Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Nnamdi Azikwe tó wà ní Awka tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Anambra ti dágbére fáyé lẹ́yìn tí ó ti kọ́kọ́ró yàrá rẹ̀ mọ́lé tí kò sì ní àǹfààní àtilo òògùn rẹ̀ tó wà nínú yàrá.
Isabella ni orúkọ akẹ́kọ̀ọ́bìnrin yìí, ìpele kìíní ló wà ní ẹ̀ka ìmọ̀ òfin. Ààrùn ìtọ̀ ṣúgà ni ó ń bá Isabelle fínra.
A gbọ́ pé àwọn mẹ́ta ni wọ́n jọ ń lo yàrá iléègbé Emalda, lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Igbe tó kọjá yìí, Isabella àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ti kọ́kọ́rọ́ yàrá wọn mọ́ ilé, wọ́n rọ àwọn aláṣẹ iléègbé náà láti fún wọn ní ẹ̀da kọ́kórọ́ yàrá wọn àmọ́ wọ́n kọ̀ jálẹ̀ pé àfi kí wọn ó san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì náírà ẹnìkọ̀ọ̀kan. Gbogbo ẹ̀bẹ̀ wọn kò wọ etí àwọn adarí iléègbé náà.
Alẹ́ ọjọ́ náà ni àìsàn Isabella bẹ̀rẹ̀ tó sì nílò àwọn òògùn rẹ̀, gbogbo bí ọmọ náà ṣe ń jẹ ìrora tí wọ́n sì ń bẹ̀ wọ́n, wọ́n ní àwọn adarí náà kò dá wọn lóhùn.
Àwọn ọmọ yìí san ọgọ́ta ẹgbẹ̀rún nínú owó náà àmọ́ wọ́n yarí pé àfi tó bá pé. Gbogbo àsìkò yìí ni àìlera Isabella ti ń burú síi àmọ́ wọn kò dáa lóhùn.
Àwọn ọmọ yìí kò rí yàrá wọn wọ̀ láti ọjọ́ Ẹtì náà títí di òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, lásìkò yìí, Isabella ti wà ní ipò to léwu, ó lo àwọn òògùn rẹ̀ àmọ́ kò bá a mọ́ ni wọ́n bá gbé e lọ sí ilé ìwòsàn inú ọgbà ilé ìwé náà. Ilé ìwòsàn UNIZIK kò ní ohun tó le fi tọ́jú àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ni wọ́n bá darí rẹ̀ sí ilé ìwòsàn ìjọba ẹ̀kọṣẹ́ òògùn òyìnbó níbi tó padà dákẹ́ sí.
Àwọn akẹgbẹ́ Isabella fi ẹ̀sùn kan ilé ìwé wọn pé wọ́n kọ̀ láti fún àwọn ní ẹ̀dà kọ́kọ́ro fún odidi ọjọ́ mẹ́ta nítorí pé àwọn kò rí owó tí wọ́n bèèrè san, wọ́n ní ìgbà tí wọ́n ríi pé Isabella ti wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn láàárọ̀ ọjọ́ Ajé láti ọjọ́ Ẹtì.
Wàyí o, àlàyé tí ilé ìwé UNIZIK ṣe lòdì sí ohun tí àwọn ọmọ náà sọ kalẹ̀ yìí. Nínú àtẹ̀jáde tí alukoro ilé ìwé náà; Njelita Louis fi léde la ti kà á pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, wọ́n ní ẹni tí àwọn ẹ̀dà kọ́kọ́rọ́ wà lọ́wọ́ rẹ̀ ri ìrìn àjò kúrò nínú ìlú lásìkò náà kò sì padà dé títí di òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé náà, bó ṣe dé náà ni ó ti fún wọn ní kọ́kọ́rọ́ mìíràn.
Ilé ìwé UNIZIK tako ohun tí àwọn ọmọ náà sọ pé wọ́n bèèrè owó lọ́wọ́ wọn kí wọn ó tó le fún wọn ní kọ́kọ́rọ́, Njelita wí pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ pé àwọn kò bèèrè tàbí gba owó lọ́wọ́ wọn.
Ní báyìí, wọ́n ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí bí gbogbo ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ wọ́n sì rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti yàgò fún gbogbo ohun tó le da àlàáfíà ilé ìwé náà rú.
