Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ti tẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Adekunle Ajaasin méjì tí wọ́n fipá bá akẹgbẹ́ wọn lájọṣepọ̀.
Olushola Ayanlade; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé àwọn ẹni náà tan ọmọbìnrin ẹni ogún ọdún náà lọ sí ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ darapọ̀ mọ́ wọn nílé ìwé náà. Ọmọbìnrin yìí ti mọ Queen Sodo; ẹni ọdún mọ́kàndínlógún láti ilé ìwé girama ó sì lọ kíi nígbà tó wọ ilé ìwé gíga tí òun náà wà.
Nígbà tó dé ilé Queen, ó mu nǹkan mímu láì mọ̀ pé Queen ti fi òògùn olóró sínú rẹ̀, nígbà tí obìnrin yìí sùn lọ, Queen bọ́ síta ó sì pe ọkùnrin náà wọlé láti bá a lájọṣepọ̀.
Aráalé Queen ló gbọ́ ohun tí kò fanimọ́ra láti inú yàrá Queen ló yọjú wo inú ilé náà, ó ṣí ilẹ̀kùn yàrá náà ó sì bá ọkùnrin náà lórí ọmọ yìí.
Wọ́n ṣe aájò ọmọ yìí dé ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.
Àwọn afurasí méjéèjì jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ ni àwọn fún un ní òògùn olóró mu àti pé kìí ṣe tirẹ̀ ni àkọ́kọ́.
Ayanlade wí pé àwọn afurasí náà yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí bá parí ó sì rọ àwọn òbí láti máa gba àwọn ọmọ wọn níyànjú lóòrèkóòrè.
oro bale kan baale, oro ifipabanilo kan pasito Aka-Bashorun:
Pásítọ̀ Aka-Bashorun Olawale; ẹni tó tún jẹ́ agbẹjọ́rò ti balẹ̀ síwájú adájọ́ Hakeem Oshodi ti ilé ẹjọ́ gíga Ikeja lórí ẹ̀sùn pé ó fi ọwọ́ tẹ ọmú ọmọdébìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan.
Ìròyìn fi yé wa pé Pásítọ̀ Olawale jẹ́ pásítọ́ ní ìjọ ìràpadà, ẹ̀sùn oníkókó kan tí ìjọba fi kàn án náà ni pé ó fi ọwọ́ tẹ ọmú ọmọdébìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan ní agbègbè Iwaya, ìpínlẹ̀ Èkó.
Agbẹjọ́rò ìjọba; Funmilola Aluko wí pé ohun tí pásítọ̀ Olawale ṣe yìí tako òfin ipínlẹ̀ Èkó àmọ́ agbẹjọ́rò Olawale wí pé Olawale ko jẹ̀bi ẹ̀sùn náà. Morenikeji Oyekunle rọ ilé ẹjọ́ láti gba onídùúró Olawale nítorí pé kò le sá lọ àti wí pé pásítọ̀ ni.
Agbẹjọ́rò fún ìjọba; Funmilola Aluko tako ẹ̀bẹ̀ Morenikeji ó sì rọ ilé ẹjọ́ láti wo ọ̀rọ̀ náà dáadáa.
Adajo Hakeem Oshodi gba onídùúró Olawale pẹ̀lú àṣẹ pé ó gbọ́dọ̀ yọjú ní gbogbo ìgbẹ́jọ́ tió yóò wáyé.
Àlàyé tí ọmọdébìnrin ìgbà náà; ẹni tó ti pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nísìn yìí ṣe ni pé lọ́dún 2010 nígbà tí òun wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ ni bàbá òun mú òun lọ gbé ní ilé pásítọ̀ Olawale kí òun le tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ kí òun sì le máa kópa nínú ẹgbẹ́ akọrin ìjọ. Ó wí pé bí òun ṣe dé ibẹ̀́ ni Olawale ti ń ṣe òun mọ́kumọ̀ku, yóò fi ọwọ́ tẹ gbogbo ọmú rẹ̀ yóò sì tún lù ú lálùbami bí ó bá fìdí rẹ́mi nílé ìwé.
