Ọ̀gá ilé ìwé girama Excel tó wà ní Èjigbò, tó tún jẹ́ pé òun ló ni ilé ìwé náà; Dele Oke ti fèsì sí fọ́nrán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé náà tó gbòde níbi tí àwọn ọmọ náà ti ń fa kàná.
Àlàyé tí Dele Oke ṣe náà ni pé lóòótọ́ ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ nínú ilé ìwé náà àmọ́ kìí ṣe bó ṣe rí nìyẹn, ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù Èbìbí, òbí kan gbé àkàrà òyìnbó àti ọtí ẹlẹ́rìnròdò wá fún ọjọ́ ìbí ọmọ rẹ̀ tó wà ní ilé ìgbé ní nǹkan bíi aago méje, lọ́jọ́ náà, àwọn ọmọ náà jẹ àkàrà òyìnbó náà wọ́n sì tún mu ọtí ẹlẹ́rìnròdò tí ìyá náà gbé wá, ìyá ọmọ náà ló ká fọ́nrán bí àwọn ọmọ náà ṣe yọ ayọ̀ ọjọ́ ìbí náà.
Nípa fọ́nrán tí àwọn ọmọ ń fa kàná nínú rẹ̀, ọ̀gá ilé ìwé Excel wí pé kò rí bẹ́ẹ̀ pé àwọn ọmọ náà kò fa igbó tàbí òògùn olóró, ó ní erépá kan ti wọ́n ń pè ní ‘Puff and Pass’ ni àwọn ọmọ náà ń ṣe.
Wàyí ọ, Dele Oke wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wà ní ìpele àgbà kẹta àwọn sì ti júwe ilé fún gbogbo wọn lásìkò náà.
Nípa ti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, Dele Oke ṣe àlàyé pé àwọn gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìpele àgbà kẹta láàyè láti lo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọn.
Àlàyé Dele Oke tẹ̀síwájú pé àwọn ti ṣe àtúntò ètò ilé ìwé náà ní èyí tí yóò dènà irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí lọ́jọ́ iwájú.
Ó wí wí àwọn ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn olùkọ́, adarí àti àwọn tí wọ́n ń mójútó àwọn ọmọ náà ní ilé ìgbé, àwọn ti ṣe ọ̀pọ̀ àwọn àlàkalẹ̀ tí yóò mú kí àmójútó àwọn ọmọ náà ó nípọn síi.
Fọ́nrán wo ni ó dá gbogbo èyí sílẹ̀?
Fọ́nrán kan tó gba orí ìtàkùn ayélujára kan nínú èyí tí a ti rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé náà tí wọ́n ń fa kàná náà ni, àwọn òbí àti alágbàtọ́ fara ya lórí rẹ̀ wọ́n sì ké sí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó láti gbé ìgbésẹ̀.
A mú ìròyìn náà wá pé:
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti fèsì sí fọ́nrán kan tó gba orí ìtàkùn ayélujára kan, nínú fọ́nrán yìí ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́kùnrin ti ń fa kàná tí wọ́n sì ń fìkan rànkan.
Àwọn ọmọ yìí jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé girama Excel tó wà ní Ejigbo, inú ilé ìgbé ni wọ́n wà tí wọ́n bọ́ aṣọ lọ́rùn, wọ́n ń bẹ́ná sí kàná wọ́n sì tún ń kọ́ àwọn tí kò tíì mọ ẹnu rẹ̀ láàrin wọn.
Inú oṣù Igbe, ọdún yìí ni wọ́n ṣe èyí gẹ́gẹ́ bíi déétì tó wà lórí fọ́nrán náà.
Àwọn òbí faraya lórí fọ́nrán yìí wọ́n sì bu ẹnu àtẹ́ lu ilé ìwé náà fún kíkùnà láti mójútó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.
Kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Olohundare Jimoh ti pàṣẹ fún ẹ̀ka aṣèwádìí Panti láti gba ẹjọ́ náà lọ́wọ́ àgọ́ ọlọ́pàá Ejigbo, wọ́n ti ránṣẹ́ sí ọ̀gá ilé ìwé náà fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.
Abimbola Adebisi; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ṣe àlàyé pé ọ̀gá ilé ìwé náà tó sì tún jẹ́ pé òun ló ni ilé ìwé náà sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà nínú fọ́nrán náà ti kẹ́kọ̀ọ́jáde.
Adebisi wí pé ilé ìwé Excel fi ọwọ́ sòwọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá láti ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
‘A kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ yìí nítorí pé ó níí ṣe pẹ̀lú ọjọ́ ọ̀la àti ìwà ọmọlúàbí. A fi àkókò yìí ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn adarí ilé ìwé láti ṣe àmójútó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn’ – ilé iṣé ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó.
