Akọ̀ròyìn Ayo Babalola Ti Gba Itúsílẹ̀ Lágọ̀ọ́ Ọlọ́pàá. Níbi ìwọ́de ìfẹ́hónúhàn tí Ayọ̀ lọ ká sílẹ̀ lọ́jọ́ àbámẹ́ta tó kọjá ní olú ìlú wa Abuja ni àwọn ọlọ́pàá ti mú un tí wọ́n sì tìí mọ́lé fún wákàtí mẹ́rìnlélógún gbáko.
Àgọ́ ọlọ́pàá Wuye náà ni wọ́n gbé akọ̀ròyìn ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n náà lọ lọ́jọ́ àbámẹ́ta ọ̀ún kí wọ́n tó dáa sílẹ̀ láago mẹ́ta ọ̀sán ọjọ́ Àìkú pé kí ó máa lọ ilé rẹ̀ láyọ̀.
Èyí kò ṣàdédé wáyé bíkòṣe ariwo, ẹ̀bẹ̀, ìpè àti èpè àwọn ẹbí, ará àti ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀ tó pọ̀jù fún àjọ ọlọ́pàá pé kín ni ẹ̀ṣẹ̀ arákùnrin náà gan-an?
https://www.christiantoday.com.au/news/the-roaring-reformer-apostle-ayo-babalola.html
https://iweiroyinyoruba.com/e-lo-fokan-bale/
Ayo Babalola dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà tó délé lánàá pé wọ́n ṣeun wọ́n kú àdúrótì.
Bákan náà ni ìròyìn tẹ̀ wá lọ́wọ́ pé ẹni tí ó darí ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ẹ̀ka Abuja ni àwọn ọlọ́pàá DSS lọ gbé ní ilé rẹ̀ lóru àná.
Aago méjì òru ni wọ́n yabo ilé Michael Lenin tí wọ́n sì mú un ní tìpátìkúùkú wọ inú ọkọ̀ wọn.