Àwọn agbébọn kan tí a kò tíì ṣe ìdámọ̀ wọn ya wọ ọjà ibùdó àwọn ológun tó wà ní Ojo, Èkó. Ìsọ̀ alápata náà ni wọ́n dorí kọ tí wọ́n sì yìnbọn pa á.
Ridwan ni orúkọ alápàta yìí, ẹran ló ń tà nínú ọjà náà. Nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́ ni àwọn agbébọn náà tí iye wọn tó mẹ́rin yaw ọ inú ọjà, wọ́n yìnbọn sókè tako! tako! ọ̀rọ̀ di bóòlọ-o-yàgò, àwọn ọlọ́jà náà sáré sọ́tùn-ún sósì, lẹ́yìn tí wọ́n tú ọjà ni wọ́n kọrí sí ìsọ̀ Ridwan tí wọ́n sì yìnbọn pa á.
Mummy Blesssing ṣe àlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí pé àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń pàtẹ ni àwọn agbébọn náà dé tí wọ́n fi aṣọ bojú, lẹ́yìn tí gbogbo wọn kán lu ìgbẹ́ ni wọ́n tọ Ridwan lọ, wọ́n yìnbọn fún un láìmọye ìgbà wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ́ẹ̀.
Àwọn ẹni náà ti súnmọ́ ìsọ̀ Ridwan dáadáa kí wọ́n tó yìnbọn, èyí ló fà á tí kò fi rọ́nà sá lọ.
Ilé ìwòsàn ológun kọ̀ ọ́ nígbà tí wọ́n dù ú dé ibẹ̀̀, kò dé ilé ìwòsàn kejì tó fi kú.
Àwọn ọlọ́pàá wí pé ìkọlù náà súnmọ́ ti ẹgbẹ́ òkùnkùn àmọ́ wọ́n ti sin òkú rẹ̀ nítorí pé Mùsùlùmí ni, èyí ló fà á tí ìwádìí ikú rẹ̀ ó fi wọ́lẹ̀ díẹ̀.
Ní ìpínlẹ̀ Kwara:
Ìyàwó ilé kan ti dákú nílé ẹjọ́ nígbà tí ọkọ rẹ̀ takú pé dandan àfi kí ìgbéyàwó náà túká.
Mulikat Yusuf ni orúkọ obìnrin yìí nígbà tí ọkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ishaq Abdulganiyu. Agbègbè Igboro ní ìpínlẹ̀ Kwara ni ilé wọn wà.
Ishaq fi àáké kọ́rí nílé ẹjọ́ pé òun kò fẹ́ Mulikat mọ́ kí adájọ́ ó tú ìgbéyàwó náà ká. Ó wí pé ìgbéyàwó náà ti sú òun, ìjà ni ní gbogbo ìgbà òun kò ṣe mọ́.
Tẹkún tẹkún ni Mulikat fi bẹ adájọ́ Toyin Aluko pé òun kò ṣe tán àti kọ ọkọ òun sílẹ̀, ó ní ọmọ mẹ́fà ni òun bí fún un kí adájọ́ ó bá òun bẹ̀ ẹ́.
Nígbà tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ jálẹ̀ ni ó múdìí lọlẹ̀ tó sì dákú gbọrangandan. Àwọn èrò ilé ẹjọ́ ṣe aájò rẹ̀, wọ́n rọ́ omi lé e lórí kó tó jí sáyé padà.
Adájọ́ Toyin Aluko rọ Mulikat láti lo gbogbo ọgbọ́n tó bá mọ̀ tó le fi fa ọkọ rẹ̀ mọ́ra padà, ó sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ kẹwàá, oṣù Ọ̀pẹ, ọdún 2025.
Mamuda pa ọlọ́kadà kó le rí owó fẹ́ ìyàwó kẹta.
MAMUDA GÚN ỌLỌ́KADÀ LỌ́BẸ, O TÚN GBÉ Ọ̀KADÀ RẸ̀ LỌ.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi ti tẹ ọmọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mamuda Zakari Yau lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn àti ìdigunjalè.
