Àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo tó fìkàlẹ̀ sí Ile-Ife ń dárò akẹ́kọ̀ọ́ kan tó sùn tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ kú láti ojú oorun.
A gbọ́ pé Timileyin Toromade; akẹ́kọ̀ọ́ ìpele kẹta ẹ̀kọ́ ìṣègùn òyìnbó sùn ní alẹ́ ọjọ́ Ajé kò sì padà jí sáyé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun. Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni Timileyin, ìpele kẹta ló wà nínú ẹ̀kọ́ ìṣègùn òyìnbó àti iṣẹ́ abẹ.
Alukoro ilé ìwé náà; Abiodun Olanrewaju fi àtẹ̀jáde kan léde, nínú rẹ̀ ló ti sọ pé Timileyin kú ní nǹkan bíi aago méjì òru mọ́jú ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ìdí ni pé nǹkan bíi aago méjì òru náà ni akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣí ilẹ̀kùn fún akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí wọ́n jọ ń gbé.
Ọ̀gá ilé ìwé náà; Ọ̀jọ̀gbọ́n Simeon Bamire bá àwọn ẹbí Toromade kẹ́dùn ọmọ wọn tó lọ, ó fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sí wọn pé òun banujẹ́ gidi lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Timileyin fi ara da gbogbo àdojúkọ tó rọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ ìṣègùn òyìnbó pẹ̀lú ìrètí pé yóò máa ṣe ìwòsàn fún àwọn èèyàn lọ́la àmọ́ kòkòrò kò jẹ́ kí a gbádùn obì tó gbó, ikú mú Timileyin lọ láàrín àwọn akẹgbẹ rẹ̀.
Ilé ìwé náà ṣe ìlérí àtiṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ohun tó le fa ikú Timileyin, wọ́n rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pàápàá àwọn akẹgbẹ́ Timileyin láti kún fún àdúrà fún mọ̀lẹ́bí akẹgbẹ́ wọn náà lásìkò yìí.
Ilé ìwé OAU ń jáde nínú ìròyìn lẹ́nu lọ́lọ́ yìí, ìgbà kan ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ké gbàjarè pé wọ́n ń jí àwọn gbé, lẹ́yìn ìgbà náà ni wọ́n tún pariwo síta pé àwọn adigunjalè ń yọ àwọn lẹ́nu:
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo ní Ilé-Ifẹ̀ kò ní ojú oorun lásìkò yìí látàrí pé àwọn adigunjalè ń bá wọn lálejò lemọ́lemọ́, tìbọntìbọn ni pàápàá.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé àwọn ilé ìgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tó wà ní ìta ọgbà ilé ìwé náà ń gbóná janjan láìkò yìí, tìbọn tàdá ni àwọn olè náà ń dé bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lálejò, wọ́n nà wọ́n lálùbámi wọ́n tún ṣe wọ́n léṣe.
Daniel; ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ náà bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ó wí pé nǹkan bíia aago mọ́kànlá alẹ́ ni àwọn olè náà máa ń ya dé tí wọn ó sì da ìbọn bolẹ̀, wọn yóò gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, ẹ̀rọ ayárabíàṣá, owó àti àwọn ohun ìní mìíràn lọ, ó pẹ́ tán, ọjọ́ kẹrin, wọn ó tún dé.
Ó wí pé àwọn aṣojú akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń pè ní SUG ló gba àwọn kalẹ̀ tí wọ́n gbé àwọn tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn.
Àwọn aláṣẹ ilé ìwé kò ṣe bí ìgbà tí wọ́n gbọ́ nǹkankan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, èyí ló mú kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ó kóra jọ kojú àwọn olè náà nígbà tí wọ́n tún padà wá àmọ́ ìró ìbọn ló tú wọn ká.
Lọ́jọ́ tí wọ́n ṣe ìkọlù sí Peace Hostel, pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àdá ni wọ́n fi dábírà sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lára.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti wá ké gbàjarè síta báyìí, wọ́n ké sí àwọn aláṣẹ ilé ìwé náà àti ìjọba láti pèsè ààbò tó péye fún wọn. Wọ́n ní nǹkan kò fara rọ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Obafemi Awolowo, bí olè ṣe ń jà wọ́n ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń sọnù, láàrín oṣù méjì, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bíi méjì ni wọn kò rí mọ́ di asìkò yìí, bí alẹ́ bá ti lé, wọn kò gbọdọ̀ jáde, jíjígbé ni, bí wọ́n tún wà nínú ilé, olè ń bọ̀ wá ká wọn mọ́, wọ́n ní ẹ̀mí àwọn kò dé mọ́ kí ìjọba ó gbà wọ́n kalẹ̀.
Wọ́n tilẹ̀ tún jí akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn gbé àmọ́ ó sá mọ́ wọn lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ mú un sínú ọkọ̀ mìíràn tórí sì kó o yọ.
Àwọn SRC bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣejọba Gómìnà Ademola Adeleke pé ó kùnà láti pèsè ààbò tó péye fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́.
