Gbogbo àgbáríjọ àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Yorùbá tí a mọ̀ sí “ Congress of Yorùbá Leaders” ti bu ẹnu àtẹ́ àti àbùkù lu gómìnà tẹ́lẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun, Olóyè Adegboyega Oyetọ́lá àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ fún ṣíṣe àtìlẹ́yìn fún kò-bà-ò-lè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun lérò pé yóò jẹ́ ọ̀nà látigba ìṣàkóso ìjọba ìpínlè Ọ̀ṣun.
Àwọn ẹgbẹ́ náà fi ojú láìfí wo rògbòdìyàn náà tó bẹ́ sílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun lọ́jọ́ Ajé tó kọjá yìí tó sì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí lọ. Wọ́n ní àwọn eku ẹdá tó dá èyí sílè ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ alátakò APC èyí tí Oyetọ́lá kó sòdí.
Àwọn aṣáájú ilẹ̀ Yorùbá ṣàpèjúwe èyí gẹ́gẹ́ bí ìwà ipá àti ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti ba ìjọba tí ará ìlú dìbò yàn ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun jẹ́. Akọ̀wé ìpolongo àpéjọpọ̀ àwọn àgbà náà; Ọmọ ọba Abiodun Ọlámidé ló sọ bẹ́ẹ̀ nínú Ìròyìn tó fọwọ́ sí.
Ikọ̀ náà tún bu ẹnu àtẹ́ lu ìpè ìjọba pàjáwìrì ní ìpínlè Ọ̀ṣun tí àwọn igun tí Oyetọ́lá ń pè. Wọ́n ní ìsọkúsọ àti ìṣekúṣe gbáà ni, èyí tó sì lè fa àìbàlẹ̀ ọkàn fáráàlú. Apėjọ àwọn așáájú yìí wáá rọ Ààrẹ Tinubu láti gbé ìgbésẹ̀ kánkán lòdì sí Oyetọ́lá àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti bàa pinwọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú mìíràn.
Nínú àlàyé wọn, àwọn àpèjọ àgbààgbà yìí ní láìsí àní-àní àwọn rí Ọ̀gbẹ́ni Oyetọ́lá àti ikọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Ọ̀gbẹ́ni Ajíbọ́lá Bashir tí í ṣe akọ̀wé àpapọ̀ ẹgbẹ́ APC nílẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀dádá tó dá wàhálà ọjọ́ Ajé sílẹ̀ . Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀dá yìí kéré níye nínú ètò ìṣèlú ìjọba ipinlẹ̀ Ọ̀ṣun, síbẹ̀ wón là kàkà láti dabarú ìjọba tárá ìlú dìbò yàn. Ìpè tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń pè fún ìjọba pàjáwìrì jẹ́ ohun tó burú jáì tí ò ṣeé gbọ́ sétí, tó sì jẹ́ ọ̀nà láti fọ́ nnkan lójú pọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀șun.
Àwọn àgbà má-jẹ̀ẹ́-ó-bàjẹ́ yìí káàánú lórí àwọn ẹ̀mí tó ti ṣòfò. Wọ́n yòǹbó ipa tí àwọn agbófinró kó. Wọ́n sì pe Ààrẹ Tinubu pé kó pe Oyetọ́lá, kó sì kìlọ̀ fún un pé kó tẹ ọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọṣọ. Wọ́n ní kò yẹ kí ìjọba àpapọ̀ fààyè gba àwọn olóṣèlú kan láti dabarú ètò ìṣèjọba Ìpínlẹ̀ tó ti ní àlàáfíà.
Wọ́n sì tún rọ àwọn ará ìlú pé kí wọ́n máa báṣẹ́ wọn lọ láìsí ìfòyà àti ìbẹ̀rù. Wọ́n sì ní àwọ́n rí ipa tí Oyetọ́lá, Ajíbọ́lá àti àwọn ọmọ Ogun eégún alákìísà wọn ń kó láti dá kò-bà-ò-le sílẹ̀. Ṣùgbọ́n kí àwọn aráàlú máa lọ ìlọ tiwọn lálàáfíà.
Àná ọjọ́ ni gbogbo rògbòdìyàn yìí bẹ̀rẹ̀ ní èyí tó mú ẹ̀mí dání.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn agbébọn tó da nǹkan bojú rọ́ wọ àgbègbè ìjọba òkè baálẹ̀ ní Òṣogbo nígbà tí ẹgbẹ́ APC àti PDP ń bá ara wọn fà á lórí ẹni tí yóò gba ìṣàkóso sẹkitéríàtì ìjọba ìbílẹ̀ náà. Ẹnìkán tilẹ̀ ti fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀ ó sì tún ń bá adàlúrú mìíràn wọ̀yá ìjà. Ní àkókò tí ìró ìbọn ń dún tùkẹ-tùkẹ̀, òpópónà ibi tí ọ́fíìsì ìjọba ìbílẹ̀ náà wà dá páropáro ni.
Àwọn agbófinró tó di ìhámọ́ra gbágbá wà níbi àbáwọlé inú ọgbà ilé ìjọba ìbílẹ̀ yìí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn jàǹdùkú tó ń yìnbọn yìí ń yìn ín léjìdà-léjìdà, tí ìbẹ̀rù-bojo àti ìpayà sì mú àwọn aráàlú.
Ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìwọ̀-oòrùn Àtàkúnmọ̀sà, Ọlọ́lá Festus Kọ́mọláfẹ́ tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun náà kó àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lẹ́hìn wá sí gbàgede ìjọba náà ; àmọ́ wọn ò dúró pẹ́ tí wọ́n fi kó rẹirẹi wọn kúrò níbẹ̀.
