Àwọn agbésùnmọ̀mí ya wọ abúlé Adanla ní Igbaja, ìjọba ìbílẹ̀ Ifelodun, ìpínlẹ̀ Kwara. Ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n ni wọ́n ya wọ abúlé náà ní nǹkan bíi aago méje alẹ́, wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀ láti ojúlé sí ojúlé, àwọn èèyàn méje ni wọ́n pa nínú ìkọlù náà.
Àlàgbà ìlù, ẹni tó jẹ́ adarí ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ agbègbè náà; Àlàgbà Olaitan Oyin-Zubair ṣe àlàyé pé lọ́gán tí àwọn gba ìpè nípa ìkọlù náà ni àwọn ti ké sí àwọn ọdẹ ìletò tó sún mọ́, ọ̀gágun agbègbè náà fi àwọn ológun ránṣẹ́ àmọ́ kí wọ́n tó dé ibẹ̀, àwọn agbésùnmọ̀mí náà ti pa èèyàn méje, wọ́n ṣe obìnrin kan léṣe wọ́n sì kó àwọn èèyàn mẹ́jọ lọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ní àwọn kò tíì gbọ́ nǹkankan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà títí di àsìkò yìí.
Ni ipinle Kwara kan na, won tun se ikolu si Isapa:
A gbọ́ pé ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ajé ni àwọn agbébọn náà tí iye wọn ń lọ bíi ogún sí ọgbọ̀n ya wọ àdúgbò náà tí wọ́n yìnbọn lákọlákọ, wọ́n pín ara wọn káàkiri gbogbo àbáwọ inú ìlú náà pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ màálù.
Wọ́n tọ àárín ìlú náà tí wọ́n sì ń yìnbọn mọ́ gbogbo ilé, ojú ọta ìbọn kún ojú fèrèsé àti ògiri nígbà tí wọ́n lọ tán.
Àwọn èèyàn mọ́kànlá ni wọ́n kó lọ pẹ̀lú aláboyún kan, méje nínú wọn lọ jẹ́ mọ̀lẹ́bí kan.
Àwọn tí wọ́n kó lọ náà ni Talatu Kabiru; ọmọ ọdún mẹ́fà, Magaji; ọmọ ọdún mẹ́fà, Kande; ọmọ ọdún márùn-ún, Hadiza; ọmọ ọdún mẹ́wàá, Mariam; ọmọ ọdún mẹ́fà, Saima; ọmọ ọdún márùn-ún, Habibat, Fatima Yusuf, Sarah Sunday; aláboyún ẹni ọdún méjìlélógún, Lami Fidelis àti Haja Na Allah tó ń tọ́mọ lọ́wọ́.
Àwọn ará ìlú náà ṣe àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi èyí tó burú jáì, inú fu àyà fu ni àwọn èèyàn wà wọn kò sì mọ ohun tí yóò tún ṣẹlẹ̀.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ti fèsì pé àwọn ti kán lu igbó láti wá àwọn èèyàn náà jáde nínú igbó tó pààlà Isapa àti Eruku.
Wọ́n wí pé ìkọlù yìí wáyé lẹ́yìn èyí tí ìkọlù ti ilé ìjọsìn Eruku níbi tí wọ́n ti kó àwọn èèyàn méjìdínlógójì. Láti ìgbà náà ni àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ti kún àwọn abúlé náà àmọ́ èyí kò dá àwọn agbébọn náà dúró.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ní àwọn kò tíì gbọ́ nǹkankan lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.
Ni Baruba, ipinle Kwara yii naa:
Ọjọ́ àìkú, ọjọ́ kọkànlélógún, osu Erena ni àwọn agbébọn mẹ́wàá ṣàdédé ya wọ ibùdókọ̀ Ilesa Baruba tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Baruten, ìpínlẹ̀ Kwara. Ilé ìgbafẹ́ kan tó wà ní ibùdókọ̀ yìí ni wọ́n ṣínà ìbọn bò tí wọ́n sì pa àwọn èèyàn mẹ́fà nígbà tí àwọn èèyàn méjì mìíràn farapa.
Ilé ìgbókùúsí Baruba ni wọ́n kó àwọn tó kú náà lọ nígbà tí wọ́n kó àwọn tó farapa náà lọ sí ilé ìwòsàn.
