Abúlé Zikke gbóná janjan lóru mọ́jú òní nígbà tí àwọn agbébọn bá wọn lálejò. Ìjọba ìbílẹ̀ Bassa ni abúlé Zikke wà ní Jos tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Plateau.
Òru ní nǹkan bíi aago méjìlá kọjá ni àwọn agbébọn náà dé sí abúlé Zikke lógúnlógún lọ́gbọ̀nlọ́gbọ̀n. Wọ́n yìnbọn lákọlákọ, wọ́n dáná sun ọ̀pọ̀ ilé, wọ́n pa àwọn èèyàn bíi ọgbọ̀n wọ́n sì tún ṣe ogúnlọ́gọ̀ báṣubàṣu.
Ó lé ní wákàtí kan tí wọ́n fi ṣe ọṣẹ́ yìí láìsí ìdíwọ́ kankan.
Olórí ọ̀dọ́ abúlé Zikke, ẹni tó jẹ́ akọ̀wé ẹgbẹ́ Irigwe; Joseph Chudu bá ikọ̀ àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó wí pé wọ́n ti kó àwọn tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Jos, ipò wọn burú wọ́n sì nílò ẹ̀jẹ̀.
Chudu rọ ìjọba láti ṣe àtúnṣe sí ètò ààbò tó mẹ́hẹ yìí. Gbogbo akitiyan láti kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Plateau kò so èso rere nípa pé agbẹnusọ wọn; Alabo Alfred kò gbé ìpè àwọn oníròyìn.
Ìkọlù yìí jẹ́ ọ̀tun lẹ́yìn gbogbo àwọn ìkọlù tó ti wáyé ní ìpínlẹ̀ Plateau lẹ́nu lọ́lọ́ yìí. Ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni wọ́n fẹ́rẹ̀ run gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ Bokko. Àádọ́ta èèyàn ni wọ́n pa lọ́sẹ̀ tó kọjá nìkan tí ọ̀pọ̀ dúkìá sì tún ṣòfò.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù tó ń wáyé sásá yìí ó sì rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò láti wá àwọn agbésùnmọ̀mí náà jáde.
Kọmíṣọ́nà fún ìfitónilétí; Joyce Renmap wí pé ìkọlù tó gba ìpínlẹ̀ Plateau kan yìí jẹ́ ohun tó bani lọ́kà jẹ́. Joyce wí pé ogúnlọ́gọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n pa ní ìjọba ìbílẹ̀ Bokko àti Bassa láàrín ọ̀sẹ̀ méjì yìí.
Ọ̀rọ̀ Joyce tẹ̀síwájú pé ìlú tó kún fún ìfẹ́ àti àdùn tẹ́lẹ̀ ti parade di ibi tó kún fún ìkorò àti ìbànújẹ́ látàrí ìkọlù ojoojúmọ́ yìí. Ó gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí àwọn èèyàn ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti borí àdojúkọ yìí.
Ìkọlù àwọn agbésùnmọ̀mí kìí ṣe ìròyìn mọ́ ní ìlú wa, ojoojúmọ́ ni àwọn agbésunmọ̀mí ń ṣọ́ṣẹ́ láìfọ̀tápè.
Ìròyìn mìíràn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láàárọ̀ yìí ni ti ìwọ́de tí àwọn obìnrin ṣe ní ìpínlẹ̀ Rivers láti ṣègbè fún ìjọba ológun tó wà lóde ní ìpínlẹ̀ náà. A gbọ́ pé ‘Ogúnlọ́gọ̀ àwọn òbinrin ló tú yáyá tú yàyà jáde láti ṣe ìwọ́de ṣègbè fún ìjọba ológun tó wà lórí àlééfà ní ìpínlẹ̀ Rivers.
Aago mẹ́jọ àárọ̀ yìí ni a rí àwọn obìnrin náà tí wọ́n kóra jọ sí ìkóríta Garrison fún ìwọ́de náà. Oríṣìí àkọlé ló wà lọ́wọ́ wọn.
Wọ́n ń kọrin àtìlẹyìn fún apaṣẹ wàá; Admiral Ibot-Ete Ibas, wọ́n sì ń rìn lọ sí ilé ìjọba tó wà ní Portharcourt.
