Àgùnbánirọ̀ ni Rofiat Lawal, ìlú Ogbomosho ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ó ti ń sin ilẹ̀ bàbá rẹ̀, Ogbomosho náà ló ń lọ tí àwọn ajínigbé fi gbé e lójú ọ̀nà Benin sí Ìbàdàn.
Rofiat lọ sí ilé àwọn òbí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Edo, Ogbomosho níbi tó ti ń sìnlú ló ń padà sí tí àwọn ajínigbé fi gbé e lọ.
Ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agbakwara ṣe àlàyé pé Rofiat pe òun láti àkàtà àwọn ajínigbé náà pé kí òun ó bá òun wá ogún mílíọ̀nù náírà owó ìtúsílẹ̀.
Agbakwara ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé àwọn òbí Rofiat kò là bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ṣagbe, ìbo ni kí wọ́n ti rí adúrú owó náà?
Aminat Lawal, ẹni tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Rofiat bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé Rofiat pè lórí aago tó sì ń sunkún pé kí wọn ó bá òun tu owó ìtúsílẹ̀ náà. Ogún mílíọ̀nù náírà ni wọ́n bèèrè fún àmọ́ àwọn òbí rẹ̀ ti gba sí mílíọ̀nù márùn-ún náírà.
Aminat rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo ọmọ Nàìjíría láti má dá àwọn dá èyí kí wọn ó dákun dábọ̀ fi iye tí wọ́n bá ní ránṣẹ́ kí wọn ó le gba Rofiat kalẹ̀.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé nínú ọ̀rọ̀ tí Rofiat sọ ni wọ́n ti ríi dì mú pé awakọ̀ náà ló kó wọn lé àwọn ajinigbe lọ́wọ́.
Èrò Ìbàdàn ni ọkọ̀ náà kó láti Benin, bó ṣe dé Ore ló dúró tí àwọn ajinigbe ọ̀hún sì jáde láti inú igbó. Fúnra awakọ̀ náà ló kó wọn lé àwọn ajínigbé náà lọ́wọ́ tó sì bá tirẹ̀ lọ.
Aminat ṣe àlàyé pé àwọn ti kàn sí àjọ àgùnbánirọ̀ NYSC lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ èsì tí àwọn gbà náà ni pé Rofiat kò gba ìyànda tó fi lọ sí ilé, wọ́n ní àwọn ti ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn àgùnbánirọ̀ láti máa gba ìyànda bí wọ́n bá fẹ́ lọ sí ilé tàbí rin ìrìnàjò kankan.
Àjọ àgùnbánirọ̀ wí pé àwọn ti da àwọn ẹ̀ṣọ́ síta láti wá ọmọ náà jáde.
Ìjínigbé kìí ṣe ìròyìn mọ́ lórílẹ̀-ède Nàìjíríà, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń gbé àwọn èèyàn bí ìgbà tí wọ́n bá gbé ewúrẹ́. Kò fẹ́rẹ̀ sí ibi tí ààbò ti péye mọ́ nílùú yìí, Nàìjíríà wá di kóńkó jabele; kálukú ń ṣe tirẹ̀.
Mélòó ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé tí a fẹ́ sọ nípa rẹ̀? Ṣé ti àwọn ọmọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé Chibok ni tàbí ti àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n kó nígbà ìṣèjọba Buhari?
Mélòó àwọn arìnrìnàjò tí wọ́n ti dàwátì làtàrí ìjínigbé yìí?
Ṣé ẹ rántí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó tí wọ́n dá lọ́nà níjọ́sí? A mú ìròyìn náà pé
‘Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó tó tó ogún ni àwọn ajínigbé dá ọkọ̀ wọn lọ́nà tí wọ́n sì kó gbogbo wọn lọ.
Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Maiduguri àti Jos ni wọ́n gbéra láti lọ sí ibi ìpéjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn ọlọ́dọọdún ní Benue, ìgbà tí wọ́n dé Otukpo ni àwọn ajínigbé dá ọkọ̀ wọn lọ́nà tí wọ́n sì kó gbogbo wọn lọ.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Benue; Catherine Anene wí pé lóòótọ́ ni àwọn gba ìpè pé wọ́n jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ tí àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ó wí pé nǹkan bí aago márùn-ún àbọ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀, àwọn ọlọ́pàá ti kán lu ìgbẹ́ láti wá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jáde’
Lọ́pọ̀ ìgbà, àlọ la máa ń gbọ́ àbọ̀ kìí dájú nígbà mìíràn. Ìdí ni pé púpọ̀ nínu àwọn tí wọ́n bá jí gbé yìí ni kìí dé mọ́ kódà bí àwọn ẹbí wọn san owó ìtúsílẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò mọ̀ ju àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lọ, ìgbà wo ni a ó ṣe èyí dà?
