Àwọn òṣìṣẹ́ iná mọ̀nàmọ́ná IKEJA ELECTRICITY DISTRIBUTION COMPANY ṣàgbákò lánàá látàrí bí wọ́n ti kúndùn láti máa sọ àwọn ènìyàn sínú òkùnkùn , wọ́n sì máa gbé bíìlì kiri tóṣù bá parí. Àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ àbò òfurufú tó wà ní SAM ETHNAN AIR FORCE ní Ìkẹjà fi imú àwọn òṣìṣẹ́ iná dánrin, ṣìyàjẹ́ bò wọ́n, wọ́n rugi oyin. Agogo méjé kọjá díẹ̀ láàrọ́ ọjọ́ Ẹtì ni wọ́n ya wọ inú ọgbà iléesẹ́ iná mọ̀nàmọ́ná IKEDC, ọkọ̀ akóyọyọ méjì ni àwọn ẹ̀ṣọ́ àbò OP-MESA wà gúnlẹ̀ sí iléeṣẹ́ àwọn oní iná mọ̀nàmọ́ná IKEDC, pẹ̀kí-n-pẹ̀kí ni wọ́n ṣe pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ iná bí wọ́n ti múra láti lọ ṣe iṣẹ́ oòjó wọ́n ní ÀDÌYÀN. KÍÁ! Àwọn ẹ̀ṣọ́ àbò òfurufú fàwọ́n bọ́ sílẹ̀ láti inú ọkọ̀ wọn,wọ́n nà wọ́n bí i bẹ̀mbẹ̀ Ànọ́bì, wọ́n tún fi ìdí wọn gúnlẹ̀.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ àbò òfurufú tí obìnrin sáájú wọn dé sí iléeṣẹ́ àwọn oní iná IKEDC, wákàtí kan àbọ̀ ni wọ́n fi pitú méje tí ọdẹ n pa ninú igbó. Níṣe ni wọ́n dábùú ọ̀nà, èyí fún wọn ní ànfààní láti pidán fún àwọn òṣìṣẹ́ iná náà dáradàra. A gbọ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ iná lọ kó wáyà iná wọn lọ, wọ́n sọ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò sínú òkùnkùn látàrí gbèsè bílíọ̀nù mẹ́rin náírà tí wọ́n jẹ. Ọ̀gá àgbà àwọn òṣìṣẹ́ iná IKEDC, KINGSLEY OKOTIE sọ pé àwọn ẹ̀ṣọ́ àbò òfurufú jẹ gbèsè bílíọ̀nù mẹ́rin, àwọn sì ti fí ìwé ìfilọ̀ ránṣẹ́ láìmọye ìgbà fún wọn kó tó di pé àwọn gbé ìgbésẹ̀ láti lọ yọ iná wọn; KINGSLEY OKOTIE ní ọṣẹ́ nlá ni àwọn ẹ̀ṣọ́ àbò ṣe lọ́dọ̀ àwọn lọ́jọ́ ẹtì tó kọjá yìí, gbogbo ìlẹ̀kùn ni wọ́n bà jẹ́, ẹ̀rọ̀ àbò CCTV gan an bàjẹ́, gbogbo ẹ̀rọ kọ̀mpútà ni wọ́n tún fọ́ láì ṣẹ́ku nnkankan. Ojúmọmọ ọjọ́ Ẹtì ni àwọn ẹ̀ṣọ́ àbò òfurufú SAM ETHNAN AIR FORCE BASE wá kó ogun ja àwọn.
Arábìnrin FUNMILAYO ADENIYI, òṣìṣẹ́ IKEDC wí pé ‘ìṣẹ̀lẹ̀ tí n kò le è gbàgbé lọ́jọ́ pípẹ́ nìyí. Ṣàdéédé ni àwọn ẹ̀ṣọ́ àbò òfurufú ya wọ iléeṣẹ́ wà, wọ́n fi ìdí ìbọn lù mí, méjì nínú wọn gbé mi jù sínú ọkọ̀ wọn, mo ti lẹ̀ lérò pé ọgbà wọn ni à n lọ ṣùgbọ́n wọ́n fàmí bọ́ sílẹ̀, wọ́n fi ìdí mi gúnlẹ̀, wọ́n tún da omi sími lára, wọ́n kó pàṣán bòmí bí ẹran, ànàdojúdélẹ̀ ni wọ́n lù mí, mi ò sì le è dá dìde.
ỌLÀJÍDÉ KỌ́LÁWỌLÉ, òṣìṣẹ́ mìíràn ní IKEDC tún ṣàlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ àbò òfurufú pé : ‘ Njẹ́ Ẹ tilẹ̀ mọ̀ pé àwọn ẹ̀ṣọ́ náà pọ̀ jùwá lọ, àwọn kan nínú wọn gan an fo ìgànná wọlé síwa lára, wọ́n lù wá jù, tẹ̀gàn ni ẹ̀ẹ̀ẹ̀n! wọ́n na SAMUELI náà tí ajìjọ n ṣọ́ ẹnu ìbodè bí i bẹ̀mbẹ́ Ànọ́bì, wọ́n tún ṣíjú sí àwọn èèyàn tó n jẹun ní iyàrá oúnjẹ ló faragbá níbi ìkọlù ọjọ́ Ẹtì tó kọjá.
