ayé, Ìròyìn, Ọ̀rọ̀ Ààbò
0
ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ ṢE ÀWÁRÍ IBI TÍ WỌ́N TI Ń FI ỌMỌ ṢÒWÒ
0
SHARES
8
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ṣe àwárí ibi tí wọ́n ti ń fi ọmọ ṣòwò – Ilé náà wà ní Okuju ní Badagry, ìpínlẹ̀ Èkó.
Òru ọjọ́rú mọ́jú ọjọ́bọ ni àwọn ẹ̀ṣọ́ NSCDC ya wọ inú ilé náà tí wọ́n sì kó wọn ní pápámọ́ra. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin méjìdínlógún ni wọ́n gbà sílẹ̀ àti àwọn ọmọdé mẹ́wàá. Àwọn obìnrin méjìdínlógún yìí wà nínú oyún, gbogbo wọn ló ń retí ọmọ titun jòjòló. – Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ṣe àwárí ibi tí wọ́n ti ń fi ọmọ ṣòwò.
Bákan náà ni ọwọ́ tẹ àwọn tó ń darí ilé òwò ọmọ yìí, orúkọ wọn ni Joy Okeke àti Raphael Agwu. Àwọn obìnrin náà ṣe àlàyé pé wọn kò fi ipá mú wọn, fúnra wọn ni wọ́n fi orúkọ sílẹ̀ lórí ìkànnì facebook.
Ilé náà ni wọn yóò máa gbé títí wọn yóò fi bímọ tí wọn yóò sì tà á. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ẹ̀gbẹ̀rún náírà sí mílíọ́nù kan ààbọ̀ náírà ni wọn ń ta ọmọ kan. Àwọn kan nínú wọn gbé ọmọ tí wọ́n ti bí tẹ́lẹ̀ wá tà níbẹ̀.
Àwọn ọmọdé mẹ́wàá tí wọ́n bá náà kò tíì rí ẹni rà wọ́n ni wọ́n ṣì ṣe wà níbẹ̀. Ọjọ́ orí àwọn obìnrin yìí wà láàrín méjìdínlógún sí ọgbọ̀n, àwọn ọlọ́pàá fi wọ́n hàn ní àgọ́ wọn tó wà ní Ibereoko.
Adedotun Keshinro; ẹni tó jẹ́ adarí àjọ NSCDC ìpínlẹ̀ Èkó ṣe àlàyé pé ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ni awọn fi tọpinpin. Wọ́n ya bò wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.
Keshinro ṣe àlàyé pé àwọn òṣìṣẹ́ wọn wà ní ìgboro bámú. Iṣẹ́ wọn ni láti tan àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n rí oyún he wá sí ilé náà. Wọ́n á rọ̀ wọ́n kí wọ́n wá sí ilé náà fún ìtọ́jú wọn yóò sì tún ta ọmọ náà. Ìdí ni pé wọn kò nílò rẹ̀. Lọ́gán tí wọ́n bá ti bímọ tán ni wọn yóò fún wọn lówó wọn tí wọn yóò sì padà sí ìgboro.
Àlàyé Keshinro tẹ̀síwájú pé oyún bàjẹ́ lára ọ̀kan nínú àwọn obìnrin náà látàrí ìjayà nígbà tí wọ́n ya bò wọ́n. Ìdúnáàdúrà sì ti ń lọ lórí àwọn ọmọdé náà kó tó di pé wọ́n kó wọn.
Keshinro ní ọ̀ràn ńlá ni ohun tí àwọn ẹni náà ṣe yìí. Wọn yóò fà wọ́n lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ fún ìgbẹ́jọ́.
Àwọn ohun tí wọ́n rí gbà padà nínú ilé náà ni ẹ̀rọ ìpọnmi kan, àwọn ìsaàsùn ọbẹ̀, fáánù, gáàsì ìdáná. Àwọn yòókù ni ẹrù ọmọ, àti oúnjẹ lóríṣiríṣi.
Ó wí pé àwọn yóò fa ilé náà lé ìjọba Èkó lọ́wọ́ ni. Ó ṣeéṣe kí wọn ó da ilé náà wó láti fi òpin sí ìtẹ̀síwájú lọ́jọ́ iwájú.
Joy Okeke; ẹni tó ń darí ilé náà ṣe àlàyé ọ̀rọ̀. Ó ní Ìkòròdú ni òun ti ń ṣe òwò òun tẹ́lẹ̀ àmọ́ ibẹ̀ kò gba òun mọ́. Ìdí rèé tí òun fi wá ilé tó tóbi wá sí Badagry.
