Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ogun.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́https://share.google/K77aGn1Ua64bC9OEU ilé ìwé gíga Olabisi Onabanjo ní ìpínlẹ̀ Ogun ti fi ẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà pé wọ́n yìnbọn mọ́ àwọn. Níbi tí àwọn ti ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn wọ́rọ́wọ́ tí àwọn kò sì fa wàhálà kankan. Wọ́n ní ṣeni àwọn ọlọ́pàá ṣíná ìbọn bolẹ̀ tí wọ́n sì tún lu àwọn tí ọwọ́ wọ́n tẹ̀ lálùbami lẹ́yìn náà ni wọ́n tún kó àwọn kan lọ sí àgọ́ wọn.
Nínú àtẹ̀jáde tí ààrẹ ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé; Kehinde Bamigbose àti akọwé gbogbogbò; Olajire Emmanuel bu ọwọ́ lù ni a ti ríi kà pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tako bí àwọn ọlọ́pàá ṣe mú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé náà sí àhámọ́ láìnídìí kan pàtó.
Ààrẹ ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gbéra pẹ̀lú akẹgbẹ́ rẹ̀ kan lọ sí àgọ́ Oru-Ijebu níbi tí wọ́n mú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sí, nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀ tí wọ́n bèèrè àwọn akẹgbẹ́ wọn tí wọ́n mú sí àhámọ́, àwọn ọlọ́pàá àgọ́ náà fi ìfọ́tí olóòyì pàdé wọn, wọ́n lu àwọn méjéèjì bíi kíkú bíi yíyè wọ́n sì tún fún Kehinde lọ́rùn bíi kí ó kú.
Lẹ́yìn èyí, ààrẹ ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà tún padà lọ pẹ̀lú àwọn adarí mìíràn, wọ́n lọ sí àgọ́ náà láti bá àwọn ọlọ́pàá náà sọ̀rọ̀ ní tùbí-ǹ-nùbí lórí ìwà tí wọ́n hù àmọ́ níṣe ni àwọn ọlọ́pàá náà tún ṣíná ìyà fún wọn, wọ́n ṣe wọ́n bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú wọ́n sì tún yìnbọn fún ọ̀kan nínú wọn lápá. Lẹ́yin náà ni wọ́n kó wọn dà sí àtìmọ́lé.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ogun lati enu ẹgbẹ akẹ́kọ̀ọ́ ti won fárígá báyìí pé àwọn kò ní gbà kí èyí ó lọ bẹ́ẹ̀, wọ́n ní ìwà ìfìyàjẹni lọ́nà àìtọ́ gbáà ni èyí, wọ́n ní ìwà àṣìlò agbára ni àwọn ọlọ́pàá náà hù ó sì tún tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀. Wọ́n ké sí ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun láti dá sí ọ̀rọ̀ yìí.
Wàyí o, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti fèsì láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Oluseyi Babaseyi pé irọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ní àwọn kò mú akẹ́kọ̀ọ́ kankan àwọn kò sì lu ẹnikẹ́ni.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọ́n fi ìyà jẹ wọ́n lọ́nà àìtọ́. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Yaba kò le gbàgbé ohun tí ojú wọn rí bọ̀rọ̀. David kó àlàyé rò pé:
David Owolabi ní wọ́n gba ẹ̀rọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ òun wọ́n sì bà á jẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wọ́ ọ ní ìwọ́kúwọ̀ọ́, àwọn mẹ́wàá mìíràn ni wọ́n kó pẹ̀lú rẹ̀.
Nígbà tí wọ́n dé àgọ́, wọn kò bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn, ogún ẹgbẹ̀rún náìrà ni wọ́n bèèrè lọ́wọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan tó bá fẹ́ padà sílé. David ní òun takú pé òun yóò rí ọ̀gá nítorí akẹ́kọ̀ọ́ lòun àmọ́ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tí ọ̀gá ní kí òun ó san owó náà.
Àlàyé David tẹ̀síwájú pé òun àti ọ̀rẹ́ òun tí wọ́n jọ kó bẹ̀ wọ́n pé akẹ́kọ̀ọ́ láwọn wọn kò ní irú owó bẹ́ẹ̀ àmọ́ wọ́n ní kò kan àwọn. Nígbà tó yá, wọ́n gbà láti gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà lọ́wọ́ òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀.
