Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo tó wà ní Ilé-ifẹ̀ ti di àwátì báyìí, àwọn aláṣẹ ilé ìwé náà ké gbájarè síta.
Dorcas Oseghale ni orúkọ akẹ́kọ̀ọ́ yìí, ẹ̀ka ìmọ̀ kẹ́mísìrì ni ó wà, ó sì ti wà ní ìpele kẹrin.
Ó ti pé ọjọ́ mẹ́rin báyìí tí wọ́n ti fi ojú kan Dorcas gbẹ̀yìn.
Alukoro fún ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo; Ọ̀gbẹ́ni Abiodun Olanrewaju ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde.
Ó wí pé àwọn àwọn ará ilé Dorcas ni wọ́n fi sùn pé Dorcas kò padà wọlé lẹ́yìn tó lọ ra oúnjẹ.
Ilé Adesanmi tó wà ní ọ̀nà Ìbàdàn ni Dorcas ń gbé pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, lálẹ́ ọjọ́ náà ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́, Dorcas jáde lọ ra oúnjẹ ní ‘Student’s village’ tó wà ní ọ̀nà Ẹdẹ.
Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò ríi kó dé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní pe aago rẹ̀ àmọ́ aago rẹ̀ méjèèjì kò lọ.
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ẹ̀ṣọ́ ilé ìwé létí wọ́n sì fi sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá.
Ọ̀gá àgbà ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo; Ọ̀jọ̀gbọ́n Simeon Bamire ti pàṣẹ fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé ìwé láti sa ipa wọn ó sì tún rọ àwọn ọlọ́pàá láti wá ọmọ náà jáde.
ÀJỌ EFCC YA BO ILÉ ÌTURA OBASANJO NÍ ABEOKUTA, WỌ́N KỌ́ Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ ÀWỌN Ọ̀DỌ́KÙNRIN TÍ WỌ́N FURA SÍ PÉ WỌ́N JẸ́ ỌMỌ ‘YÀHÛ’
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó lé ní àádọ́rùn-ún ni àwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu EFCC ti kó báyìí ní ilé ìtura Obasanjo tó wà ní Abẹ́òkúta, ìpínlẹ̀ Ogun.
Àwọn ọ̀dọ́ náà kóra jọ fún patí etídò lóru àná ni kó tó di pé àwọn EFCC ya bò wọ́n níbẹ̀.
Ọ̀rọ̀ di bóòlọ-o-yàgò, ìró ìbọn lákọlákọ, wọ́n sì mú àwọn ọ̀dọ́ tó lé ní àádọ́rùn-ún.
Àwọn ọkọ̀ bọ̀gìnnì, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ olówó iyebíye àti àwọn ohun ìdíyelé mìíràn ni wọ́n gbà lọ́wọ́ wọn.
ÀWỌN AGBÉBỌN PA ÈÈYÀN MẸ́TA NÍ BENUE.
Àwọn agbébọn ti pa àwọn èèyàn mẹ́ta nínú ìkọlù titun tí wọ́n ṣe sí Yelwata ní ìpínlẹ̀ Benue.
Òwúrọ̀ kùtù ni àwọn agbébọn tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ fulani ya wọ inú abúlé náà ní nǹkan bíi aago méje, wọ́n yìnbọn pa àwọn èèyàn mẹ́ta wọ́n sì tún pa àwọn mẹ́ta mìíràn lára.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n kó òkú àwọn tí wọ́n pa náà lọ sí àbáwọ ìlú tí wọ́n sì tẹ́ wọn síbẹ̀.
Àwọn ará ìlú tú jáde láti ṣe ìwọ́de tako ìpànìyàn yìí, wọ́n dí ọ̀nà tó lọ sí Abuja láti Makurdi.
Olórí ọ̀dọ́ Yelwata; Achii Mathias ṣe àlàyé pé òwúrọ̀ kùtù ni awọn Fulani náà ya wọ inú abúlé tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yìnbọn lákọlákọ.
Gbogbo akitiyan láti kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Benue kò tíì so èso rere.
ÀWỌN ABARAPÁ ṢE ÌWỌ́DE ILÉ ÌWÉ WỌN TÓ WÀ NI TÍTÌ PA.
Àwọn abarapá ní ìpínlẹ̀ Èkó tú jáde láti ṣe ìwọ́de látàrí bí ilé ìwé wọn ṣe wà ní títìpa. Wọ́n dí gbogbo ọ̀nà tó lọ sí pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed.
Ohun tí wọ́n ń bèèrè fún náà ni kí ìjọba ó ṣí ilé ìwé àwọn tó ti wà ní títìpa láti ọdún méjì sẹ́yìn.
