Arákùnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Alexander Peter ti ṣá ìyá rẹ̀ ládàá pa ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.
Ẹni ọdún mọ́kànléláàdọ́rin ni ìyá Alexander, abúlé Ikot Inyang ní ìjọba ìbílẹ̀ Oruk Anam, ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ni ó ń gbé pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ Alexander.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù Okúdù tí a wà yìí ni Alexander ṣá ìyá rẹ̀ náà ládàá pa.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ṣì ń ṣe ìwádìí ohun tó mú kí Alexander ó ṣá ìyá rẹ̀ pa nítorí títí di àsìkò yìí, Alexander kò tíì rí àlàyé kankan ṣe.
Irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí kìí ṣe àkọ́kọ́ láàrín àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ mọ̀lẹ́bí kan náà. A mú iròyìn wá nínú ọdún yìí nípa Pásítọ́ ìjọ ìràpada kan tó ṣá ìyàwó rẹ̀ ládàá pa ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom yìí kan náà. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Ọ̀gá ọlọ́pàá ti ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ní ọwọ́ ti tẹ Pásítọ̀ ìjọ Ìràpadà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Victor Okoh. Ọmọ ọdún méjìlélógójì ni Victor, ẹ̀sùn tó fi kan ìyàwó rẹ̀ náà ni pé ó ń ṣe àgbèrè.
Victor Okoh kò ká ọkùnrin pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, ó ní òun fura síi ni pé ó ń yan àlè mọ́ òun lára.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ pasitọ Victor Okoh, ó ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá níbi tí wọ́n ti n fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò láti mọ ohun tó rí lọ́bẹ̀, tó fi waro ọwọ́. Ikú victoria ti dá ọ̀fọ̀ nlá sílẹ̀ ní agbègbè rẹ̀ nítorí ṣe ni tọmọdé tàgbà n kárí bọnú, tí wọ́n dáró, tí wọ́n n kọ hàà! hàà! Irú kí lèyí?
Timfon John; ọlọ́pàá tí yóò ṣe ẹjọ́ náà wí pé ẹjọ́ ti dé ọ̀dọ̀ àwọn, ọwọ́ sì ti tẹ àfurasí ọ̀daràn náà, wọ́n sì ti gbé òkú Victoria lọ sí ilé ìgbókùúsí ti ilé ìwòsàn ìjọba ìpínlẹ̀ náà.
Ní kété tí pásítọ̀ Victor Okoh ti ṣiṣẹ́ láabi rẹ̀ tán ló bá lọ fara pamọ́ sábẹ́ òrùlé, ibẹ̀ ni ọwọ́ ti bà á. Àwọn ará àdúgbò ní kìí ṣèní kìí ṣàná ni gbọ́nmi-si-ò-tó ti n wáyé lààrín tọkọ tayà yìí, bí wọ́n ti máa n ṣe ní gbogbo ìgbà nìyí, kò jọwá lójú àmọ́ tọjọ́ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ nítorí ọ̀rọ̀ ọjọ́ yìí di fàá-kája débi pé pasitọ victor okoh ti pilẹ̀ ní kí ìyàwó máa lọ ilé àwọn òbí rẹ̀, ó ní òun kò ṣe mọ́.
Ṣàdéédé ló tún pè é wọlé padà, a ò mọ bí ọ̀rọ̀ ti padà bẹ́yìn yọ tó fi di pé pasitọ Victor fi ṣá Victoria pa sínú ilé. Ní àkókò yìí, pásítọ̀ Victor Okoh ti ilẹ̀kùn gbọingbọin pa látinú ní èyí tí kò fún àwọn olùlàjà kankan láàyè láti làwọ́n. Gbogbo bí ìyàwó ṣe ń kígbe , ‘ẹ gbà mí oooo, ó ti fẹ́ pamí oooo, yééè! A kò le è gbà á sílẹ̀ nítorí kò ṣeéṣe fún wa ni á bá pe aago àwọn ọlọ́pàá kí wọ́n tètè wá dá sí ọ̀rọ̀ náà kó tó bẹ́yìn yọ.
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá náà ti dé, wọ́n sì fi tipàtipá fa ilẹ̀kùn já ní wọ́n bá bá Victoria nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àti àdá tó n kán tó tó tó fún ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀.
Kíá ni àwọn ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí, abẹ́ òrùlé ni wọ́n ti fa ọkọ ìyàwó yọ níbi tó kájọ sí bí ejò sèbé ni ọwọ́ bá ba aláṣejù rẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé afurasí ọ̀dàran náà yóò fojú bá ilé ẹjọ́ fún ẹ̀sùn ìpànìyàn nítorí pé ó lódìí sí òfin orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Nàìjíríà. Bákan náà ni wọ́n rọ lọ́kọláya láti máa fi pẹ̀lẹ́pùtù yanjú aáwọ̀.
Ìròyìn mìíràn tún fara pẹ́ èyí ni ti ọkọ tó lu ìyáwó rẹ̀ pa nítorí oúnjẹ ìṣínu àwẹ̀ Ramadan tó kọjá yìí.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ní agbègbè Fadamam Mada nítòsí ní ìpínlẹ̀ Bauchi.
Orúkọ afurasí náà ni Alhaji Nuru Isah ẹni tó jẹ́ ọmọ àádọ́ta ọdún. Isah na ìyàwó rẹ̀; Wasila Abdullahi, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún pa lẹ́yìn ìjà àti asọ̀ lórí oúnjẹ àti èso tí wọn yóò fi ṣínu ààwẹ̀ lọ́jọ́ náà.
Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn sọ pé ẹgba ni Alhaji Nuru Isah kó bo ìyàwó rẹ̀ Wasila títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀. Gbogbo akitiyan láti dóòlà ẹ̀mí rẹ̀ ló jásí pàbó.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi; Auwal Musa Muhammed wí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ kan kò ní lọ láì jìyà àti pé kò sí ààyè fún ìfìyàjẹni lọ́nà àìtọ́, kí tọkọ tayà máa tètè yanjú aáwọ̀ ní pẹ̀lẹ́ kùtù kó tó búrẹ́kẹ́. Ó ní Alhaji Nuru Isah yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí ìwádìí bá parí.
Bákan náà ni ọwọ́ wa tẹ ìròyìn kan láti ìpínlẹ̀ Edo nípa ọkùnrin kan tó ṣekú pa ìyàwó rẹ̀. A gbọ́ pé Kelvin Izekor ṣekú pa ìyàwó rẹ̀; Success Izekor nípa ṣíṣá a ládàá pa.
Inú oṣù Èbìbí ọdún yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀, a gbọ́ pé Kelvin àti Success ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìgbéyàwó ni nígbà náà, kò sí ẹni tó le sọ pàtó ohun tó mú kí Kelvin ó yọ àdá sí ìyàwó rẹ̀ tó sì ṣá a láṣàápa.
Àwọn ọlọ́pàá ló wá gbé òkú Success lọ sí ilé ìgbókùú sí, kódà, wọ́n yí i mọ́ aṣọ ni nítorí pé kò ṣe é gbé lódindi, ó ṣá a wẹ́lẹwẹ̀lẹ ni.
Àwọn ará ilé wọn wí pé ọ̀rọ̀ náà ṣe àwọn ní kàyééfì nítorí pé kò pẹ́ tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò jà.
Àwọn ọ̀dọ́ tilẹ̀ fẹ́ dáná sun Kelvin ni àwọn ọlọ́pàá ló gbà á kalẹ̀, wọ́n ní yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́.