GABRIEL FATOYE ní wọ́n gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi lásìkò ìkọlù yìí, jẹ́ẹ́jẹ́ ni mò sì n bọ̀ láti ìta ni mó bá ṣe pẹ̀kì-n-rẹ̀kí pẹ̀lú wọn, wọ́n fi nínà ba tèmi jẹ́, fóònù mi gan an lọ sí i.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí àwọn ará àdúgbò agbègbè ILASAMAJA ní ìjọba ìbílẹ̀ OSHODI/ISOLO ní Èkó náà n fi ẹ̀họ́nú wọn hàn bí wọn kò ṣe rí iná mọ̀nàmọ́nà lò láti oṣù kẹsàn án ọdún 2024. Bákan náà ni ọmọ ṣe orí ní agbègbè ISOKAN PHAZE I&II, WAKILU STREET, GREENLAKE AYOBO, inú òkùnkùn birimùbirimù ni wọ́n wà láti oṣù kejìlá ọdún 2024, wọn rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba àpapọ̀ alámójútó iná pé kí wọ́n rí sí ìwà láabi tí iléeṣẹ́ IKEDC n hù sí wọn látàrí ẹ̀rọ̀ amúnáwá tiransifọ́mà tó ti bàjẹ́ tí wọn kò sí túnṣe. Ìdènà nlá ni èyí jẹ́ fún ìgbé ìrọ̀rùn àwọn ará àdúgbò náà , owó kò sí bẹ́ẹ̀ iṣẹ́ kò lọ déédé. Owó gọbọi ni wọ́n n ra epo bẹntiróòlù àti sólà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ipá wọn kò sì káa.
Inú m bí àwọn èèyàn wọnyìí,a kò sì le è sọ ohun tó le è tẹ̀yìn rẹ̀ yọ.Arábìnrin FUNMILAYO ADENIYI, òṣìṣẹ́ IKEDC wí pé ‘ìṣẹ̀lẹ̀ tí n kò le è gbàgbé lọ́jọ́ pípẹ́ nìyí. Ṣàdéédé ni àwọn ẹ̀ṣọ́ àbò òfurufú ya wọ iléeṣẹ́ wà, wọ́n fi ìdí ìbọn lù mí, méjì nínú wọn gbé mi jù sínú ọkọ̀ wọn, mo ti lẹ̀ lérò pé ọgbà wọn ni à n lọ ṣùgbọ́n wọ́n fàmí bọ́ sílẹ̀, wọ́n fi ìdí mi gúnlẹ̀, wọ́n tún da omi sími lára, wọ́n kó pàṣán bòmí bí ẹran, ànàdojúdélẹ̀ ni wọ́n lù mí, mi ò sì le è dá dìde.
ỌLÀJÍDÉ KỌ́LÁWỌLÉ, òṣìṣẹ́ mìíràn ní IKEDC tún ṣàlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ àbò òfurufú pé : ‘ Njẹ́ Ẹ tilẹ̀ mọ̀ pé àwọn ẹ̀ṣọ́ náà pọ̀ jùwá lọ, àwọn kan nínú wọn gan an fo ìgànná wọlé síwa lára, wọ́n lù wá jù, tẹ̀gàn ni ẹ̀ẹ̀ẹ̀n! wọ́n na SAMUELI náà tí ajìjọ n ṣọ́ ẹnu ìbodè bí i bẹ̀mbẹ́ Ànọ́bì, wọ́n tún ṣíjú sí àwọn èèyàn tó n jẹun ní iyàrá oúnjẹ ló faragbá níbi ìkọlù ọjọ́ Ẹtì tó kọjá.
GABRIEL FATOYE ní wọ́n gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi lásìkò ìkọlù yìí, jẹ́ẹ́jẹ́ ni mò sì n bọ̀ láti ìta ni mó bá ṣe pẹ̀kì-n-rẹ̀kí pẹ̀lú wọn, wọ́n fi nínà ba tèmi jẹ́, fóònù mi gan an lọ sí i.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí àwọn ará àdúgbò agbègbè ILASAMAJA ní ìjọba ìbílẹ̀ OSHODI/ISOLO ní Èkó náà n fi ẹ̀họ́nú wọn hàn bí wọn kò ṣe rí iná mọ̀nàmọ́nà lò láti oṣù kẹsàn án ọdún 2024. Bákan náà ni ọmọ ṣe orí ní agbègbè ISOKAN PHAZE I&II, WAKILU STREET, GREENLAKE AYOBO, inú òkùnkùn birimùbirimù ni wọ́n wà láti oṣù kejìlá ọdún 2024, wọn rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba àpapọ̀ alámójútó iná pé kí wọ́n rí sí ìwà láabi tí iléeṣẹ́ IKEDC n hù sí wọn látàrí ẹ̀rọ̀ amúnáwá tiransifọ́mà tó ti bàjẹ́ tí wọn kò sí túnṣe. Ìdènà nlá ni èyí jẹ́ fún ìgbé ìrọ̀rùn àwọn ará àdúgbò náà , owó kò sí bẹ́ẹ̀ iṣẹ́ kò lọ déédé. Owó gọbọi ni wọ́n n ra epo bẹntiróòlù àti sólà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ipá wọn kò sì káa.
Inú m bí àwọn èèyàn wọnyìí,a kò sì le è sọ ohun tó le è tẹ̀yìn rẹ̀ yọ.