Aago mẹ́sàn-án àbọ̀ alẹ́ ni wọ́n ṣe ìkọlù ti ibùdókọ̀ Baruba yìí, nígbà tó di aago mọ́kànlá àbọ̀ alẹ́ ọjọ́ kannáà, àwọn ikọ̀ agbésùnmọ̀mí mìíràn tún ṣe ìkọlù sí Kemanji ní ìjọba ìbílẹ̀ Kaiama. Àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ kojú wọn wọ́n sì mú mẹ́ta balẹ̀ nínú wọn àmọ́ àwọn náà yin ọdẹ kan níbọn ó sì padà kú sí ilé ìwòsàn.
Yusuf Samba ni orúkọ ọdẹ tí wọ́n yìnbọn pa náà, òun àti ikọ̀ rẹ̀ ni wọ́n dá àwọn agbésùnmọ̀mí náà lọ́wọ́ kọ́ tí wọ́n sì fi ìbọn ṣe mẹ́ta léṣe nínú wọn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara sọ̀rọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Toun Ejire-Adeyemi pé àwọn gba ìfisùn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ìkọlù tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Kwara, wọ́n ní ọwọ́ ti tẹ èèyàn kan tó ń fún àwọn agbésùnmọ̀mí lọ́wọ́. Toun wí pé ẹni náà ti jẹ́wọ́ pé òun ló ń fún àwọn agbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ tí wọ́n fi wá ṣe àwọn ìkọlù náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá sọ nínú ọ̀rọ̀ wọn pé àwọn ti ṣe àlékún àwọn ọlọ́pàá agbègbè náà, àwọn sì ti dá àlàáfíà padà sípò. Wọ́n ní ẹni tọ́wọ́ bà náà yóò wúlò púpọ̀ fụ́n ìwádìí ìkọlù yìí wọ́n sì ṣe ìlérí pé àwọn yóò mú àwọn tó ṣe ìkọlù náà.
Bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara ò tilẹ̀ wí nǹkan sí gbogbo ìkọlù yìí, tó tún já sí pé àwọn obìnrin ìlú tí wọ́n lọ ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ní iwájú ilé ìjọba náà bá ìyà bọ̀ ni, wọ́n lù wọ́n bíi bàrà nínú fọ́nrán tó lu síta, Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger kò ṣe bẹ́ẹ̀, ó fi ọ̀rọ̀ tútù ránṣẹ́ sí àwọn èèyàn rẹ̀ pé:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger; Muhammed Bago ti bá àwọn ará ìlú rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí bí ìṣèjọba rẹ̀ ṣe lọ lọ́dún yìí àti ètò tó ní fún wọn lọ́dún tó ń bọ̀ ìyẹn ọdún 2026.
Bago ṣe àlàyé pé ìjínigbé, ìgbésùnmọ̀mí àti ètò ààbò tó mẹ́hẹ ló fẹ́ mi ìṣèjọba òun wò lọ́dún yìí àmọ́ òun dúró ṣinṣin, òun kò jẹ́ kí èyí ó pa ìṣèjọba òun lára tàbí da ètò òun rú, òun dúró wámú òun sì kojú rẹ̀ láti ṣe àṣeyọrí ní ìpínlẹ̀ náà.
Ó gbé oríyìn fún àwọn ará ìpínlẹ̀ Niger tí wọ́n dúró ní ìṣọ̀kan, ìrẹ́pọ̀ àti ìgbàgbọ́ nínú ìṣèjọba rẹ̀. bago rọ àwọn èèyàn rẹ̀ láti má dẹ́kun àtìlẹ́yìn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn lọ́dún tó ń bọ̀, ó ní òun ti ṣètò àlàkalẹ̀ lórí ìṣèjọba rere, ètò ààbò, ọrọ̀ ajé àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ fún ọdún 2026.
Mo kí gbogbo ẹ̀yin ará ìpínlẹ̀ Niger àti ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀ kú ìpalẹ̀mọ́ ọdún titun nínú èyí tí ìrètí wa ó ti di ọ̀tun.
Ọdún tó parí yìí jẹ́ ọdún tó dán ìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀kan wa wò pàápàá nípa ti ètò ààbò tó mẹ́hẹ àmọ́ mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ yín fún ìgbàgbọ́ tí ẹ ní nínú ìṣèjọba mi.
Ìjọba nìkan kò le dá ìlú ṣe bíkòṣe pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yín, a gbọdọ̀ wà ní ìrẹ́pọ̀ àti ìṣọ̀kan kí a le tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀.
Mo fi ń dá a yín lójú pé ìṣèjọba mi wà fún ìlọsíwájú, ààbò, àti gbogbo ohun tó le mú kí ayé yín dẹrùn – Gómìnà Muhammed Bago.