Ìwọ́de èyí ni ìwọ́de àtakò sí ìwọ́de tó wáyé lọ́sẹ̀ tó kọjá tí àwọn ikọ̀ kan fi lòdì sí ìjọba pàjáwìrì náà’
ìròyìn mìíràn tí òun náà ń jà ràìnràìn lórí ìtàkùn ayélujára ni ti ìbúgbàmù tó wáyé ní Ikeja, a gbọ́ pé ‘Isọ̀ kan tó wà ní òpópónà Kodesho ní Ikeja, Computer ló gbaná ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ẹtì.
Àwọn ẹ̀rọ akáwòránsílẹ̀ ni wọ́n ń tà ní ìsọ̀ yìí, nǹkan bíi aago méje ìrọ̀lẹ́ ń lọ lù ni ìbúgbàmù náà wáyé. Àwọn márùn-ún ló farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ọ̀kan nínú wọn ti dágbére fáyé.
Benjamin Hundeyin; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ṣe àlàyé pé àwọn ta mọ́ra dé ibẹ̀ lójú ẹsẹ̀ tí àwọn gba ìpè náà, wọ́n gbé àwọn márùn-ún to farapa náà lọ sí ilé ìwòsàn ìkọ́ṣẹ́-òògùn-òyìbó tó wà ní Ikeja.
Wọ́n ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tó ṣe okùnfà ìbúgbàmù náà’
Ṣé ẹ gbọ ti akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé Obafemi Awolowo tó dágbére fáyé? Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé ‘Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo tó wà ní Ilé-Ifẹ̀ dèrò ọ̀run nígbà tó dìrọ̀ mọ́ ìgànná ilé tó ti ilé tó ń gbé.
Bọ́ọ̀lù ni akẹ́kọ̀ọ́ yìí (a kò ní ìyọ̀ǹda láti dárúkọ rẹ̀) lọ mú nínú ọgbà ilé kejì, ó sọ bọ́ọ̀lù náà síta fún àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀. Akẹ́kọ̀ọ́ yìí bá gun ìgànná ilé náà pé kó fò ó jáde láìmọ̀ pé àwọn wáyà iná kan ti wà lórí ìgànná náà. Wáyà yìí gbé akẹ́kọ̀ọ́ yìí níná ó sì ṣekú pa á.
Ẹnìkan tí ó jẹ́ alábàágbé rẹ̀ ló ṣe àlàyé pé ọjọ́ Ẹtì ni atẹ́gùn òjò já wáyà iná náà lórí òpó tó sì já àjákù rẹ̀ sí orí ìgànná náà kí ó tó di pé akẹ́kọ̀ọ́ yìí mú un gùn lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.
Nígbà tí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ ń gbá bọ́ọ̀lù rí i pé kò mira lórí ìgànná náà ni wọ́n fi igi ré e bọ́ sílẹ̀, wáyà náà lẹ̀ mọ́ ọn lára típẹ́típẹ̀ síbẹ̀, wọ́n fi igi já wáyà náà kúrò lára rẹ̀.
Wọ́n ṣe aájò rẹ̀ dé ilé ìwòsàn kan tó wá ní Ipetumodu àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́, eléérú ti sun igi fún akẹ́kọ̀ọ́ náà.
Alukoro fún ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo; Ọ̀gbẹ́ni Olanrewaju fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn.
Nínú àlàyé rẹ̀ la ti mọ̀ pé akẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé ìmúrasílẹ̀ àtiwọ ilé ìwé gíga Obafemi Awololo tí wọ́n ń pè ní CDL.
Ó wí pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà bani lọ́kàn jẹ́, ilé ìwòsàn àkọ́kọ́ wí pé ọmọ náà ti kú, ilé ìwòsàn kejì tí wọ́n gbé e lọ náà sọ pé ọmọ náà ti dágbére fáyé.
Wọ́n ti kàn sí àwọn òbí rẹ̀ láti fi tó wọn létí’
Èyí àti àwọn mìíràn ni ìròyìn tó gba ojú ewé kan láàárọ̀ yìí, ẹ má jìnnà sí ojú òpó wa. Ẹ ṣeun.
Discussion about this post