Àwọn agbẹjọ́rọ̀ Chimamanda ti kọ ìwé sí ilé ìwòsàn Euracare lórí ikú ọmọ rẹ̀; Nkanu. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà pé wọn kò kọbi ara sí iṣẹ́ wọn, ìwà àìbìkítà wọn sì mú ẹ̀mí ọmọ oṣù mọ́kànlélógún náà lọ.
Ọjọ́ kẹwàá, oṣù ṣẹẹrẹ ni ilé iṣẹ́ Chimamanda àti agbẹjọ́rò rẹ̀ kọ ìwé náà ránṣẹ́ tí wọ́n sì bu ọwọ́ lù ú.
Wọ́n kọ ọ́ pé ọjọ́ kẹfà, oṣù ṣẹẹrẹ ni wọ́n darí ọmọ náà sí ilé ìwòsàn Euracare láti ilé ìwòsàn Atlantis Pediatric fún àwọn àyẹ̀wò ìmúrasílẹ̀ kí wọ́n tó gbé e lọ sí òkè òkun fún ìtọ́jú.
Àwọn àyẹ̀wò náà ni àyẹ̀wò bí ọkàn ṣe ń ṣiṣẹ́ sí, àwòrán ọpọlọ, díríìbù tí yóò mú ọkàn rẹ̀ le títí yóò fi dé òkè òkun àti àyẹ̀wò ọ̀pá ẹ̀yìn rẹ̀. Gbogbo èyí ni àwọn dọ́kítà òkè òkun nílò kí wọ́n le bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bó bá ṣe ń balẹ̀ sọ́hùn-ún.
Wọ́n fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn náà pé òògùn propofol ni wọ́n fi sínú díríìbù tó lọ sínú ọkàn ọmọ náà, nígbà tí wọ́n parí àwòrán ọpọlọ tí wọ́n fẹ́ gbé e lọ sí yàrá tí yóò ti ṣe àyẹ̀wò ọkàn, ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí ni fi àwọn àmì ìnira hàn. Wọn kò tún tẹ̀lé ìlànà gbígbé aláìsàn láti yàrá kan lọ sí yàrá mìíràn, èjìká ni dọ́kítà fi gbé ọmọ náà lọ sí yàrá àyẹ̀wò ọkàn ní èyí tó mú kí ipò ọmọ náà burú síi nítorí ó pa èémí rẹ̀ lára, wọn sì ti kùn ún lọorun lásìkò yìí.
Gbogbo ìwà àìbìkítà tí wọ́n hù yìí mú kí èémí ọmọ náà ó lọ sílẹ̀ pátápátá tó sì padà kú lọ́jọ́ keje, oṣù ṣẹẹrẹ.
Ẹ̀sùn oníkókó mẹ́rin tí wọ́n fi kan ilé ìwòsàn Euracare nínú ìwé náà ni àpọ̀jù òògùn propofol, àìṣètó afẹ́fẹ́ èémí tó péye, àìyẹ ọmọ náà wò lẹ́yìn tí wọ́n kùn ún lóorun àti àìtẹ̀lé ìlànà gbígbé aláìsàn láti yàrá kan lọ òmíràn.
Bákan náà ni wọ́n bèèrè fún àrídájú pé ilé ìwòsàn náà ni ohun èlò tó péye fún ìtọ́jú ọmọ náà àti ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àwọn dọ́kítà wọn.
Ko tán síbẹ̀ o, wọ́n ní ilé ìwòsàn Euracare kò ṣe àlàyé fún àwọn òbí ọmọ náà pé propofol ni wọn yóò lò fún ọmọ wọn àti àwọn ohun tó le ti ẹ̀yìn rẹ̀ yọ kí wọ́n t́ mú wọn tọwọ́ bọ̀wé ní èyí tó já sí pé wọ́n rú òfin ìfọwọ́sí olùtọ́jú aláìsàn.
Gbogbo èyí ni wọ́n fi pinnu pé ìwà àìbìkítà gbáà ni wọ́n fi pa ọmọ Chimamanda Adichie nílé ìwòsàn wọn.
Àwọn agbẹjọ́rò yìí bèèrè fún ìwé ẹ̀rí àwọn dọ́kítà àti nọ́ọ̀sì tó ṣe ìtọ́jú Nkanu Nnamdi láàrín ọjọ́ méje òní. Wọ́n sì tún bèèrè fún ìwé ẹ̀rí tí wọ́n fi darapọ̀ mọ́ àjọ dọ́kítà àti olùtọ́jú, ìwé àkọsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀.