Àlàyé tí a rí gbà láti ẹnu alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ni pé Mamuda fẹ́ ṣe ìgbéyàwó ó sì nílò owó fún ètò ìgbéyàwó náà. Èyí ló mú un lọ dá Zango Saidawa; ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n lọ́nà, ó gún un lọ́bẹ pa ó sì gbé ọ̀kadà rẹ̀ sá lọ.
Mamuda jẹ́wọ́ pé òun gún Zango lọ́bẹ lóòótọ́ àmọ́ òun kò lérò láti pa á, ó ní òun ṣe èyí láti rí owó fẹ́ ìyàwó kẹta.
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ragina Daniels?
Ned Nwoko; ọkọ òṣèrébìnrin nnì Regina Daniels ti ṣe àlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ láàrin òun àti ìyàwó rẹ̀ pé ojú lásán kọ́ ni Regina fi ń ṣe gbogbo ohun tí ó ń ṣe náà, àpọ̀jù òògùn olóró ló ń dà á láàmú.
Àlàyé yìí jáde lẹ́yìn fọ́nrán tó jáde nínú èyí tí a ti rí Regina tó ń fọ́ àwọn gíláàsì ọkọ̀ tó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́.
Ned ṣe àlàyé pé oníwà tútù bíi àdàbà ni Regina tẹ́lẹ̀ kó tó di pé òògùn olóró pa á dà sí oníjàgídíjàgan.
‘Ó di dandan kí Regina ó padà sí ilé ìtọ́jú ìràpadà bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó léwu fún òun fúnra rẹ̀.
Regina gbá etí àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́ta, ó ba ọkọ̀ àti àwọn ohun olówó iyebíye jẹ́ láì nídìí.
Ọ̀rọ̀ náà kò bá má burú tó bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ òun nìkan àmọ́ àwọn tí wọ́n ń ta òògùn olóró náà fún un tó wá síbẹ̀ ló jẹ́ kó burú jù, ọ̀kan lára wọn ni Ann.’ Èyí ni ohun tí Ned kọ sí ojú òpó X rẹ̀.
Blessing ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí:
ỌWỌ́ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TẸ IKỌ̀ AFỌMỌṢÒWÒ NÍ ÌPÍNLẸ̀ RIVERS.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ ikọ̀ afọmọṣòwò kan ní ìpínlẹ̀ Rivers, ohun tí wọ́n máa ń ṣe náà ni pé wọn yóò rọ àwọn ọmọdé tó bá róyún he àti àti aláboyún tí wọn kò ní olùrànlọ́wọ́ láti ta ọmọ náà fún wọn.
Blessing Jack ni olórí ikọ̀ yìí, ó ti ṣe ẹ̀wọ̀n ní ìpínlẹ̀ Cross-River lórí ẹ̀sùn kan náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers ni ó sọ èyí di mímọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Grace Iringe-Koko pé àwọn mú Blessing; ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́ta ní ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù kẹwàá, ní Igwuruta nítòsí Port Harcourt lẹ́yìn ìtanilólobó àwọn tó fura síi.
Mímú tí wọ́n mú Blessing ni àwọn ọlọ́pàá fi tọpinpin àwọn mẹ́ta tó jẹ́ ẹmẹ̀wàá rẹ̀, ọ̀pọ̀ ọmọ ọwọ́ ni wọ́n bá ní ibùdó wọn nígbà tí wọ́n ya bò wọ́n.
Bákan náà nip é Blessing ń ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú dọ́kítà ọkùnrin kan tí yóò fi ayédèrú àwòrán oyún tan àwọn aláboyún ilé ìwòsàn rẹ̀ pé ọmọ inú wọn kò dá pé, lẹ́yìn tí wọ́n bá bímọ tán ni yóò wí fún wọn pé ọmọ náà ti kú tí yóò sì tà á ní mílíọ́nù méjì fún Blessing.
Ọdún mẹ́ta ni Blessing ti lò lẹ́wọ̀n lórí ọ̀ràn yìí ní ìpínlẹ̀ Cross-River, bó ṣe jáde lẹ́wọ̀n ló tẹ̀síwájú ní ìpínlẹ̀ Rivers.