Wọ́n tẹ̀lé ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà lọ sí òde láti gba owó náà lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe POS àmọ́ gbogbo wọn ti lọ ilé, wọ́n wá pe èèyàn kan fi àkáńtì rẹ̀ ránṣẹ́, ogún ẹgbẹ̀rún náírà ni wọ́n san sínú àkáńtì náà fún ìdásílẹ̀ òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀. Aago méjì òru ni wọ́n dá David àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílẹ̀.
Bákan náà ni ó wí pé àwọn ọlọ́pàá náà kò fi orúkọ wọn pe ara wọn bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò wọṣọ, ìnagijẹ ni wọ́n ń pe ara wọn, ọ̀kan nínú wọn ń jẹ́ Agba.
Ọ̀rọ̀ yìí ti dé etí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó, alukoro wọn; Abimbola Adebisi wí pé àwọn ti gbọ́ nípa ẹ̀sùn náà wọ́n sì ti tari rẹ̀ lọ sí ẹ̀ka tí yóò wádìí rẹ̀. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ọmọ náà yóò yọjú sí ìgbìmọ̀ náà. Títí di àsìkò yìí, kò tíì sí èsì kan gúnmọ́ láti ìgbìmọ̀ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ń sẹ́ gbogbo àwọn ẹ̀sùn yìí lọ́tùn-ún lósì síbẹ̀ àwọn èèyàn ò yé pariwo wọn síta. Bí wọn kò ṣe àwọn èèyàn báṣubáṣu wọn yóò lọ́ wọn lọ́wọ́ gbà.
Nínú oṣù Ṣẹẹrẹ ni ọ̀gbẹ́ni Wojuola fi ẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n gba gbogbo owó rẹ̀ nítorí pé ó ṣe oore fún èèyàn kan tó padà kú. Bí ìròyìn náà ṣe lọ rèé:
Ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Wojuola ti jáde síta fi ẹ̀sùn kan ọ̀gá ọlọ́pàá àgọ́ GRA ní Asaba tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Delta pé ó fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kan òun látàrí pé òun ṣe ìrànwọ́ fún ẹnìkan tí òun rí lójú pópó.
Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2025 ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀, Wojuola ní òun ń lọ nínú ọkọ̀ òun lọ́jọ́ náà ni òun rí ọkùnrin kan tí ó ń japoró ikú tí kò le mí dáadáa, àwọn èèyàn kàn ń wò ó níran wọn kò ṣe ìrànwọ́ fún un ni òun bá gbé e sínú ọkọ̀ òun, bí ó ṣe dé ilé ìwòsàn ni ọkùnrin náà kú. Ilé ìwòsàn náà pe àwọn ọlọ́pàá nítorí òun kò mọ arákùnrin náà rí, òun kàn ṣe ìrànwọ́ fún un ni.
Wojuola ṣe àlàyé pé àwọn ọlọ́pàá àgọ́ GRA tí wọ́n pè fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kan òun, wọ́n mú òun ní tìpátìkúùkù kọ àkọsílẹ̀ pé òun ló pa ọkùnrin náà, ọ̀gá àgọ́ náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Joseph Udoh sọ fún òun lójúkojú pé òun á fi ìyà jẹ ẹ́, ṣe bí ìwọ ni Jésù olùgbàlà, nígbà tí mo bá ṣetán pẹ̀lú rẹ, oò ní ṣe irú ẹ̀ mọ́.
Àti ìgbà náà ni wọ́n ti ń bá Wojuola ṣe ẹjọ́, wọ́n fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn án. Àwọn ẹbí ẹni tó kú náà jáde ṣe àlàyé pé ọmọ wọn ní àìlera tẹ́lẹ̀ àmọ́ àwọn ọlọ́pàá kò dá Wojuola sílẹ̀. Lẹ́yìn tí àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba dá síi tí wọ́n sì padà yọ̀ǹda rẹ̀ lẹ́yìn bíi oṣù mẹ́wàá, àwọn ọlọ́pàá wọ́ gbogbo owó inú àpò owó rẹ̀ wọ́n sì fún un ní ẹgbẹ̀rún méjì náírà kó fi wọ ọkọ̀ relé.
Wojuola ní ó wá yé òun ìdí tí àwọn èèyàn kò fi ki ń ṣe ìrànwọ́ fún ẹlòmíràn, ó ní àṣìṣe gbáà ni òun ṣe òun kò sì ní ṣe irú rẹ̀ mọ́.
Lẹ́yìn tó kéde síta ni ìjọba pàṣẹ kí wọn ó dá gbogbo owó rẹ̀ padà fún un. Mélòó mélòó irú ẹ̀?





