Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ lójú pópó, FRSC ; Sheu Muhammad ti sọ ohun tó le mú kí iṣẹ́ wọn ó rọrùn, ó wí pé kò sí bí àwọn ṣe le gbádùn iṣẹ́ àwọn bikòṣe pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́.
Lórí ìkànnì ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán Arise ni Muhammad ti ṣe àlàyé ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù Ọwẹ́wẹ̀ yìí pé ó ṣe pàtàkì kí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú pópó ó máa lo ìbọn, ìdí ni pé àwọn awakọ̀ kìí dúró bí àwọn bá dá wọn dúró àmọ́ bí àwọn bá ní ìbọn lọ́wọ́, wọn yóò máa dúró.
Ó wí pé kò rọrùn fún àwọn láti dá ọkọ̀ àjàgbé eléjò dúró fún àyẹ̀wò pàápàá àwọn ọkọ̀ àjàgbé tí wọ́n kó ẹrù àti èrò, adojúkọ nlá ni àwọn ń kojú ni àwọn ń kojú láti dá àwọn ọkọ̀ yìí dúró àmọ́ ìlò ìbọn yóò mú kí ó rọrùn fún àwọn.
Ọ̀rọ̀ Muhammad tẹ̀síwájú pé ojú bọ̀rọ̀ kò ṣeé gba ọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́ ni ọ̀rọ̀ àwọn awakọ̀ ojú pópó náà, ọmọ iná sì ló yẹ kí àwọn ó rán síná.
Ọ̀gá àgbà FRSC tẹnu mọ́ ọn pé ìlò ìbọn nìkan ni yóò mú kí iṣẹ́ àwọn ó rọrùn.
Olóòtú bèèrè lọ́wọ́ Muhammad pé ṣé àwọn ẹ̀ṣọ́ yìí kò ní máa ṣi agbára lò bí ìbọn bá dé ọwọ́ wọn tán nítorí pé itú tí wọ́n ń pa láìní ìbọn gan-an kò kéré?
Muhammad dáhùn pé lóòótọ́ ni pé àwọn kan ń ṣìwà hù láàrin wọn àmọ́ àwọn máa ń fi ìyà tó tọ́ jẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ni àwọn ti yọ níṣẹ́ lórí ìfìyàjẹni àti àwọn ìwà mìíràn bẹ́ẹ̀.
Bákan náà ló wí pé àhesọ lásán ni pé àwọn ti ṣe àfikún iye owó tí wọ́n ń gba káàdì ìwakọ̀, Muhammad wí pé iye tí àwọn ń gbà láti ọdún mẹ́ẹ̀dógún sẹ́yìn náà ni àwọn ṣì ń gbà di ìsìn yìí.
Ìròyìn mìíràn tí a kò gbọdọ̀ má fi tóo yín létí ni ìròyìn ilé alájà méjì kan tó dà wó ní Mangoro, Èkó.
A gbọ́ pé:
Ilé alájà méjì kan tó wà ní agbègbè Modupeola, Mangoro ní ìpínlẹ̀ Èkó.
Nǹkan bíi aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Ọwẹ́wẹ̀ yìí ni ilé náà ṣàdédé dà wó lulẹ̀.
Kọ́míṣọ́nà fún ìfitónilétí; Gbenga Omotoso ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé àwọn òṣìṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ta mọ́ra dé ilé náà nígbà tí wọ́n gba ìpè pàjáwìrì náà.
Àwọn èèyàn márùn-ún ló há sí abẹ́ rẹ̀, mẹ́rin nínú wọn kò fara pa púpọ̀ nígbà tí ẹnìkan há pátápátá torítorí tó ṣe pé Olódùmarè kàn mọ̀ọ́nmọ̀ dá ẹ̀mí rẹ̀ sí ni.
Àwọn òṣìṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì NEMA kó àwọn mẹ́rin náà lọ sí ilé ìwòsàn aládàáni kan tó wà nítòsí nígbà tí wọ́n gbé ẹni tó fara pa lọ́pọ̀ náà lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Èkó.
Ipò rẹ̀ nílò iṣẹ́ abẹ pàjáwìrì, kíá náà sì ni wọ́n ti ṣe ètò rẹ̀.
Ẹni ọdún mẹ́rínlélógójì ni ọkùnrin yìí, òpópónà Olabode ní Alomosho ni ó ń gbé, ó gbéra kúrò nílé rẹ̀ lọ sí Mangoro níbi tó ti ṣe àgbákò ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Nígbà tí ilé Fatai Qadri kò dàwò, fúnra rẹ̀ ni ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ da ilé rẹ̀ rú tó sì gba ibẹ̀ dé ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Ohun tó ṣe náà ni pé ó lu ìyàwó ilé rẹ̀ nílùkulù.
Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Ilé ẹjọ́ ti pàṣẹ kí Fatai Qadri ó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n di ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Ọ̀wárà lórí ẹ̀sùn pé ó lu ìyàwó ilé rẹ̀ lálùbami.
Nínú fọ́nrán kan tó gba orí ìtàkùn ayélujára kan ni a ti rí Fatai tó ń kọ́ ẹ̀ṣẹ́ bo ìyàwó rẹ̀; Rukayat Qadri tó sì tún fi igi lù ú.
Rukayat gbìyànjú àti sá jáde nínú yàrá náà àmọ́ Fatai tún gbá tẹ̀lé e.
Àlàyé ìdí ìjà náà tí a ri gbà ni pé Fatai pàṣẹ fún ìyàwó rẹ̀ pé kò gbọdọ̀ dé orí ilé olójú mẹ́wàá tí òun ń kọ́ lọ́wọ́ náà mọ́ nítorí pé òun àti ìyàwó òun titun tí òun yóò fẹ́ ni àwọn yóò jọ gbé níbẹ̀.
Ilé ẹjọ́ fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Fatai ti yí orúkọ ìwé ilé náà sí ti ìyàwó rẹ̀ titun yìí.
Ẹ̀sùn oníkókó mẹ́ta ni ìjọba fi kan Fatai, nínú rẹ̀ ni pé ó ṣe ìpalára fún ìyàwó rẹ̀ ó sì da omi àlàáfíà ilé náà rú.
Ẹni àádọta ọdún ni Rukayat nígbà tí Fatai jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta. Ọmọ mẹ́ta ni Rukayat bí fún Fatai, méjì wà nílùú òyìnbó tí wọ́n sì ti fẹ́ ìyàwó, àbígbẹ̀yìn tó ń bá wọn gbé ni ó ká fọ́nrán náà tó sì fi léde.
Adájọ́ P.O Odunsi ti pàṣẹ pé kí wọn ó fi Fatai sí ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù tó ń bọ̀.
Ìròyìn tí a ó fi kásẹ̀ rẹ̀ náà ni ti akẹ́kọ̀ọ́ fafiti Èkó tó kú sínú odò.
Báyìí ni ìròyìn náà ṣe lọ:
Damilola Balogun; akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Èkó ti kú sínú odò ní Lekki.
Àlàyé tí a rí gbà nípa ikú rẹ̀ ni pé òun àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ lọ sí ibi ìgbafẹ́ etídò kan tó wà ní Ibeju-lekki nígbà tí odò gbé e lọ níbi tó ti ń ṣeré létí omi.
Damilola ni ààrẹ àṣẹ̀ṣẹ̀yàn ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé náà, òun àti àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀yàn bíi tiẹ̀ tẹ̀lé àwọn tó máa gbé ọ̀pá àṣẹ sílẹ̀ lọ ṣe ayẹyẹ ní ibi ìgbafẹ́ etídò náà lọ́jọ́rú, nígbà tó di ọjọ́ kejì, àwọn akẹgbẹ́ Damilola lọ àmọ́ òun àti àwọn méjì mìíràn nínú àwọn tó ń fipò sílẹ̀ dúró.
Ẹni tó ṣe àlàyé náà wí pé àwọn gbá bọ́ọ̀lù tán ni Damilola ní òun fẹ́ ṣeré létí omi kí òun ó sì máa ya àwòrán rẹ̀.
Ó ní òun kìlọ̀ títí pé òkun náà ń ru lárujù lásìkò náà àmọ́ Damilola kò dáhùn òun sì fi sílẹ̀ síbẹ̀.
Ẹ̀yìn ìgbà náà ni àwọn gbọ́ ariwo tí àwọn sì ríi pé Damilola ni odò ń wọ́ lọ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lókè.
Àwọn adóòlá ẹ̀mí gbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí Damilola àmọ́ kò bá a mọ́.
Ìpele kẹrin ni Damilola wà ó sì yẹ kó bẹ̀rẹ̀ ìkọ́niwò ní ọjọ́ Ajé kó tó di pé ó bá odò lọ yìí.
Ọjọ́ kẹta ni wọ́n tó rí òkú rẹ̀ ní Museyo ní adojúkọ ibi tí omi náà ti gbé e wọ́n sì ti sin òkú rẹ̀ sí Museyo náà