Gbogbo akitiyan láti bá àwọn aláṣẹ ilé ìwé náà sọ̀rọ̀ kò yọrí sí rere látàrí pé aago alukoro ilé ìwé náà; Ọ̀gbẹ́ni Abiodun Olanrewaju kò lọ bẹ́ẹ̀ sì ni kò fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́.
Àwọn akọ̀ròyìn kàn sí alukoro ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun; Abiodun Ojelabi lórí ọ̀rọ̀ yìí àmọ́ ó yani lẹ́nu nígbà tó fèsì pé òun kò gbọ́ nǹkankan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kò fi tó àwọn ọlọ́pàá létí rárá pé àwọn kò tilẹ̀ mọ̀ pé wọ́n ń sọnù tàbí pé olè ń ká wọn mọ́, ó ní tó bá ṣe pé àwọn gbọ́ ni, àwọn yóò ti wá nǹkan ṣe síi.
Èyí tó tún dà bíi rẹ̀ ni ti akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga NOUN tó kú sínú gbọ̀gàn ìdánwò. A mú ìròyìn náà wá pé:
Àlàyé tí a rí gbà ni pé Michael Coker wà ní gbọ̀gán ìdánwò ní ẹ̀ka ilé ìwé náà tó wà ní Victoria Island, ó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìdánwò rẹ̀ ní ó ṣàdédé mú ìdí lọ sílẹ̀, ẹni tó wà lẹ́yìn rẹ̀ ló pàdé rẹ̀ tó sì tẹ́ ẹ sílẹ̀. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fẹ́ ṣúgbà rẹ̀ kí wọn ó ṣa aájò rẹ̀ àmọ́ olùkọ́ kan tó jẹ́ obìnrin ní kí wọn ó fi sílẹ̀ pé yóò dìde ó sì lé wọn padà sídìí ìdánwò wọn.
Lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́rin tí Michael ti wà nílẹ̀ tí èémí rẹ̀ sì ń ṣe ṣégeṣège, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tún gbìyànjú àtiṣe aájò rẹ̀ àmọ́ olùkọ́ náà tún lé wọn padà. Nígbà tó lé ní ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún tí Michael ti wà nílẹ̀, olùkọ́ mìíràn wọlé wá ó sì wí pé àwọn ti pé nọ́ọ̀sì. Ó gba nọ́ọ̀sì náà ní ìṣẹ́jú márùn-ún mìíràn kí ó tó gbé Michael jókòó, lẹ́yìn náà ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ṣèt̀ àtigbé e lọ sí ilé ìwòsàn.
Bukola; ẹni tí òun náà jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àlàyé pé àwọn bèèrè bí Michael bá ní wárápá tàbí gìrì, wọ́n tilẹ̀ gbìyànjú àtifi ṣibí há a lẹ́nu àmọ́ olùkọ́ náà kò gbà.
Ilé ìwòsàn àkọ́kọ́ tí wọ́n gbé Michael lọ kò gbà á, wọ́n darí rẹ̀ sí ilé ìwòsàn mìíràn àmọ́ Michael kú kí wọ́n tó dé ilé ìwòsàn kejì.
Nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ parí ìdánwò ni wọ́n gbọ́ pé Michael Coker ti kú, wọ́n nàka àbùkù sí olùkọ́ náà pé òun ni kò jẹ́ kí wọn ó tètè ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
Olùkọ́ mìíràn ní ilé ìwé náà tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun ṣe àlàyé pé èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí akẹ́kọ̀ọ́ yóò dákú tí yóò sì tún dìde. Ó wí pé púpọ̀ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni ó ní àìsàn lágọ̀ọ́ ara, òmíràn kò tilẹ̀ mọ̀ títí yóò fi wá dákú sí ilé ìwé tàbí nínú ìdánwò.
Akẹ́kọ̀ọ́ kan ti dákú rí tó sì jẹ́ pé òògùn olóró tó mu ló fà á. Òmíràn ní gìrì, òmíràn ní ikọ́ọfe tí wọn yóò sì máa dákú.
Akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun sọ èrò rẹ̀ pé òun kò lérò pé olùkọ́ náa mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe ìdíwọ́ fún ìtọ́jú Michael, ó lè jẹ́ pé ó kàn fẹ́ kí wọn ó fún un ní ààyè kí atẹ́gùn le fẹ́ síi. Ó ní òun kò sí nínú gbọ̀ngán lásìkò náà òun kàn gbọ́ ariwo ni.
Àwọn akọ̀ròyìn kàn sí ilé ìwòsán Bonny Camp tí wọ́n kọ́ gbé Michael lọ, dọ́kítà ibẹ̀ ní àwọn kò kọ Michael, àwọn darí rẹ̀ lọ sí ilé ìwòsàn mìíràn nítorí àwọn kò ní èémí tó nílò.
Àwọn mọ̀lẹ́bí Michael ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́, wọn kò tíì le sọ nǹkankan báyìí bẹ́ẹ̀ sì ni adarí ilé ìwé náà kọ̀ láti fèsì sí ìbéèrè àwọn akọ̀ròyìn.