Tàwọn tí wọ́n ń dáni lọ́nà wà lápá kan. Lápá kejì ni ti àwọn ẹbí ẹni tó ń jíni lọ́mọ gbé tàbí tanni fún àwọn ajínigbé. Ṣé ẹ rántí Joy? Joy tí ó gbé ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ tà?
A kọ nípa rẹ̀ nígbà náà pé “Bí wọ́n bá sọ fún ẹ̀gbọ́n Joy pé omi ni yóò se ẹja jinná, yóò jiyàn rẹ̀. Àbúrò rẹ̀ tó finú tán jí ọmọ rẹ̀ gbé láti tà fún àwọn tí yóò lò ó.
Agbègbè Kwamba, Suleja ní ìpínlẹ̀ Niger ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀. Ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Ọ̀pẹ ọdún tó kọjá ni ìyá ọmọ oṣù mẹ́fà yìí fi ọmọ rẹ̀ ti Joy; ẹni tó jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ pé òun fẹ́ jáde.
Dídé tí yóò dé lálẹ́, kò bá ọmọ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni kò bá Joy tó fi ti ọmọ náà. Kò kọ́kọ́ bìkítà pé bóyá ó sáré jáde ni àmọ́ nígbà tí Joy kò gbé aago tí ilẹ̀ fi ṣú ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé ewu ń bẹ lóko lóńgẹ́.
Obìnrin yìí kàn sí àwọn ọlọ́pàá Suleja wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
Ohun tó mú kí ìwádìí náà ó rọrùn ni àwọn ara ilé rẹ̀ méjì tí wọn kò sí nílé láti ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, bí ọ̀kan nínú wọn ṣe dé ni àwọn ọlọ́pàá he é bíi ìgbín, òun ló júwe ibi tí Joy àti àwọn méjì yòókù wà.
Agbègbè Kubwa ní Abuja ni wọ́n gbé ọmọ oṣù mẹ́fà náà lọ láti tàá, Emmanuel Ezekiel jẹ́wọ́ pé àwọn ti ń gbìmọ̀pọ̀ tipẹ́ láti jí ọmọ náà gbé pẹ̀lú Joy, nígbà tí àwọn sì rí anfààní láti gbé e ni àwọn ṣe jọ jí ọmọ náà gbé lọ tà.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ Joy àti Favour, wọ́n mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ilé Patience Obana tí yóò bá wọn ta ọmọ náà, kò tíì rí ọmọ náà tà tí àwọn ọlọ́pàá fi mú un. Àlàáfíà sì ni ọmọ yìí wà.
Wasiu Abiodun; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Niger bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé àwọn mú Joy Nuwa; ẹni ogún ọdún tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Nasarawa, Emmanuel Ezekiel; ẹni ọgbọ̀n ọdún tó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Niger, Favour James; ẹni ọdún márùndínlọ́gbọ̀n tó sì jẹ́ ọmọ ìlú Niger bákan náà àti Patience Obana; ẹni ọdún mẹ́tàlélógún tí òun sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Abuja lórí ẹ̀sùn ìjọ́mọgbé.
Kìí wá ṣe pé ẹ̀sùn ìjọ́mọgbé nìkan o, ọmọ títà ni iṣẹ́ Patience, Kubwa ní Abuja ló tẹ̀dó sí.
Àwọn ọlọ́pàá ti gba ọmọ náà padà lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì ti gbé e fún ìyá rẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Abiodun wí pé àwọn ti kó àwọn afurasí mẹ́rin yìí sí àtìmọ́lé, wọn yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́ láìpẹ́’
Bíntín ni èyí nínú àwọn ìròyìn ìjínigbé tó wáyé nílé àti lóko. Ààbò Ọlọrun ni kí a máa bèèrè fún ní ìlú yìí báyìí.