Ó ní òun padà sá kúrò nílé Olawale lọ́dún náà lọ́hùn-ún tí òun sì ṣe àlàyé fún ìyá òun.
Lọ́dún 2023 tí òun gbọ́ pé Olawale ṣe irú èyí fún ọmọdébìnrin mìíràn ni òun pe ẹjọ́ náà. Ó wí pé ẹlẹ́rìí òun ni olùkọ́ òun nígbà náà; Arábìnrin Akingbeoyewa nítorí pé òun sọ fún un nígbà náà.
Adájọ́ Oshodi pàṣẹ kí Olawale ó san ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà fún ọmọbìnrin náà ṣáájú ìgbẹ́jọ́ tó ń bọ̀. Ó sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Ọ̀pẹ.
Bàbá ẹni ọdún méjìdínláàdọ́ta kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanuel George ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn tó fi ipá gba ìbálé ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjìlá kan.
A gbọ́ pé nínú keke maruwa tí bàbá yìí ń w ni ó ti já ìbálé ọmọ náà.
Ọjọ́ kẹfà, oṣù Ọwẹ́wẹ̀ yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ ní agbègbè Mini Orlu ní Portharcourt tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Rivers.
Ọmọbìnrin yìí ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó wá lo ìsinmi lọ́dọ̀ rẹ̀ rán níṣẹ́ nígbà tí Emmanuel fi ipá wọ́ ọ sínú keke rẹ̀, ó fi aṣọ díi lẹ́nu ó tún so ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn kó tó fi ipá já ìbálé rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó sálọ.
Ọmọ yìí délé ròyìn fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀, wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn wọ́n sì fi tó àwọn ọlọ́pàá létí.
Ìtọpinpin awọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi lọ gbé Emmanuel níbi tó lọ farasin sí, kò tilẹ̀ jiyàn, pẹ̀lú sùúrù ló fi jẹ́wọ́ pé òun bá ọmọ náà lò lóòótọ́.
Grace Iringe-Koko; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ ó sì ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn òbí láti mójútó àwọn ọmọ wọn.
Láyé òde òní, kìí ṣe obìnrin nikan ni wọ́n ń fipá bá lò pọ̀ mọ́ báyìí, ó kan ọkùnrin gan pàápàá.
Abdullahi Abass yóò lo gbogbo ìṣẹ̀mí rẹ̀ yòókù lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn pé ó fipá bá ọmọdékùnrin kan tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lájọṣepọ̀.
Ẹni ọdún mọ́kàndínlógún ni Abdullahi Abass, iṣẹ́ olùkọ́ ló ń ṣe nílé ìwé aládàáni kan ní agbègbè Kwali.
A gbọ́ pé lọ́jọ́ kọkàndínlógún, oṣù Ẹrẹ́nà, lẹ́yìn tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jáde ilé ìwé, Abdullahi rán akẹ́kọ̀ọ́ kan kí ó lọ pe ọmọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́sàn-án náà wá, ó tan ọmọ náà lọ sí kọ̀rọ̀ ó sì fipá bá a lò láti ihò ìdí.
Ọmọ yìí sọ fún ìyá rẹ̀ wọ́n sì fi ọlọ́pàá gbé e. ẹ̀sùn oníkókó méjì ni ìjọba fi kan Abdullahi; ìfipábánilò àti ìṣenimọ́kumọ̀ku nípa ti ìbálòpọ̀.
Ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Ọ̀wàrà ni Abdullahi farahàn nílé ẹjọ́ gíga Abuja níwájú Adájọ́ M. Osho-Adebiyi, lẹ́yìn gbogbo atótónu àti àwíjàre, adájọ́ wí pé Abdullahi jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà ó sì dá ẹ̀wọ̀n gbére fún un




