Àwọn agbébọn ṣọṣẹ́ ní Benue.
Kò dín ní èèyàn méjì tó kú nígbà tí àwọn agbébọn ya wọ agbègbè Okpafie ní ìjọba ìbílẹ̀ Okpokuní ìpínlẹ̀ Benue.
Wọn ba ilé jẹ́ wọ́n sì tún ba ọ̀nà jẹ́, wọn ṣe àwọn ará abúlé náà mọ́kumọ̀ku, ọ̀pọ̀ ló fara gbọgbẹ́ tí wọ́n sì tún kó màálù bíi ogójì lọ – Àwọn agbébọn ṣọṣẹ́ ní Benue.
Àwọn agbébọn náà tó méjìlá níye, ìbọn ńlá ńlá gbàǹgbà-gbàǹgbà ni wọ́n kó lọ́wọ́. Adah Inalegwu; ẹni tó jẹ́ alága ìjọba ìbílẹ̀ agbègbè náà ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé aago kan òru Ọjọ́bọ ni àwọn agbébọn náà ya wọ ìlú, wọ́n tó méjìlá níye, ilé bàbá kan tó ń sin ọ̀pọ̀ màálù ni wọ́n kọ́ yà sí.
Wọ́n ti wá ní ọ̀sán rí tí bàbá náà dá wọn lẹ́kun, ó kojú wọn wọ́n sì fi ẹsẹ̀ fẹ́ ẹ àmọ́ ní àsìkò yìí, òru ni wọ́n wá ká bàbá yìí mọ, ojú oorun ni wọ́n ti kìí mọ́lẹ̀ tí wọ́n sì pa á nípakúpa¬ – Àwọn agbébọn ṣọṣẹ́ ní Benue.
Ẹ̀yìn ìgbà náà ni wọ́n kó ogójì nínú àwọn màálù rẹ lọ. bákan náà ni wọ́n wọ àárín ìlú lọ ti wọ́n sì tún pa èèyàn kan síi tí ọ̀pọ̀ sì tún fara gbọgbẹ́.
Adah tẹ̀síwájú pé àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ti kán lugbó báyìí láti wá àwọn tó ṣiṣẹ́ láabi náà.
Ó ṣe ìrántí irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tó ti wáyé rí pé àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ wọn ló pàdé wọn lẹ́nu ìloro tí wọ́n sì dá wọn padà. Àwọn ẹṣọ́ yìí ti túká ni ó fún wọn ní ààyè lánàá àmọ́ ní báyìí, a ó tún kó wọn jọ padà – Adah Inalegwu.
Ọ̀rọ̀ Adah kò tán síbẹ̀ o, ó ṣe àlàyé síwájú síi pé àwọn agbébọn mẹ́ta tí àwọn mú sẹ́yìn ṣì wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá, ó ṣe é ṣe kí àwọn agbébọn yìí ó jẹ́ ọmọ ìlú Ezza- Igbo ní ìpínlẹ̀ Ebonyi.
Ìdí ni pé àwọn ẹni náà máa ń kọjá ní ààlà Ado, okpoku àti Ebonyi. Nígbà tí wọ́n sì tọpinpin ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọn, Ezza-Igbo ni ó ń tọ́ka sí.
Gbogbo akitiyan láti kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Benue kò tíì so èso rere lásìkò yìí.
Àwọn agbébọn ti fẹ́rẹ̀ jẹ ìlú run tán, ọjọ́ kejì tí wọ́n ṣọṣẹ́ ní Kastina ni wọ́n tún ya wọ Benue. Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló bá ìkọlù Katstina náà lọ.
Ìkọlù tó tún mìlú tìtì ni èyí tó wáyé ní Rukuba ní ìpínlẹ̀ Plateau, ìkọlù náà le tó bẹ́ẹ̀ tí ààrẹ fi ní láti ṣe àbẹ̀wò sí ìlú náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wọ àárín ìlú, pápákọ̀ òfurufú ni ó ti dúró nítorí kò sí iná ọba ní ìlú náà.