Wọ́n ṣe ìkìlọ̀ fún ilé ìwòsàn Euracare pé kí wọn ó má ṣe danbaru gbogbo ohun tó le jẹ́ ẹ̀rí lórí ikú ọmọ náà, láti orí ẹ̀rọ akáwòránsílẹ̀ ilé ìwòsàn náà tó fi dé orí ìwé àkọsílẹ̀ wọn àti ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà tí wọ́n ń lò. Wọ́n ní bí àwọn bá rí ipa pé wọ́n fi ohunkóhùn bò, wọn yóò fi ojú winá òfin.
Kíkùnà láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bèèrè fún yìí yóò mú kí wọn ó lo gbogbo ohun tó wà ní ìkápá wọn láti fi ẹsẹ̀ òfin tọ ìṣẹ̀lẹ̀ náà kí wọn ó sì ríi dájú pé òfin fi ẹsẹ̀ múlẹ̀.
Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀:
Gbajúgbajà òǹkọ̀wé Chimamanda Ngozi Adichie ti fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn Euracare tó wá ní Èkó pé wọ́n fi àìbìkítà wọn gba ẹ̀mí ọmọ rẹ̀, ọmọ kékéré tó ń lọ pé ọdún méjì.
Ngozi ṣe àlàyé pé àwọn wá ṣe ọdún kérésì ní Èkó ni ọmọ náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nkanu bẹ̀rẹ̀ àìsàn, wọ́n kọ́ rò pé otútù ni àmọ́ àyẹ̀wò nílé ìwòsàn fi hàn pé àwọn kòkòrò àìfojúrí ló fà á, wọ́n ṣètò àti gbé e lọ sí orílẹ̀-ède United Kingdom fún ìtọ́jú, gbogbo ètò ti tò àmọ́ àwọn dọ́kítà lọ́hùn-ún bèèrè fún àwọn àyẹ̀wò kan kí ó tó lọ sí ọ̀hún.
Ó ku ọ̀la tó máa lọ sí UK ni wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn Euracare fún àwọn àyẹ̀wò ara náà. Àyẹ̀wò náà gba kí ọmọ náà ó wọ inú ẹ̀rọ wọn kò sì fẹ́ kí ó mira, wọ́n sọ fún ìyá rẹ̀ pé àwọn yóò pa iyè Nkanu ní ráńpẹ́ kí ó má baà mira nínú ẹ̀rọ náà, nígbà tó yá ni dọ́kítà gbé e ní pàjáwìrì lọ sí ẹ̀ka pàjáwìrì tí àwọn nọ́ọ̀sì sì ń sáré kiri, ìgbà náà ni Ngozi mọ̀ pé nǹkan ti yíwọ́.
Ngozi ní dọ́kítà tó kun ọmọ náà lóorun fún un ní àpọ̀jù òògun apaniníyè tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní propofol wọn kò tún yẹ ọmọ náà wò títí tó fi di pé èémí rẹ̀ lọ sílẹ̀.
Wọ́n de ẹ̀rọ ìmí mọ́ ọn nímú, wọ́n sì gbìyànjú àti jíi sáyé. Ọmọ náà jí sáyé padà ó sì nílò àti lọ sí yàrá pàjáwìrì. Ngozi ní dọ́kítà náà yọ ẹ̀rọ tí ọmọ náà fi ń mí ó sì gbé e lé èjìká láti yàrá iṣẹ́ abẹ lọ sí yàrá pàjáwìrì, nígbà tí yóò fi dé ibẹ̀, èémí rẹ̀ ti lọ sílẹ́ pátápátá, ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní sẹ́ gìrì ọkàn rẹ̀ sì da iṣẹ́ sílẹ̀. Bí ọmọ náà ṣe kú nìyẹn.
Ngozi Adichie fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn Euracare pé wọ́n fún ọmọ òun ní àpọ̀jù òògun propofol wọn kò sì tún yẹ ọmọ náà wò, nígbà tó tún jí sáyé, dọ́kítà náà tún yọ ẹ̀rọ èémí nímú rẹ̀ ó sì gbé e bẹ́ẹ̀ lọ sí yàrá pàjáwìrì. Ngozi ní ìwà ọ̀daràn gbáà ni dọ́kítà náà hù.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé àwọn èèyàn méjì ló ti fi ẹjọ́ sùn báyìí nípa dọ́kítà kan náà, wọ́n ní bí ó ṣe máa ń fún àwọn ọmọdé ní àpọ̀jù òògùn nìyẹn, kìí ṣe ti Nkanu làkọ́kọ́.
Ngozi bèèrè ìdí tí ilé ìwòsàn Euracare fi gbà á láàyè láti máa ṣiṣẹ́ lọ? Ó ṣe ìlèrí láti fa ẹjọ́ náà, ó ní òun yóò ríi dájú pé ọmọ mìíràn kò ṣe àgbákò dọ́kítà yìí