Ó ṣe pàtàkì láti fi kún un pé ikú Isabella wáyé lọ́jọ́ kẹrin tí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ka ìmọ̀ kòkòrò tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tochi fò ṣánlẹ̀ lórí pápá ìṣeré tó sì kú.
Ìpele kẹta ni Tochi wà, ìwádìí lórí ikú rẹ̀ kò tíì parí.
Bákan náà ni ọwọ́ wa tẹ ìròyìn kan nípa ikú ọjọ́ ọ̀la mìíràn ní ìpínlẹ̀ Èkó pé:
Ọmọ ọdún mẹ́ta kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Chibuike Uba ti dágbére fáyé lẹ́yìn tó kó sí inú ṣáláńgá tí wọn kò dé lórí. Agbègbè Babarinsa ní Ibeju Lekki ni èyí ti ṣẹlẹ̀.
A gbọ́ pé ìyá Chibuike mú ọmọ rẹ̀ lọ kí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní Lekki, ó kù dẹ̀dẹ̀ kí Utoro tíí ṣe ìyá Chibuike ó máa lọ ilé rẹ̀ ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀; Uba bọ́ síta lọ gba ìpè tí ọmọ náà sì tẹ̀lé e. nígba tí Uba padà ẉọlé ni ó bèèrè ọmọ náà lọ́wọ́ Utoro; ìyá rẹ̀.
Ìyá Chibuike dáhùn pé ọmọ náà tẹ̀lé e bọ́ síta ni wọ́n bá fi ń wá a kiri.
Etí ṣáláńgá náà ni wọ́n ti rí bàtà rẹ̀ tí wọ́n fi mọ̀ pé ó ti kó sínú ṣálánágá.
Utoro bá àwọn akọ̀rọ̀yìn sọ̀rọ̀, ó wí pé láti Epe ni òun ti gbéra lọ kí ẹ̀gbọ́n òun ní Lekki tí ọmọ òun sì lọ kú síbẹ̀.
Ó wí pé ẹ̀gbọ́n òun; Uba tip e baba onílé náà láìmọye ìgbà pé kó dí ṣáláńgá náà àmọ́ ṣe ni ó ń fi òní dónìí fọ̀la dọ́la.
Gbogbo akitiyan láti bá bàbá onílé náà sọ̀rọ̀ kò yọrí sí rere látàrí pé kò gbé aago, wọ́n ti fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí.
Bákan náà la gbọ́ pé wọ́n ti yọ òkú arábìnrin kan tó kó sínú kànǹga láti ọjọ́ mẹ́wàá sẹ́yìn:
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti Ijegun, ìpínlẹ̀ Èkó kò ṣẹnure rárá. A gbọ́ pé arábìnrin kan ló kó sínú kànǹga kan ní iwájú ilé tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní Ijegun, ìpínlẹ̀ Èkó.
Ọgbọ̀njọ́, oṣù Okúdù tó kọjá yìí ni obìnrin náà kó sínú kànǹga yìí., odidi ọjọ́ mẹ́wàá gbáko ló lò nínú rẹ̀ kí wọ́n tó wá yọ òkú rẹ̀ láàárọ̀ yìí. Wọ́n ní àwọn òṣìṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì kò ní irinṣẹ́ tí wọ́n le fi yọ ọ́ nítorí pé kànǹga náà jìn ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà àádọ́jọ.
Ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Èkó sọ̀rọ̀ láti ẹnu alukoro wọn; Maria Fadairo pé àwọn gba ìpè pájáwìrì náà nípa obìnrin kan tó kó sínú kànǹga ní iwájú ilé tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ tó wà ní òpópọ́nà Abuba Anthony, ibùdókọ̀ Obalagbe nítòsí ilé ìtura Fadeko.
Wọ́n ní awọn ta mọ́ra débẹ̀ àmọ́ kànǹga náà jìn gan-an ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà àájọ́jọ (170 ft) ní èyí tó gba kí àwọn ó kàn sí àwọn ẹ̀ka mìíràn.
Odidi ọjọ́ mẹ́wàá ló gbà wọ́n láti rí òkú obìnrin náà yọ jáde. Wọ́n ní àwọn bá àwọn ẹbí rẹ̀ kẹ́dùn àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹni tó ni ilé náà.



