Àpótí ìwé wó pa ọmọ ọdún méjì ní ilé ìwé; Wisdom Gate. Elimgbo ní ìjọba ìbílẹ̀ Obio/Akpor, ìpínlẹ̀ Rivers ni ilé ìwé náà wà. Ẹ̀sùn tí àwọn òbí Winnie fi kan ilé ìwé Wisdom Gate ni pé wọ́n fi igbá kan bọ̀kan nínú lórí ikú tó pa ọmọ wọn nínú ilé ìwé náà. Wọ́n tún fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọ́n fẹ́ paná ọ̀rọ̀ náà.
Àlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni pé Winnie Akukue lọ sí ilé ìwé lọ́jọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Ẹrẹ́nà. Ọmọ náà ń sùn ni àpótí ìwé náà wó lu ọmọ náà, wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn méjì àmọ́ Winnie padà kú. Wọn kò sọ fún àwọn òbí rẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n kàn ní ó ṣe bákan àwọn sì gbé e lọ sílé ìwòsàn.
Ọ̀gbẹ́ni Akekue ṣe àlàyé pé àyẹ̀wò òkú Winnie fi hàn pé eegun orí rẹ̀ fọ́ sínú tó sì ṣekú pa á, dọ́kítà tó ṣe àyẹ̀wò náà fi yé wọn pé nǹkan tó wuwo ló ba ọmọ náà lórí. Wọ́n ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èsì àyẹ̀wò náà yóò tẹ àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Ilé ìwé Wisdom Gate jiyàn pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Bàbá Winnie fi ẹ̀sùn kàn wọ́n pé àpótí ìwé náà ló wó pa ọmọ rẹ̀ nítorí wọ́n ti gbé àpótí náà kúrò níbi tó wà tẹ́lẹ̀.
Láti ìgbà náà ni ọ̀rọ̀ náà ti wà ní àgọ́ ọlọ́pàá, ọ̀gbẹ́ni Akukue fi ẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá pé wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ falẹ̀.
Wàyí o, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers ti fèsì láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Grace Iringe Koko. Ó ṣe àlàyé pé ọ̀rọ̀ náà ti dé iwájú ẹ̀ka CID ìwádìí sì ń lọ lọ́wọ́. Wọ́n ti ṣe àyẹ̀wò òkú ọmọ náà wọ́n sì ń bá ìwádìí lọ. Grace tako ọ̀rọ̀ tí Akukue sọ pé wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀ àti pé àwọn kò mọ̀ nípa àwọn tí wọ́n ń halẹ̀ mọ́ Akukue pé kí ó sin ọmọ náà kó sì fi ṣe egbò ilé.
Akukue àti ìyàwó rẹ̀ ṣe àlàyé pé gbogbo ìgbà ni ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọn ń dún, bí wọ́n bá ti gbé e, ìhàlẹ̀ ni wọ́n ń gbọ́ pé kí wọn ó pa ẹjọ́ dé kí wọn sì yanjú rẹ̀ ní tùbí-ǹ-nùbí bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò ríyà he. Lẹ́yìn náà ni wọ́n pe àwọn tó sún mọ́ wọn tí wọ́n sì halẹ̀ mọ́ àwọn náà.
Wọ́n ní ẹ̀rù ń bà àwọn báyìí nítorí àwọn tí wọ́n ń halẹ̀ mọ́ wọn pé kí wọn ó má ṣe ẹjọ́ bí wọ́n bá fẹ́ gbé ayé. Akukue ní ohun tí òun ń fẹ́ náà ni kí ìdájọ́ òdodo ́ wáyé lórí ikú ọmọ rẹ̀.
Ọ̀gá ilé ìwé fèsì:
Ọ̀gá ilé ìwé Wisdom Gate náà fèsì sí gbogbo ẹ̀sùn yìí. Ó ní àwọn kò figbá kan bọ̀kan nínú àti pé àpótí kò wó pa ọmọ náà. Ìgbà tí ọmọ náà ṣe bákan ni àwọn gbé e lọ sí ilé ìwòsàn tó sì kú sí ilé ìwòsàn kejì tí wọ́n gbé e lọ. Ó ṣe àlàyé pé àwọn ti sọ gbogbo rẹ̀ fún àwọn ọlọ́pàá àwọn ṣì ń ran ìwádìí wọn lọ́wọ́.
