Àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti bọ́ sóde láti wá awakọ̀ kan tó gbá àwọn ọmọ́débìnrin méjì tí wọ́n ń ti ilé ìwé bọ̀ lánàá 24/02/2025.
Ọmọ odún mẹ́ẹ̀dógún àti méjìlá ni àwọn ọmọ yìí, wọ́n jáde ilé ìwé, wọ́n ń darí lọ ilé, ìgbà tí wọ́n dé ìbùdókọ̀ Ogundare ní Abeokuta ni ọkọ̀ gbá àwọn méjéèjì nígbàákúgbàá.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko; Benjamin Hundeyin ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé àwọn ń wá awakọ̀ kan tó gbá ọmọ ìyá méjì ní ibùdókọ̀ Ogundare. Benjamin ṣe àlàyé pé àwọn ọmọ méjéèjì yìí dúró sí òpópọnà tí a yà sọ́tọ̀ fún ọkọ̀ akérò ìjọba Eko; BRT, ṣàdédé ni awakọ̀ yìí ń sáré àsápajúdé bọ̀, ó kọlu àwọn ọmọ obìnrin méjéèjì yìí ó sì sá lọ.
Àwọn èèyàn ṣe aájò àwọn ọmọ yìí dé ilé ìwòsàn, èyí àbúrò; ọmọ ọdún méjìlá gbé ẹ̀mí mìn nílé ìwòsàn, ẹ̀gbọ́n ti wà ní ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó Èkó; LASUTH nítorí pé ipò tó wà kọjá agbára ilé ìwòsàn aládàáni tí wọ́n kọ́kọ́ gbé wọn lọ.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Olohundare Jimoh banu jẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí , ó bá òbí àwọn ọmọ náà dárò ó sì kàn án nípá fún àwọn ọlọ́pàá láti wá awakọ̀ náà jáde ní gbogbo ihò tó bá wù kó sá wọ̀.
Ọ̀gbéni Olohundare rọ àwọn awakọ̀ láti máa tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ lójú pópó.
**** ***** ***** ***** **** **** **** **** ***** ***** ***** **** ***** **** **** **** ***** **** ****** **** *** ***** *** ******* ***** ***** **** *****
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí awakọ̀ máa sáré àsápajúde fi tirẹ̀ kó bá ẹlòmíràn. Nínú ọdún yìí nìkan, ilé iṣẹ́ Ìwé ìròyìn Yorùbá ti kọ nípa àwọn ìjàm̀bá ọkọ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ látàrí eré àsápajúdé.
Nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn ní ọjọ́ kẹrin oṣù yìí, nǹkan yan; ọkùnrin kan gbé ẹ̀mí mìn nígbà tí àwọn èèyàn márùndínlógún mìíràn farapa yánnayànna. ọkọ̀ náà rún wómúwómú ni, ó kọjá bẹ́ẹ̀, bí èèyàn bá jẹ orí ahun gan-an yóò kérora abiyamọ.
Ọkọ̀ Mazda kan ló pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì lọ forí sọ ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan tó jáde láti inú ọgbà ilé iṣẹ́ aládàáni kan tó wà ní ojú ọnà náà.
Èèyàn mẹ́rìndínlógún ló wà nínú ọkọ̀ Mazda yìí. Àwọn èèyàn ṣe aájò wọn dé ilé ìwòsàn àmọ́ eléérú sungi fún ẹni kan nínú wọn kí awon dọ́kítà tó tẹ́wọ́ gbà á rárá.
Ẹnìkan tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣàlàyé pé ọkọ̀ àjàgbé eléjò ti ilé iṣẹ́ AIM Coy jáde láti inú ọgbà ilé iṣẹ́ náà ní tirẹ̀ kó tó di pé ọkọ̀ Mazda náà sá eré àsápajúdé pàdé rẹ̀ lójijì.
Adarí àjọ ààbò ojú pópó ìpínlẹ̀ Ogun; ọ̀gbẹ́ni Seni Ogunyemi fìdìí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ pé ó bani lọ́kàn jẹ́ gan-an ni.