Báyìí ni ìròyìn Rukuba náà ṣe lọ:
Ìpínlẹ̀ Plateau ni Angwa Rukuba wà, ìgboro ni ìlú náà kìí ṣe abúlé ó sì kún fọ́fọ́. Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n ni àwọn agbébọn náà ya wọ ìlú náà pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀kadà, wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀ wọ́n sì kó àwọn èèyàn náà ní pápámọ́ra. Gbogbo ẹni tí wọ́n rí ni wọ́n yìnbọn mọ́, wọn kò mọ ọmọdé tàbí àgbà, kòsàkòsà ni ìbọn ń dáhùn lára gbogbo ẹni tí wọ́n ká mọ́.
Ọ̀kan nínú àwọn olùgbé Angwa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Caleb bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ó ṣe àlàyé pé ìkọlù náà kọjá bẹ́ẹ̀, èèyàn mẹ́fà ni wọ́n kọ́ mú balẹ̀ ní fọnná-fọnṣu tí ọ̀pọ̀ sì tún wà ní ilé ìwòsàn Luna ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run.
Janet Pam náà ṣe àlàyé pé inú ilé ni òun wà nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ ìró ìbọn, nígbà tó yọjú síta, àwọn agbébọn ló rí tí wọ́n ń yìnbọn lákọlákọ lórí ọ̀kadà.
Àwọn tí wọ́n ń lọ ní títì àti àwọn tó ń tajà ló fi ara gbọta jù, Janet ní wọ́n pa ará ilé òun kan tó ń ti ilé ìjọsìn bọ̀. Ìyàlẹ́nu ni èyí jẹ́, a kò rí irú èyí rí ní àdúgbò wa, wọ́n sá lọ kí àwọn ọlọ́pàá tó dé – Janet Pam.
Ìkọlù náà ti kó ìpayà bá àwọn ará ìlú, àwọn ọ̀dọ́ tú jáde láti ṣe ìwọ́de tako ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n bèèrè fún kí ìjọba ó fi òfin de alùpùpù ní gbogbo agbègbè náà, lẹ́yìn náà ni wọ́n gbégi dí ọ̀nà tó wọ ìlú náà àmọ́ àwọn ọlọ́pàá tú wọn ká.
Gómìnà Caleb Mutfwang bá àwọn ará agbègbè náà kẹ́dùn, ó ní òun mọ bí iná náà ṣe ń jó wọn lára tó nítorí pé ẹlẹ́ran ara ni òun náà.
Ó ṣe ìlérí pé ìṣèjọba òun yóò ṣe àwárí àwọn agbébọn náà wọn yóò sì fi imú wọn dánrin.
Bákan náà ni ìṣèjọba Mutfwang yóò san owó ìtọ́jú àwọn tó wà nílé ìwòsàn wọn yóò sì tún ṣe ètò ìsìnkú àwọn tó kú náà.
Caleb ní òun yóò ṣètò ìsìnkú ẹ̀yẹ fún àwọn tó kú náà láti fi ṣe àpọ́nlé ẹ̀mí wọn tó bọ́ láìtọ́jọ́.
Gómìnà Caleb rọ àwọn lọ́balọ́ba láti mú ètò ààbọ̀ lọ́kúnkúndùn kí wọn ó ṣètò ààbò tó péye fún agbègbè wọn.
Títí di àsìkò yìí, kò sí ìgbésẹ̀ kankan tó ti wáyé lẹ́yìn ìlérí tí wọ́n ṣe náà.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù tó ń wáyé sásá yìí ó sì rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò láti wá àwọn agbésùnmọ̀mí náà jáde.
Ojoojúmọ́ ni àwọn agbébọn fi ń ṣọṣẹ́ tí ìjọba sì ń ṣe ìlérí, ìgbà wo ni ìfẹ̀míṣòfò máa dópin ní orílẹ̀-èdè yìí?