Akukue kò gbà:
Bàbá Winnie kọ̀ láti gba àlàyé ọ̀gá ilé ìwé yìí, ó ní àtúntò wáyé ní kíláàsì ọmọ náà lẹ́yìn tí ọmọ náà kú tó já sí pé wọ́n ń fi nǹkan kan pamọ́. Àti pé dọ́kítà tó ṣe àyẹ̀wò òkú Winnie sọ pé nǹkan tó wúwo ló fọ́ ọ lórí, dájúdájú àpótí ìwé ni nítorí wọ́n ti gbé e jìnnà síbi tó wà tẹ́lẹ̀.
Bákan náà ni ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn ṣẹ̀ nílé ìwé girama ìjọba tó wà ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom:
Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé girama ìjọba tó wà ní Ikot Ekpene, ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ti dágbére fáyé lójọ́ Àìkú ọjọ́ àjíǹde. Ufokobong Edwin Godwin ni orúkọ ọmọ náà, ó lọ sí ilé fún ìsinmi àjíǹde ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ní pariwo ọrùn, bàbá ra òògùn ara ríro fún un láìmọ̀ pé ohun tó ṣe é jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Nígbà tí ìnira náà pọ̀ ni wọ́n bá gbé e lọ sílé ìwòsàn àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́, Edwin dágbére fáyé.
Àwọn dọ́kítà tó ṣe ìtọ́jú rẹ̀ ṣe àlàyé pé ẹ̀jẹ̀ dídì ti díi ní ọ̀fun dé ibi ọrùn ló fà á tó fi kú. Bábá Edwin ní ọmọ náà kérora ọrùn àti ọ̀fun àmọ́ òun kan ra òògùn ara ríro fún un ni, kò mọ̀ pé nǹkan ti ṣe ọmọ náà nílé ìwé kí ó tó wálé.
Àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí, wọ́n bá àwọn akẹgbẹ́ Edwin nílé ìwé sọ̀rọ̀. Ìpele kìíní ni Edwin wà, ọmọ tí wọ́n jọ ń lo yàrá ló ṣe àlàyé pé lọ́jọ́ kan kí wọ́n tó gba ìsinmi àjínde, akẹ́kọ̀ọ́ ìpele kẹta àgbà (SS3) kan wà sínú yàrá wọn wá bá Edwin.
Ó bèèrè fún àwọn ohun jíjẹ lọ́wọ́ Edwin àmọ́ ó kọ̀ láti fún un, Edwin ní ìwọn tí ó kù ni òun náà yóò jẹ títí wọn yóò fi lọ sílé. Akẹ́kọ̀ọ́ àgbà náà gbá Edwin ní ọrùn lẹ́ẹ̀mẹ́ta ní kíkankíkan tí Edwin sì dákú.
Ẹni tó ń mójútó wọn nílé ìgbé ni wọ́n ké sí tó sì gbé e lọ sílé ìwòsàn. Edwin jí nílé ìwòsàn àmọ́ ó ti ṣèṣe nínú ọrùn. Ilé ìwé àti alámòjútó wọn kò sọ nǹkankan fún àwọn òbí Edwin nígbá tí wọ́n wá mú un fún ìsinmi àjíǹde.
Jude Ezeogu; ẹni tó jẹ́ ọ̀gá ilé ìwé náà wí pé òun kò tíì le wí nǹkankan àfi ìgbà tí wọ́n bá ṣe ìpàdé lọ́la. Àmọ́ ikú Edwin dun òun nítorí pé ọmọ wọn ni.
Bàbá Edwin rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba ìpínlẹ̀ Akwa Ibom láti ṣe ìwádìí àti ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ rẹ̀.