Ogunyemi wí pé àwọn ti gbé òkú arákùnrin tó kú náà sí ilé ìgbókùúsí ilé ìwòsàn Livewell tó wà ní Shagamu. Ilé ìwòsàn Livewell yìí kan náà ni àwọn mẹ́ẹ̀dógún yòókù ti ń gba ìtọ́jú.
Nínú ọ̀sẹ̀ tó ṣaajú ìṣẹ̀lẹ̀ ti ọkọ̀ Mazda yìí, ìjàm̀bá ọkọ̀ méjì ló wáyé lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn yìí kan náà.
Ọkọ̀ Toyota kan tó kó èèyàn méje láti ìpínlẹ̀ Osun wá sí Èkó pàdánù ìjánu rẹ̀ ó sì kó sí abẹ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan tó ń lọ ní tirẹ̀.
Aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ni ìjàmbá yìí wáyé lọ́jọ́ àìkú ọ̀sẹ̀ náà.
Ọ̀gbẹ́ni Sanni Saifullahi ló wa ọkọ̀ àjàgbé eléjò náà, ọkọ̀ àjàgbé yìí ga tó ìwọ̀n ogójì ẹsẹ̀ bàtà, ilé iṣẹ́ Ay and Rolly’s ventures tó wà ní Magodo, ìpínlẹ̀ Èkó ló ni ọkọ̀ àjàgbé yìí.
Ọgbẹ́ni Sunday Okpe ti ilé iṣẹ́ Miracle Ultima international limited ló wa ọkọ̀ Sienna yìí.
Ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ni ọ̀gbẹ́ni Sunday ti gbéra pẹ̀lú èrò méje, ojú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn ní ìta Olúwo, Ìkòròdú ni ọkọ̀ yìí ti pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì kó sí abẹ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò náà.
Arábìnrin Miracle Chibuzor tí òun náà jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ Miracle Ultima international limited ló jókòó níwájú, ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbá yìí, àwọn èèyàn márùn-ún mìíràn fara pa yánnayànna.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Omolola Odutola ló fi ọ̀rọ̀ yìí ṣọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn pé arábìnrin Miracle pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní ojú ọnà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn.
Àwọn ọlọ́pàá ojú pópó ló kó àwọn márùn-ún tí wọ́n farapa náà lọ sí ilé ìwòsàn Falobis tó wà ní Mowe fún ìtọ́jú.
Wọ́n gbé òkú arábìnrin Miracle lọ sí ilé ìgbókùúsí Idera fún àyẹ̀wò àti ìwé ẹ̀rí.
Lẹ́yìn náà ni àwọn ọlọ́pàá wọ́ àwọn ọkọ̀ méjèèjì náà lọ sí àgọ́ wọn tó wà ní Shagamu kí àwọn òṣìṣẹ́ VIO le ṣe àyẹ̀wò rẹ̀.
Eré àsápajúdé náà ló fa ìjàm̀bá ọkọ̀ Toyota Highlander kan nígbà tó pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ní ojú ọnà márosẹ̀ Lekki-Epe lọ́sàn-án gangan.
Awakọ̀ yìí pàdánù ìjánu rẹ̀ ó sì lọ kọlu ọkọ̀ àjàgbé kan tó ń lọ sí Epe, ọkọ̀ Toyota náà gbaná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tó kọlu àjàgbé náà, gbogbo akitiyan láti dóòlà ẹ̀mí awakọ̀ yìí kò yọrí sí rere.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì; Adebayo Taofiq ló fi ọ̀rọ̀ náà léde pé àwọn gbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí arákùnrin tó wa ọkọ̀ náà àmọ́ ó ti kú kí wọn ó tó ríi yọ wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ fún àwọn ẹbí rẹ̀. Àjọ LASTMA gba àwọn awakọ̀ níyànjú láti ṣe pẹ̀lẹ́.
Ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ìgbòkègbodò ọkọ̀ Èkó: LASTMA sọ nígbà kan rí pé ìdá àádọ́rùn-ún àwọn ìjám̀bá ọkọ̀ tó ti wáyé jẹ́ àfọwọ́fà awakọ̀.Wọ́n rọ àwọn awakọ̀ láti yẹra fún eré asápajúde adẹ́mìílégbodò tó ń fojoójúmọ́ pa àwọn èèyàn lẹ́kún yìí.