Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers mẹ́rìndínlógún ti yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ ilé náà; Martin Amaewhule ló ṣáájú ìṣípòpadà náà, ó wí pé ìdí tí àwọn fi kọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ ni pé ẹgbẹ́ náà ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, kò sí ìṣọ̀kan mọ́, gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ ti fọ́n ká bí iná alẹ́, ẹgbẹ́ náà kò ní àfojúsùn fún ọjọ́ ọ̀la.
Ó ní òun ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC òun sì ti fi tó alága ẹ̀kun òun létí.
Ọ̀rọ̀ Martin tẹ̀síwájú pé inú òun dùn láti jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, òun yóò fi ọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ààrẹ Bola Ahmed Tinubu láti mú ìdàgbàsókè bá Nàìjíríà.
Kò sí ẹni tí kò ní wù láti bá ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ṣe nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-ède Nàìjíríà dọ́kàn ó sì fi ìfẹ́ hàn sí ìpínlẹ̀ Rivers.
Èyí kò yẹ kó jọ wá lójú nítorí pé tilétilé ni gómìnà ìpínlẹ̀ Delta náà lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC:
Gọ́mìnà ìpínlẹ̀ Delta; Sheriff Oborevwori ti kéde ìṣípòpadà rẹ̀ láti jíjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kìí ṣe Sheriff nìkan ló yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, bí ìgbín bá fà ni ó fi ọ̀rọ̀ náà ṣe, Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta tẹ́lẹ̀rí; Ifeanyi Okowa àti gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Delta tó fi dé orí alága ìjọba ìbílẹ̀ ni wọ́n ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC báyìí.
Ìkéde yìí wáyé ní Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtalélógún, oṣù Igbe ní Asaba tíí ṣe olú ìlú Delta. Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà nnì; James Manager ló fi ìkéde yìí síta lẹ́yìn ìpàdé oníwákàtí mẹ́fà tó wáyé ní ilé ìjọba tó wà ní Asaba.
Aṣòfin James wí pé gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Delta pátá ló ti gbà láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Tó fi dé orí agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ pátá tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, gbogbo wọn ló ti digbá dagbọ̀n wọn báyìí láti ré kété sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kọmiṣọ́nà fún ìfitónilétí ní ìpínlẹ̀ Delta; Ọ̀gbẹ́ni Aniagwu Charles náà sọ̀rọ̀ lórí ìṣípòpadà yìí, ó wí pé àwọn kò le wà nínú ọkọ̀ tó ti rì, ó di dandan kí àwọn ó ṣe àtúnṣe sí ètò ìṣejọba àwọn ní èyí tó gba kí àwọn ó ṣe ìpinnu tó nípọn bẹ́ẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Charles wí pé ìpinnu yìí yóò jẹ́ kí iṣẹ́ rere ó le tẹ̀síwájú ní ìpínlẹ̀ Delta. Dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC yóò mú kí ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ó dé bá ìpínlẹ̀ Delta, ìgbé ayé àwọn ará Delta yóò di ọ̀tun, ìpínlẹ̀ Delta ó wá di ìpínlẹ̀ tí yóò ṣe máa mú yangàn láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Charles tẹ̀síwájú pé àwọn aṣáájú ló ṣe ìpinnu náà, ó sì di dandan kí gbogbo àwọn ìsọmọgbè ó tẹ̀lé e nítorí pé ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Delta ló jẹ gbogbo àwọn lógún.
Ọjọ́ Ajé tó ń bọ̀ yìí ni gbogbo wọn ó di ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lógidi. Kí a máa retí ìsọdọ̀tun ní ìpínlẹ̀ Delta ló kù báyìí.
Gbogbo àwọn olóṣèlú yìí ló ń gbé oríyìn fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu bí ìgbà pé inú ìlú kọ́ ni gbogbo wa jọ ń gbé. Yahaya Bello tilẹ̀ fi Tinubu wé áńgẹ́lì:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi tẹ́lẹ̀rí; Yahaya Bello ti ṣe àpèjúwe ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bíi áńgẹ́lì tí Ọlọ́run rán láti tún Nàìjíríà ṣe.
Yahaya sọ èyí lórí ìkànnì ẹ̀rọ amóhùmáwòrán pé bí a bá ń retí kí Ọlọ́run ó sọ áńgẹ́lì kalẹ̀ láti ojú ọ̀run kí ó sì fi ìyẹ́ fò wọ Nàìjíríà, a ó dúró pẹ́ nítorí pé Ọlọ́run ti sọ áńgẹ́lì náà kalẹ̀ fún wa tipẹ́ àwa la ò kíyèsí. Ta ni áńgẹ́́lì náà? Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu ni áńgẹ́lì tí Ọlọ́run sọ̀ kalẹ̀ láti tún orílẹ̀-èdè yìí ṣe.
Ó ti pẹ́ tí a ti ń retí olùgbalà tí yóò tún Naìjíríà ṣe, áńgẹ́lì wo ló tún ju Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lọ? Ó yọ owó ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù, ó ṣètò èyáwó kàwé, ó ṣe àtúntò ẹ̀sẹ́wó owó òkèrè, ó ṣe àwọn òfin tó pawó wọlé sápò ìjọba àti aráàlú, ẹni tó bá ń retí iṣẹ́ ìyanu nìkan ni yóò sọ pé Tinubu kò ṣe tó, ààrẹ kan ò tún gbọdọ̀ ṣe ju báyìí lọ.
Ṣáájú ọdún 2015 ni a ti ń bèèrè fún Nàìjíríà titun ní èyí tí ayé ó dẹ gbogbo èèyàn lọ́rùn, gbogbo ohun tí a ń fẹ́ náà ni ààrẹ ń ṣe lọ́kọ̀ọ̀kan, ẹ kò le retí kí ó ṣe gbogbo rẹ̀ tán lẹ́ẹ̀kan náà nítorí pé ìlú ti bàjẹ́ jìnnà kí Tinubu ó tó gba ìjọba.
Èmi yóò maáa ṣe àtìlẹyìn fún ààrẹ Tinubu nítèmi nítorí pé mom ọ rírì iṣẹ́ tó ń ṣe, kò ṣe é ṣe fún ààrẹ láti ṣe gbogbo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà mo sì nírètí pé yóò ṣe gbogbo rẹ̀ pátá bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́.
Ohun tí a ń fẹ́ lọ́jó¸iwájú ni pé nígbà tí ààrẹ ó bá fi parí ìṣejọba ẹlẹ́ẹ̀kejì, yóò fi àwọn ọmọlẹ́yìn rere lélẹ̀ tí yóò máa tọ ipasẹ̀ ààrẹ tí wọn yóò sì má atẹ̀lé ìlànà ìṣejọba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ní èyí tí yóò jẹ́ pé irú àwọn èèyàn rere bíi èmi àti àwọn mìíràn tó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-ède Nàìjíríà dénú ni yóò má abọ́ sípò ààrẹ.
Lọ́jọ́ tònìí, inú mi dùn pé mo jẹ́ ọmọlẹ́yìn Tinubu, ayọ mi kún, bí ẹ bá sì wo ìṣejọba mi nígbà tí mo wà nípò, ẹ ó ríi pé àwọn iṣẹ́ rere tí mo ṣe ń tọ̀ mí lẹ́yìn – èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Yahaya Bello sọ.