Kò tíì ju oṣù mẹ́fà lọ tó kó lọ Badagry tí wọ́n fi mú un yìí. Ó ní oore ni òun ń ṣe ní tòun. Ìdí ni pé àwọn tí wọn ní ìṣòro ọmọ bíbí ni òun ń ràn lọ́wọ́. Nípa pé yóò gba ọmọ lọ́wọ́ àwọn tí kò fẹ́ yóò sì tà á fún àwọn tó ń wá ọmọ. Ó ní òun kò le sọ ju bẹ́ẹ̀ lọ àfi ìgbà tí agbẹjọ́rò òun bá dé.
Àwọn obìnrin náà bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀. Wọ́n ní àwọn dúnàádúrà pẹ̀lú àwọn agbódegbà wọn lórí iye tí wọn yóò ra ọmọ wọn. Mílíọ́nù kan ni wọ́n dá fún ọ̀kan nígbà tí wọ́n dá mílíọ́nù kan ààbọ̀ fún òmíràn. Ọ̀kan ṣe àlàyé pé òun gbà láti ta ọmọ náà nítorí ẹni tó fún òun lóyún kò wúlò. Ó ti bí ọmọ méjì tẹ́lẹ̀ tí wọ́n wà ní abúlé pẹ̀lú ìyá rẹ̀.
Wọ́n ṣe àlàyé pé oúnjẹ gidi ni àwọn ń jẹ lójúmọ́, àwọn sì le lo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. Ètò ìlera náà wà fún wọn ni sẹ́pẹ́, ohun kan tí wọn kò le ṣe ni pé wọn kò le kù gìrì jáde nílé náà láìgba àṣẹ. Bákan náà ni wọ́n le yí ọkàn wọn padà pé àwọn kò ṣe mọ́ àmọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní gba owó kankan.
Angwu; ẹni tó jẹ́ igbákejì Okeke náà sọ̀rọ̀. Ó wí pé àwọn obìnrin náà ti ọwọ́ bọ ìwé àdéhùn pé wọn yóò ta ọmọ tí wọ́n bá bí. Ó ṣe àlàyé pé àwọn ń ṣe ìrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣẹ́ oyún wọn ni. Èyí tí wọn yóò fi ṣẹ́ oyún náà dànù ni wọn yóò fi ṣe ìrànwọ́ fún àwọn tó ń wá ọmọ.
Ọ̀rọ̀ Angwu tẹ̀síwájú pé àwọn kò fi ipá mú ẹnikẹ́ni, fúnra wọn ni wọ́n fẹ́ ta ọmọ wọn. Wọ́n lóyún tí wọn kò fẹ́ ni àwọn fi ń ṣe wọ́n lóore. Fún ìdí èyí, àwọn kìí ṣe ọ̀daràn.
Àwọn mìíràn gan-an mú ọmọ tí wọ́n ti bí tẹ́lẹ̀ wá fún títà nítorí bùkátà ló jẹ́ fún wọn. Àwọn yóò bá wọn ta irú ọmọ bẹ́ẹ̀ fún àwọn tó ń wá ọmọ, kò sí ọ̀ràn nínú èyí.
Àwọn obìnrin náà kìí ṣe iṣẹ́ kankan, kí wọ́n jẹun, kí wọ́n sùn kí wọ́n sì lo òògùn wọn ni. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ni kò fẹ́ kí ẹbí rẹ̀ mọ ibi tó wà nígbà tí àwọ́n mìíràn máa ń gba àlejò mọ̀lẹ́bí wọn. Àdéhùn náà tẹ́ wọ́n lọ́rùn ni wọ́n fi ń wá síbẹ̀, àwọn mìíràn ti bí ju ọmọ kan lọ fún wọn tà. Agwu ní òun àti ọmọ òun ni àwọn ń tọ́jú ilé náà àti àwọn obìnrin náà. – Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ṣe àwárí ibi tí wọ́n ti ń fi ọmọ ṣòwò

ADVERTISEMENT
ADVERTISEMENT
Facebook Comments Box

Related

Tags: #badagry#iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnline#newsfeed#newstodaysnewsbabyfactrybabytraffickingbreaking newsbreakingnewschildtraffickingIwe Iroyin Yorubanewsnews onlinenscdcpregnancysafety
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ NÍ ÌPÍNLẸ̀ EDO.- DELTA

ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

Recommended

ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

ÌDÁJỌ́ TI WÁYÉ LÓRÍ ÀWỌN TÓ Ń ṢE ÒWÒ ỌMỌ NÍ ONDO.

3 months ago
ADÁJỌ́ PÀṢẸ KÍ WỌN Ó YẸGI FÚN ABDULRAHMAN.

ADÁJỌ́ PÀṢẸ KÍ WỌN Ó YẸGI FÚN ABDULRAHMAN.

10 months ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.