Wọ́n ṣe àlàyé pé ojú alágbe ni àwọn èèyàn fi ni wo àwọn nítorí pé àwọn kò ní anfààní àti kẹ́kọ̀ọ́.
Ìjọba wá kọ́ ilé ìwé fún àwọn sí Isheri, wọ́n sì tún tì í pa láti ọdún méjì sẹ́yìn láìní ìdí kankan.
Wọ́n ní àwọn ti kọ lẹ́tà títí kò sí èsì kankan ni àwọn ṣe ṣe ìwọ́de yìí, èyí yóò kan ìjọba lára wọn yóò sì dá àwọn lóhùn.
ÀWỌN AGBÉBỌN YA BO MỌ́ṢÁLÁṢÍ NÍ SOKOTO, IMAM DÈRÒ Ọ̀RUN.
Àwọn agbébọn ti ya wọ mọsalasi kan tó wà ní Wurno ní ìpínlẹ̀ Sokoto, wọ́n yìnbọn pa Imaamu wọ́n sì tún jí àwọn èèyàn gbé lọ.
Ìrun ìdájí ni àwọn èèyàn náà ń kí lọ́wọ́ tí àwọn agbébọn náà fi ya bò wọ́n, wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀, wọ́n pa Imaamu àti ọ̀pọlọpọ àwọn èèyàn wọ́n sì tún jí àwọn kan gbé lọ.
Isa Achida; ẹni tó jẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Sokoto bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó rọ àwọn èèyàn láti ṣe sùúrù pé àwọn agbófinró yóò wá àwọn agbébọn náà jáde.
KONJI TI SỌ ỌMỌ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ SÍ Ẹ̀WỌ̀N ỌDÚN MÁRÙN-ÚN NÍ UK.
Ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan ti rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún he ní ilẹ̀ UK nítorí pé ó fi ipá bá obìnrin lò.
Segun Ogundipe ni orúkọ ọkùnrin yìí, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n níí ṣe.
Ẹ̀sùn oníkókó méjì ni ìjọba UK fi kan Ogundipe, ó ní òun kò jẹ̀bi àmọ́ adájọ́ wí pé ó jẹ̀bi ó sì dá ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún fún un.
Ọ̀GÁ ỌLỌ́PÀÁ ÀGỌ́ KAJOLA TI DÁGBÉRE FÁYÉ.
Ọ̀gá ọlọ́pàá àgọ́ Kajola ní ìjọba ìbílẹ̀ Odigbo, ìpínlẹ̀ Òndó ti dágbére fáyé.
Nimrod Anaka ni orúkọ DPO yìí, a gbọ́ pé nígbà tí ó ń lọ síbi iṣẹ́ ní àná, ọjọ́ ìṣẹ́gun ni ààrẹ náà dé nínú ọkọ̀, ó yà lo sí ilé ìwòsàn àmọ́ kò dé ilé ìwòsàn tó fi dákẹ́.
Ayanlade Olushola; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Òndó fìdí èyí múlẹ̀, ó wí pé àyẹ̀wò yóò wáyé láti mọ ohun tó ṣe okùnfà ikú òjìjì náà
ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI ILÉ ÌWÉ DOWEN PA.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti gbé ilé ìwé Dowen tó wà ní Lekki tì pa lórí ẹ̀sùn pé ó rú òfin ìdalẹ̀nù.
Àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka ìmọ́tótó ìpínlẹ̀ Èkó; LAWMA ni wọ́n lọ ti ilé ìwé náà pa bayìí.
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ilé ìwé náà ni pé wọ́n gbé ilẹ̀ wọn fún oníọmọlanke tí òun sì lọ dà á síbi tí kò tọ́.
Ọlọ́mọlanke náà ni wọ́n mú níbi tó gbé ń da ilẹ̀ nù tó sì ṣe àlàyé pé ilé ìwé Dowen ni òun ti gbé ilẹ̀ náà.
Ìjọba Èkó ní àwọn kò ní fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú èyí nítorí pé ìmọ́tótó ìpínlẹ̀ Èkó ló jẹ àwọn lógún.
Tokunbo Wahab; ẹni tó jẹ́ kọ́míṣọ́nà fún ètò àyíká àti àwọn ohun àlùmọ́nì inú omi ìpínlẹ̀ Èkó ti dá sí ọ̀rọ̀ yìí.
CHIEF KARAN; ÒṢÈRÉ TÍÁTÀ TI DÁGBÉRE FÁYÉ.
Olusegun Akinremi tí orúkọ ìtàgé rẹ̀ ń jẹ́ Chief Karan ti dágbére fáyé lẹ́ni àádọ́rin ọdún.
Adari eré nnì; Seun Oloketuyi ló túfọ̀ Chief Karan lójú òpó Instagram rẹ̀
.



