Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga NOUN kan ti dákẹ́ sínú gbọ̀ngán ìdánwò lásìkò tó ń ṣe ìdánwò lọ́wọ́.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé Michael Coker wà ní gbọ̀gán ìdánwò ní ẹ̀ka ilé ìwé náà tó wà ní Victoria Island, ó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìdánwò rẹ̀ ní ó ṣàdédé mú ìdí lọ sílẹ̀, ẹni tó wà lẹ́yìn rẹ̀ ló pàdé rẹ̀ tó sì tẹ́ ẹ sílẹ̀. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fẹ́ ṣúgbà rẹ̀ kí wọn ó ṣa aájò rẹ̀ àmọ́ olùkọ́ kan tó jẹ́ obìnrin ní kí wọn ó fi sílẹ̀ pé yóò dìde ó sì lé wọn padà sídìí ìdánwò wọn.
Lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́rin tí Michael ti wà nílẹ̀ tí èémí rẹ̀ sì ń ṣe ṣégeṣège, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tún gbìyànjú àtiṣe aájò rẹ̀ àmọ́ olùkọ́ náà tún lé wọn padà. Nígbà tó lé ní ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún tí Michael ti wà nílẹ̀, olùkọ́ mìíràn wọlé wá ó sì wí pé àwọn ti pé nọ́ọ̀sì. Ó gba nọ́ọ̀sì náà ní ìṣẹ́jú márùn-ún mìíràn kí ó tó gbé Michael jókòó, lẹ́yìn náà ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ṣèt̀ àtigbé e lọ sí ilé ìwòsàn.
Bukola; ẹni tí òun náà jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àlàyé pé àwọn bèèrè bí Michael bá ní wárápá tàbí gìrì, wọ́n tilẹ̀ gbìyànjú àtifi ṣibí há a lẹ́nu àmọ́ olùkọ́ náà kò gbà.
Ilé ìwòsàn àkọ́kọ́ tí wọ́n gbé Michael lọ kò gbà á, wọ́n darí rẹ̀ sí ilé ìwòsàn mìíràn àmọ́ Michael kú kí wọ́n tó dé ilé ìwòsàn kejì.
Nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ parí ìdánwò ni wọ́n gbọ́ pé Michael Coker ti kú, wọ́n nàka àbùkù sí olùkọ́ náà pé òun ni kò jẹ́ kí wọn ó tètè ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
Olùkọ́ mìíràn ní ilé ìwé náà tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun ṣe àlàyé pé èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí akẹ́kọ̀ọ́ yóò dákú tí yóò sì tún dìde. Ó wí pé púpọ̀ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni ó ní àìsàn lágọ̀ọ́ ara, òmíràn kò tilẹ̀ mọ̀ títí yóò fi wá dákú sí ilé ìwé tàbí nínú ìdánwò.
Akẹ́kọ̀ọ́ kan ti dákú rí tó sì jẹ́ pé òògùn olóró tó mu ló fà á. Òmíràn ní gìrì, òmíràn ní ikọ́ọfe tí wọn yóò sì máa dákú.
Akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun sọ èrò rẹ̀ pé òun kò lérò pé olùkọ́ náa mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe ìdíwọ́ fún ìtọ́jú Michael, ó lè jẹ́ pé ó kàn fẹ́ kí wọn ó fún un ní ààyè kí atẹ́gùn le fẹ́ síi. Ó ní òun kò sí nínú gbọ̀ngán lásìkò náà òun kàn gbọ́ ariwo ni.
Àwọn akọ̀ròyìn kàn sí ilé ìwòsán Bonny Camp tí wọ́n kọ́ gbé Michael lọ, dọ́kítà ibẹ̀ ní àwọn kò kọ Michael, àwọn darí rẹ̀ lọ sí ilé ìwòsàn mìíràn nítorí àwọn kò ní èémí tó nílò.
Àwọn mọ̀lẹ́bí Michael ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́, wọn kò tíì le sọ nǹkankan báyìí bẹ́ẹ̀ sì ni adarí ilé ìwé náà kọ̀ láti fèsì sí ìbéèrè àwọn akọ̀ròyìn.
Ìlera àwon akẹ́kọ̀ọ́ ní láti jẹ́ ọ̀kúnkúndùn. Bí wọ́n ṣe fi ẹ̀sùn kan olùkọ́ yìí lórí ikú Michael ni wọ́n ṣe fi ẹ̀sùn kan aláṣẹ ilé ìgbé ti ilé ìwé gíga Nnamdi Azikwe lórí ikú Isabella.
