Ẹbí Alàgbà Ejezie ní Nnewi ní Ìpínlẹ̀ Anambra pàdánù àwọn ọmọ wọn Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n bí lọ́jọ́ kan náà. Inú ìbànújẹ́ àti ọ̀dọ̀ ni àwọn ẹbí náà wà lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí. Ọmọbìnrin méjì ọmọ ọdún mẹ́sàn-án àti ọmọ ọdún méje ; pẹ̀lú ọmọkùnrin ọmọ ọdún márùn-ún ni àwọn ọmọ náà tí wọ́n bá òkú wọn nínú ẹ̀rọ amúǹkan tútù – fírísà nínú ilé wọn.
Ìyàwó Alàgbà Ejezie tó jẹ́ ìyá awon ọmọ náà tó jẹ́ olùkọ́ àgbà gba ibi iṣẹ́ lọ láàárọ̀, ó fi àwọn ọmọ rẹ́ sílẹ̀ nílé nítorí kò sí ilé-ẹ̀kọ́ lọ́jọ́ náà. Ìpínlẹ̀ Edo ni bàbá wón ti ń ṣiṣẹ́ ìjọba.
Nígbà tí ìyá wọ́n dé latibi iṣẹ́ lọ́sàn-án, ó bá ilẹ̀kùn ilé ni ṣíṣí sílẹ̀ gbagada, tí kò sì ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ rí; fún ìyàlẹ́nu rẹ̀, kò gbúròó àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, èyí tó yàtọ̀ sí ìṣe wọn. Gbogbo ilé adákẹ́ minimini, bí ìyá ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní í wá wọn káàkiri nìyẹn. Kò sí ibi tí wón ò wá wọn dé. Ìyá ránṣẹ́ sí bàbá àwọn ọmọ rẹ̀ tó wà ní Irrua ní ìpínlè Edo. Wọ́n wá àwọn ọmọ náà dé ilé ìjọsìn níbi tí wọ́n ti máa ń ṣíṣẹ̀ẹ́ Olúwa.
Àṣẹ̀hìnwá-àṣẹ̀hìnbọ̀, ṣé wọn ní ìwákúwàá lèèyàn ń wá ohun tó sọnù, èyí ló mú kí Màmá àwọn ọmọ náà ṣàkòtí ṣí inú fírísà ńlá ilé wọn wò. ÈÈMỌ̀ lukutu-pẹ́bẹ́ rèé nígbà tó ń wo òkú àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nínú àgbá òyìnbó ńlá náà.
Ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ láti mọ àwọn ọ̀daràn tó dán irú èyí wò. Wọ́n ti gbé òkú àwọn ọmọ náà lọ sí ibi ìgbókùú sí báyìí.