Olórí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ wa; Godswill Akpabio ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ṣe yẹ̀yẹ́ lẹ́yìn tí aṣòfin Chukwu Kelvin tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ náà yapa tó sì darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Aṣòfin Kelvin Chukwu kéde pé òun ti yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ó wí pé ìdí tí òun fi kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ni pé ẹgẹ́ náà kò tòrò, rúdurùdu ni gbogbo rẹ̀ rí.
Èyí ló fà á tí Akpabio fi fi ẹgbẹ́ náà dápàárá pé wọn kò lẹ́nu níbẹ̀ nítorí pé ẹnu wọn kò kò.
Ó wí pé ‘ Mo fẹ́ ẹgbẹ́ alátakò tó fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ tó le dojúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC àmọ́ nígbà tí wọn kò bá rí ara wọn kó jọ láti di gbòógì, dandan ni kí wọn ó darapọ̀ mọ́ mi nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC kí a jọ tukọ orílẹ̀-èdè yìí.
A kò ṣe òṣèlú ẹlẹ́gbẹ́ òṣèlú kan, àǹfààní wà láti fi orúkọ ẹgbẹ́ ọ̀ṣèlú titun sílẹ̀ pẹ̀lú àjọ INEC, ẹ ṣe ara yín ní òṣùṣù ọ̀wọ̀, gbogbo ìgbà ni mo ń káàánú yín lórí bí ẹgbẹ́ yín kò ṣe tòrò.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti lulẹ̀, àbùradà wọn ti fàya, ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ń ṣe ṣégeṣège, ẹgbẹ́ òṣèlú Accord kò sí mọ́, ẹgbẹ́ òṣèlú ADC kùnà kó tó gbéra, ẹ jẹ́ má abọ̀ nínú ẹgbẹ́ tó ní ọjọ́ ọ̀la.
Mo kí ẹ̀yin aṣòfin tí ẹ jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC kú oríiire àlékún tí a ní’ èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Akpabio sọ.
Ọ̀rọ̀ tí olórí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin sọ yìí kò tẹ́ adarí ikọ̀ kéréje lọ́rùn, ó fèsì pé òun bu ọlá fún ipò olórí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin òun sì pọ́n Akpabio lẹ́ àmọ́ òun fẹ́ kí ó mọ̀ pé yíyapa àwọn èèyàn kò le tú ẹgbẹ́ náà.
Moro wí pé bí àwọn ṣe kéré mọ nílé aṣòfin, àwọn náà kópa nínú àṣeyọrí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Abdullai Ganduje; ẹni tó jẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC sọ̀rọ̀ níbi ìgbaniwọlé Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta àti àwọn ẹmẹ̀wàá rẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Ajé pé àwọn Gómìnà yòókù náà ṣì ń bọ̀ wá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Igbákejì ààrẹ; Kashim Shettima ló gba Gómìnà Sherif Oborovwori àti àwọn ikọ̀ rẹ̀ wọlé sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ó kí wọn káàbọ̀ ó sì ṣe wọ́n ní pẹ̀lẹ́.
Níbi ètò náà ni Gómìnà Sheriff ti ṣe àlàyé ìdí tí òun àti ikọ̀ rẹ̀ fi darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Ó wí pé ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfẹ́ hàn sí àwọn ní ìpínlẹ̀ Delta, kò sì sí bí àwọn ṣe le fi ìfẹ́ náà padà bí àwọn bá wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ni àwọn ṣe darapọ̀ mọ́ ọn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ kí ìfẹ́ le máa lọ bó ti yẹ.
Gómìnà Sheriff wí pé òun kò ní ìgbàgbọ́ nínú Festus Keyamo àti àwọn ọmọ Agege yòókù, ó ní òun ni aṣáájú ìpínlẹ̀ Delta, ibi tí òun bá sì lọ ni àwọn yòókù ó lọ pẹ̀lú òun.
Gómìnà Sheriff rọ àwọn Gómìnà yòókù tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Ọ̀rọ̀ Ganduje.
Bí éégún ẹni bá jóo re ni Ganduje fi ọ̀rọ̀ náà ṣe, ó lu Sheriff lọ́gọ enu fún ìgbésẹ̀ akin náà ó sì gbé oríyìn fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu pé ó jẹ́ aṣáájú rere.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ náà ló ti kí àwọn Gómìnà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC fún akitiyan wọn nínú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè yìí.
Ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Gómìnà Sheriff kéde pé òun yóò darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lọ́sẹ̀ yìí tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́.
A mú ìròyìn náà wá pé:
Gọ́mìnà ìpínlẹ̀ Delta; Sheriff Oborevwori ti kéde ìṣípòpadà rẹ̀ láti jíjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kìí ṣe Sheriff nìkan ló yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, bí ìgbín bá fà ni ó fi ọ̀rọ̀ náà ṣe, Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta tẹ́lẹ̀rí; Ifeanyi Okowa àti gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Delta tó fi dé orí alága ìjọba ìbílẹ̀ ni wọ́n ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC báyìí.
Ìkéde yìí wáyé ní Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtalélógún, oṣù Igbe ní Asaba tíí ṣe olú ìlú Delta. Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà nnì; James Manager ló fi ìkéde yìí síta lẹ́yìn ìpàdé oníwákàtí mẹ́fà tó wáyé ní ilé ìjọba tó wà ní Asaba.
Aṣòfin James wí pé gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Delta pátá ló ti gbà láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Tó fi dé orí agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ pátá tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, gbogbo wọn ló ti digbá dagbọ̀n wọn báyìí láti ré kété sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kọmiṣọ́nà fún ìfitónilétí ní ìpínlẹ̀ Delta; Ọ̀gbẹ́ni Aniagwu Charles náà sọ̀rọ̀ lórí ìṣípòpadà yìí, ó wí pé àwọn kò le wà nínú ọkọ̀ tó ti rì, ó di dandan kí àwọn ó ṣe àtúnṣe sí ètò ìṣejọba àwọn ní èyí tó gba kí àwọn ó ṣe ìpinnu tó nípọn bẹ́ẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Charles wí pé ìpinnu yìí yóò jẹ́ kí iṣẹ́ rere ó le tẹ̀síwájú ní ìpínlẹ̀ Delta. Dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC yóò mú kí ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ó dé bá ìpínlẹ̀ Delta, ìgbé ayé àwọn ará Delta yóò di ọ̀tun, ìpínlẹ̀ Delta ó wá di ìpínlẹ̀ tí yóò ṣe máa mú yangàn láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Charles tẹ̀síwájú pé àwọn aṣáájú ló ṣe ìpinnu náà, ó sì di dandan kí gbogbo àwọn ìsọmọgbè ó tẹ̀lé e nítorí pé ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Delta ló jẹ gbogbo àwọn lógún.
Ọjọ́ Ajé tó ń bọ̀ yìí ni gbogbo wọn ó di ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lógidi. Kí a máa retí ìsọdọ̀tun ní ìpínlẹ̀ Delta ló kù báyìí.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn olóṣèlú máa kọ ẹgbẹ́ òṣèlú kan sílẹ̀ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn àmọ èyí kàmọ̀mọ̀, gbogbo ìlú lẹ́ẹ̀kan náà.
Ní báyìí tí gbogbo àwọn olóṣèlú ìpínlẹ̀ Delta ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, alága ẹgbẹ́ náà ti sọ pé gbogbo àwọn Gómìnà yòókù náà ń bọ̀ wá darapọ̀.