A mú ìròyìn náà wá fún yín nínú oṣù Agẹmọ pé:
Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Nnamdi Azikwe tó wà ní Awka tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Anambra ti dágbére fáyé lẹ́yìn tí ó ti kọ́kọ́ró yàrá rẹ̀ mọ́lé tí kò sì ní àǹfààní àtilo òògùn rẹ̀ tó wà nínú yàrá.
Isabella ni orúkọ akẹ́kọ̀ọ́bìnrin yìí, ìpele kìíní ló wà ní ẹ̀ka ìmọ̀ òfin. Ààrùn ìtọ̀ ṣúgà ni ó ń bá Isabelle fínra.
A gbọ́ pé àwọn mẹ́ta ni wọ́n jọ ń lo yàrá iléègbé Emalda, lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Igbe ni Isabella àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ti kọ́kọ́rọ́ yàrá wọn mọ́ ilé, wọ́n rọ àwọn aláṣẹ iléègbé náà láti fún wọn ní ẹ̀da kọ́kórọ́ yàrá wọn àmọ́ wọ́n kọ̀ jálẹ̀ pé àfi kí wọn ó san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì náírà ẹnìkọ̀ọ̀kan. Gbogbo ẹ̀bẹ̀ wọn kò wọ etí àwọn adarí iléègbé náà.
Alẹ́ ọjọ́ náà ni àìsàn Isabella bẹ̀rẹ̀ tó sì nílò àwọn òògùn rẹ̀, gbogbo bí ọmọ náà ṣe ń jẹ ìrora tí wọ́n sì ń bẹ̀ wọ́n, wọ́n ní àwọn adarí náà kò dá wọn lóhùn.
Àwọn ọmọ yìí san ọgọ́ta ẹgbẹ̀rún nínú owó náà àmọ́ wọ́n yarí pé àfi tó bá pé. Gbogbo àsìkò yìí ni àìlera Isabella ti ń burú síi àmọ́ wọn kò dáa lóhùn.
Àwọn ọmọ yìí kò rí yàrá wọn wọ̀ láti ọjọ́ Ẹtì náà títí di òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, lásìkò yìí, Isabella ti wà ní ipò to léwu, ó lo àwọn òògùn rẹ̀ àmọ́ kò bá a mọ́ ni wọ́n bá gbé e lọ sí ilé ìwòsàn inú ọgbà ilé ìwé náà. Ilé ìwòsàn UNIZIK kò ní ohun tó le fi tọ́jú àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ni wọ́n bá darí rẹ̀ sí ilé ìwòsàn ìjọba ẹ̀kọṣẹ́ òògùn òyìnbó níbi tó padà dákẹ́ sí.
Àwọn akẹgbẹ́ Isabella fi ẹ̀sùn kan ilé ìwé wọn pé wọ́n kọ̀ láti fún àwọn ní ẹ̀dà kọ́kọ́ro fún odidi ọjọ́ mẹ́ta nítorí pé àwọn kò rí owó tí wọ́n bèèrè san, wọ́n ní ìgbà tí wọ́n ríi pé Isabella ti wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn láàárọ̀ ọjọ́ Ajé láti ọjọ́ Ẹtì.
Wàyí o, àlàyé tí ilé ìwé UNIZIK ṣe lòdì sí ohun tí àwọn ọmọ náà sọ kalẹ̀ yìí. Nínú àtẹ̀jáde tí alukoro ilé ìwé náà; Njelita Louis fi léde la ti kà á pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, wọ́n ní ẹni tí àwọn ẹ̀dà kọ́kọ́rọ́ wà lọ́wọ́ rẹ̀ ri ìrìn àjò kúrò nínú ìlú lásìkò náà kò sì padà dé títí di òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé náà, bó ṣe dé náà ni ó ti fún wọn ní kọ́kọ́rọ́ mìíràn.
Ilé ìwé UNIZIK tako ohun tí àwọn ọmọ náà sọ pé wọ́n bèèrè owó lọ́wọ́ wọn kí wọn ó tó le fún wọn ní kọ́kọ́rọ́, Njelita wí pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ pé àwọn kò bèèrè tàbí gba owó lọ́wọ́ wọn.
Ní báyìí, wọ́n ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí bí gbogbo ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ wọ́n sì rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti yàgò fún gbogbo ohun tó le da àlàáfíà ilé ìwé náà rú.