Ní Ẹgbẹ́dọ̀rẹ́, tí ibùjókòó wọn wà ní Awó, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP tí wọ́n kó ọrẹ́ lọ́wọ́ yááyáá ni wọ́n rí tí wọ́n ń pàráàro, tí wọ́n sì ń ké lé àwọn ti APC lórí pé ẹní bá láyà kó wáá wọ̀ ọ́, kó wá rídán.
Bákan náà lọmọ́ sorí ní Ayédaadé, Bórípẹ́ ní Ìrágbìjí níbi tí àwọn APC ti wọnú sẹkitéríàtì ní Ìrágbìjí. Àmọ́ kò rọrùn fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC láti inú sẹkitéríàtì ti ìjọba ijoba Ọlọ́rundá ní Ìgbọ̀nà, Òṣogbo.
*** *** *** *** *** *** *** *** *** **
ÈRÒ TIWA…..
A gbọ́n sẹ́, oyín sẹ́, àmọ́ ojú olóko rèé tó wú gùdùgbú-gùdùgbú yìí.
Ọ̀rọ̀ tó fa kò-bà-ò-lè tí ẹ̀mí fi ń șòfò ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun kò lè tó bẹ́ẹ̀ rárá. Àìfi ẹ̀lẹ̀ kébòsí ni ó fẹ́ẹ́ fi dá bí ẹni pé nǹkan fi di gbódó-ñ-ró ṣọ mọ́ àwọn olóṣèlú lọ́wọ́.
Ohun àkọ́kọ́ tí a kàn fẹ́ẹ́ sọ ni pé kí a bẹ àwọn olóṣèlú ilẹ̀ yìí kí wọ́n má ba ilẹ̀ yìí jẹ́. A sì ń fi yé wọn pé a yàn wón láti wáá ṣe ìjoba ni. Ará ìlú ló ní àṣẹ àti kùkùudà láti yan ẹni tó wù wọ́n láti wá bá wọn ṣe ìjọba wọn. Kì í ṣe oyè ìdílé ; kì í ṣe oyè àjẹwọ̀.
Lórí rògbòdìyàn tó ń lọ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun, lójú tiwa àti lérò tiwa, arí i pé ejò ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ nínú o. Ẹjọ̀ tí a dájọ́ ilé ẹjọ́ dá ló fa gbogbo wàhálà yìí nítorí ohun tó ti wà nínú àwọn olóṣèlú kan láti gbé ìgbésẹ̀ tí yóò fààyè sílẹ̀ láti mú kí wọ́n ṣe ìfẹ́ inú wọn.
Tí ó bá jẹ́ pé àwọn olóṣèlú wa fẹ́ ṣe ìlú kó gún ní tòótọ́, tí kì í bá ṣe ẹ̀mí ọ̀jẹ̀lú ló gbé wọn wọ̀, eegun òtòlò ló yẹ kí wón fi to ọ̀rọ̀ yìí láìsí kọ́núnkọ́họ kankan rárá. Ṣẹ ló yẹ kí àwọn méjèèjì Padà sílé ẹjọ́, kí wọn sì béèrè lọ́wọ́ adájọ́ pé kí wọ̀n yànnàná ẹjọ́ tí wọ́n dá lọ́nà tí yóò gbà fi yé tawo-tọ̀gbẹ̀rì.
Òótọ́ ọ̀rọ̀ kò ní ká má sọ òun, Òótọ́ ọ̀rọ̀ sì rèé bitakọ ìsọkúsọ ni. Gbogbo àwọn ẹgbẹ́ yìí kàn fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ máa pa làpálàpá tó dúró tiẹ̀ jẹ́ jẹ́ ni. Èyí tó tún dà bíi rẹ̀ ni ipa tí àwọn dájọ́ wá ń kó lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú nílẹ̀ yìí. Àwọn là á máa pè ní ‘Baba ékeé’ tàbí “tòtò abẹ́ igi” tí kì í dá ọ̀rọ̀ bójò bá ti rọ̀ tán.
Ó yẹ kí wón lè máa gbé ìdájọ́ wọn kalẹ̀ láìbo sí ẹ̀hìn ìka kan rárá. Tí aráàlú bá ti mọ ohun tí ìdájọ́ wọ́n sọ, kí wọn sì gbé ìdájọ́ náà kalè lásìkò tó wúlò, a ó mọ ibi tí ọ̀pá páńdọ̀rọ̀ fì sí, a ó sì tètè fi ojú așebi hànde.
Lákòótán a ń rọ àwọn àgbààgbà tó jẹ̀șẹ́bì pé kí wọ́n má dùúró di ìgbà tí gbogbo rẹ̀ máa bàjẹ́ tán kí wón tó ki ọwọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn bọṣọ.
Ẹ jẹ́ ká rántí Ogun “Wẹ́ẹ̀tiẹ̀” ọjọ́ sí nílẹ̀ Yorùbá. Irú bẹ́ẹ̀ ló tún ń kóra jọ báyìí ni Ipinle Ọ̀ṣun yìí. Ojú alákàn fi ń ṣọ́ orí o. Ẹ má jẹ̀ẹ́ ká ja ìjà ẹ̀bi o. Ẹ ṣàánú mẹ̀kúnnù nilẹ̀ yìí o, ” ìn a jèrè; ọní jẹ gbìì, é ni í kú gbìì ó”