Ní báyìí, aláṣẹ àti ọ̀gá ilé ìwé náà; Dele Oke ti fèsì, ohun tó sọ náà ni pé àwọn ti lé àwọn tó hu ìwà náà kúrò nílé ìwé, irú rẹ̀ kò sì ní ṣẹlẹ̀ mọ́.
Kin ni kò ṣẹlẹ̀ tán nílé ìwé lásìkò yìí? Nínú ọdún yìí náà ni odidi akẹ́kọ̀ọ́bìnrin kan di àwátì nílé ìwé gíga Obafemi Awolowo tó wà ní Ilé-ifẹ̀.
A mú ìròyìn náà wá pé:
Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo tó wà ní Ilé-ifẹ̀ ti di àwátì báyìí, àwọn aláṣẹ ilé ìwé náà ké gbájarè síta.
Dorcas Oseghale ni orúkọ akẹ́kọ̀ọ́ yìí, ẹ̀ka ìmọ̀ kẹ́mísìrì ni ó wà, ó sì ti wà ní ìpele kẹrin.
Ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́ báyìí tí wọ́n ti fi ojú kan Dorcas gbẹ̀yìn.
Alukoro fún ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo; Ọ̀gbẹ́ni Abiodun Olanrewaju ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde.
Ó wí pé àwọn àwọn ará ilé Dorcas ni wọ́n fi sùn pé Dorcas kò padà wọlé lẹ́yìn tó lọ ra oúnjẹ.
Ilé Adesanmi tó wà ní ọ̀nà Ìbàdàn ni Dorcas ń gbé pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, lálẹ́ ọjọ́ náà ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́, Dorcas jáde lọ ra oúnjẹ ní ‘Student’s village’ tó wà ní ọ̀nà Ẹdẹ.
Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò ríi kó dé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní pe aago rẹ̀ àmọ́ aago rẹ̀ méjèèjì kò lọ.
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ẹ̀ṣọ́ ilé ìwé létí wọ́n sì fi sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá.
Ọ̀gá àgbà ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo; Ọ̀jọ̀gbọ́n Simeon Bamire ti pàṣẹ fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé ìwé láti sa ipa wọn ó sì tún rọ àwọn ọlọ́pàá láti wá ọmọ náà jáde.
Ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ náà kò gbẹ́yìn, ní ìpínlẹ̀ Ògùn ni wọ́n ti sín gbẹ́rẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tó sì pa wọ́n lára.
A gbọ́ pé:
Ilé ìwé Aládàání kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun ni àwọn òbí kan ti fẹ̀sùn kàn pé wọ́n sín gbẹ́rẹ́ fún àwọn ọmọ àwọn.
Abosede, ìyá ọmọ ọdún mẹ́rin kan ṣe àlàyé pé Alamis ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní yún odò ikùn rẹ̀, nígbà tí òun yẹ ibẹ̀ wò ni òun rí gbẹ́rẹ́ náà tí òun sì gbé e lọ sí ilé ìwòsàn. Àwọn dókítà ṣe àyẹwò wọn sì wí pé abẹ tí wọ́n fi sín gbẹ́rẹ́ náà ní àwọn kòkòrò àìfojúrí.
Ọmọbìnrin mìíràn tí òun náà ń lọ sí ilé ìwé yìí ni ìyá rẹ̀ ṣe àkíyèsí pé láti ọjọ́ tí òun ti lọ gbé e lọ́sàn-án ọjọ́ náà ni ọmọ òun ti máa ń sun oorun ju bó ṣe yẹ lọ.
Ilé ìwòsàn ni wọ́n ti sọ fún òun náà pé abe tó fi sin gbere náà ní àwọn kòkòrò aifojuri.
Àwọn òbí mejeeji yìí fi ẹsun kan obìnrin tó ni ilé ìwé yìí àmọ́ ó wí pé òun kò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀.
Àwọn òbí yìí ní kó jé kí àwọn ó wo fọ́nrán ẹrọ akaworansile CCTV ilé ìwé náà, obìnrin yìí tún ní kò sí iná lójó náà pé àwọn ero náà kò sise.
Wọ́n tún ní ṣebi ilé ìwé rẹ ní ero afooorunsagbara INVERTER lóbìnrin yìí bá tún wí pé èrò náà kò ṣiṣe lojo náà. Èyí ló mú kí àwọn òbí yìí ó tọ àgọ́ ọlọ́pàá lọ.




